Gbajugbaja olorin juju to fi orile-ede Ireland sebugbe ni King Anjola Bravo, ilu Dublin lohu-un lokunrin naa ti n fi ebun ti Olorun fun un gbe oruko oril-ede yii ga.
Laipe yii ni Anjola Bravo salaye fun Ojutole pe ojo ti inu oun dun ju laye lojo ti maketa oun gba lati gbe rekoodu oun akoko jade.
Arewa olorin yii so pe saaju ki maketa naa too gba lati gbe awo oun yii jade loun ti gbinyanju lori bi awo naa yoo se jade sugbon ti awon idiwo kan wa, sugbon lojo naa kan ni maketa oun yii gba pe oun setan lati gbe rekoodu oun akoko yii jade.
O ni bi oun se kuro lodo maketa oun yii loun ti n pe awon eeyan oun nile pe Olorun ti se e, maketa naa ti gba lati gbe awo oun jade.
Bakan naa lo so pe oyinbo lo so oun ni oruko Bravo ti oun je yii, o ni lojo naa lohun-un, oun ati oyinbo naa jo wa ninu moto, lasiko naa lo so pe awon n gbo rekoodu oun kan . O ni se ni oyinbo naa beere pe ta a lo n korin, ti oun si da a lohun un pe oun ni, o ni se ni oyinbo yii so pe 'oh bravo bravo', itumo e ni pe orin naa dun pupo. Bravo ni leyin ti oyinbo bo sile loun ro o pe koun kuku maa je Bravo, bee loun fi oruko oun gangan kun un. ju.
No comments:
Post a Comment