Ọmọọba Adekọya Babajide Adefowora, ti sọ pe bi ki i ba ṣe pe Ọlọrun ti aṣiiri obinrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Tọpẹ, to gbidanwo lati pa Oloye Lateef Bello, Eleku tilẹ Ẹpẹ, wọn ko ba fi da wahala si oun lọrun ni amọ to ori ko oun yọ.
Bẹẹ lo tun bẹ gbogbo awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn fi adura ran oun lọwọ, nitori awọn kan to n lepa ẹmi oun nitori ọrọ ipo ọba.
Ninu atẹjade kan to fi sita, ni ọkunrin ọhun to jẹ ọmọ bibi Ọba Adeyemi Adedayo Adefowora, Alaketu, tiluu Ẹpẹ, to ti doloogbe, ti sọ pe ṣe lawọn kan fẹẹ maa dunkoko mọ oun.
Ariwo ki wọn ma pa oun bi wọn ṣe pa baba oun lọjọ kẹsan-an,oṣu kọkanla, ọdun 1999, ni ojule kẹtalelogoji, Arowolo, Abule Ẹgba, Awori, ni ọkunrn naa pa, nitori awọn nnkan to n ṣẹlẹ lakooko yii niluu Ketu-Ẹpẹ.
O ni ọkan oun ko balẹ, nitori bawọn kan niluu ṣe n dunkoko mọ oun,latigba ti wahala ipo ọba naa ti wa nile ẹjọ.
O ni gbogbo ọna ni ẹni to n ba oun dupo ọba fẹẹ fi dori ipo ti ko tọ si, to ni o si n sare lati lo agbara.
Bẹẹ lo ni wọn fẹẹ maa lo ọwọ agbara lati maa fi pa awọn ti wọn le ṣoootọ lẹnu mọ, bẹẹ lo ni wọn tun dunkoko mọ wọn pẹlu, nitori wọn ti mọ pe ẹyin oun ni awọn araalu wa.
Ọmọọba Adekọya tun fi kun ọrọ ẹ pe idile kan ṣoṣo lo n jọba niluu Alaketu Ẹpẹ iyẹn Ọṣọkeji Atẹsimara bẹẹ lawọn ko gbọ pe awọn ti wọn pe ara wọn ni Adeọna jọba ri.
Ọkunrin naa waa fi iṣẹlẹ to waye lẹnu ọjọ mẹta yii fi ṣe apẹẹrẹ nibi gti wọn lobinrin kan ti lọ ka ọkan lara afọbajẹ ilu naa, Oloye Lateef Bello mọ afin, to si fẹẹ okun fun lọrun pa, ko to di pe ọwọ tẹ.
Adekọya ṣọ pe ka ni aṣiiri obinrin naa ko tu, to si gba ẹmi baba agbalagba ẹni ọgọrin naa lojiji ni ọtọ ni nnkan ti wọn kọ ba maa wi, to si le jẹ akoba nla foun.
Ọmọọba yii wa rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn ma jẹ kawọn eeyan yii gbẹmi oun lojiji, nitori ẹru n ba oun lati wale nibi toun wa, nitori oun ko mọ iṣẹ ibi to wa lọwọ oun, ti wọn le ṣe.
O waa sọ pe oun nigbagbọ ninu igbẹjọ to n lọ lọwọ naa, toun si mọ pe idajọ ododo yoo waye nipa gbigba ẹtọ ọba ilu Keru Ẹpẹ le oun lọwọ.
j
No comments:
Post a Comment