IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 22 February 2024

E wo Eniowo Odeneye, Ojise Olorun to n fi ede Yoruba waasu loke-okun



Ọkan gboogi ninu awọn ọmọ orileede yii ti wọn kopa pataki ati ipa to n gbe ede Yoruba ga loke okun ni Ẹniọwọ Henry Adebayọ Odẹnẹyẹ, baba yii ni oludasilẹ ijọ Dagunduro Prayer Family to wa lorileede Amẹrika. Kinni kan ti ijọ yii fi yatọ sawọn ijọ yooku nipe ede Yoruba pọnbele ni wọn fi n waasu nibẹ. Baba yii ti ba akọroyin wa TAOFIK AFỌLABI, sọrọ, diẹ ninu ohun ti wọn sọ ree.     

 

Ẹ ṣalaye diẹ fun wa nipa yin

Emi ni aṣiwaju ẹgbẹ aladura  ti  a pe ni ‘Dagunduro Prayer family’ to fi orileede Amẹrika ṣebugbe, ṣugbọn ti a ni ẹka kaakiri orileede. Emi tun ni aṣiwaju ‘Yoruba Chritian Fellowship’, a wa ni ẹgbẹ to n fi ede Yoruba se isin ni ilu Houston, ti a n ṣe waasu ati isọji kaakiri. Bẹẹ ni mo jẹ olusọ aguntan ati district Apostle fun ijọ Apostolic  fun gbogbo agbegbe North America, ni Texas, ni Amẹrika.

Ẹ ṣalaye ninu ọrọ yin pe ede Yoruba pọnbele lẹ fi n ṣe waasu ninu ijọ, bo tilẹ jẹ pe aarin awọn oyinbo lẹ wa, ki lo fa igbesẹ yii?

Ẹ ṣeun, ti  Ọlọrun ba pe eeyan, ibeere mẹta pataki lo yẹ ki eeyan beere ko ma ba a si ẹsẹ gbe, ibeere akọkọ ti ẹni naa yoo beere nipe Oluwa, bawo ni ki n ṣe gbe igbesẹ nipa ipe yii, a pe Apostle Paul fun awọn keferi Jew,  a pe  Moses lati mu awọn ara Israel kuro ninu ahamọ ati oko eru Farao, a pe joshua lati mu wọn lọ si ilẹ Kenani. Ẹlẹẹkeji, ipe ti o pe mi yii awọn wo  lo ran mi si, ibo lo fẹ ki n ti bẹrẹ. Ibeere mẹtẹẹta yii ni Ọlọrun sọ fun mi, o wi fun mi pe oke-okun loun fẹẹ ki n ti lọọ jisẹ, bẹẹ ni mo beere  lọwọ Ọlọrun pe awọn wo lo ran mi si, ohun ti Ọlọrun sọ fun mi nipe oun fẹ ki n fi ede Yoruba ṣe ẹsin nitoripe awọn eeyan oun gbọpẹ lati sin oun.  Ẹ o ri i pe loke-okun ọja wa nibẹ ti wọn n pe ni African market awọn  ko si ounjẹ Yoruba ti ko si nibẹ, Ọlọrun ki n fi ounjẹ ẹmi bọ awọẹ eeyan lede abinibi wọn, o ni ki wọn fi ede oun ba oun sọrọ, oke-okun ni Ọlọrun ran mi si, ede Yoruba lo ni ki n fi sọrọ oun fun awọn eeyan, awọn Yoruba lo si ran mi si.

Lọjọ kan mo lọ si orileede Brasil, bi mo ṣe de papakọ ofurunfu wọn ti wọn yẹ iwe irinna mi wo, ti wọn ri i pe ọmọ  Yoruba ni mi, bi ọkan ninu awọn osisẹ asọbode naa ṣe ri pe orukọ Yoruba lo wa ninu iwe irinna mi lo beere lọwọ mi pe ṣe mo mọ nipa ifa, mo sọ fun un pe mo ka nipa ẹ ni,  ṣugbọn mi o mọ nipa ẹ daadaa,ohun ti ọkunrin naa sọ fun mi nipe, oun mọ ọn mọ kọ ede Yoruba nitoripe onifa loun, mo ni ko si ohun to buru nibẹ, ṣugbọn ẹlẹsin igbagbọ lemi.

Bi mo ṣe de otẹẹli mi ni Ọlọrun ran mi leti pe ṣe bi oun sọ fun mi pe ko si ohun to buru ninu ki n ma fi ede Yoruba ṣe ẹsin igbagbọ ti mo n ṣe, o ni pe ka wa ọmọlẹyin Jesu gbe ede Yoruba larugẹ,  pe ti a o ba sọra wọn ti fẹẹ sọ ede Yoruba di ẹsin awọn onifa, awa krisitẹẹni wa n kọ. Ti a ba wo bi a ṣe kọ ohunkohun silẹ, a o gbe sadakanta fun baba wa Oloogbe Samuel Ajayi Crowther, nitoripe awọn ni wọn tunmọ bibeli lati ede oyinbo si ede Yoruba.

Igbesẹ ti ẹ gbe yii jẹ igbesẹ ti yoo ṣe ajeji si eti awọn eeyan pe ẹ n fi ede Yoruba waasu nilẹ alawọ funfun. Bawo ni itẹwọgba?

Nigba ti a kọkọ bẹrẹ, awọn jankanjankan ti mo ba lẹnu iṣẹ iranṣe lorileede Amẹrika, mo juba wọn, mo si fi ohun ti Ọlọrun sọ fun mi yii to wọn leti, ṣugbọn ohun ti wọn sọ nipe ko le e ṣee ṣe, wọn ni awọn tawọn n fi ede gẹẹsi waasu gan-an eeyan meloo lawọn ri, ṣugbọn ti eniyan niyẹn. Mo pada lọ si ọdọ ẹni to ran mi niṣẹ, ohun ti Ọlọrun sọ fun mi nipe, iran yii emi nikan loun fi han, ko le ye awọn ti mo fọrọ lọ yii, iran yii fohun, wọn si gba a, ti awọn eeyan bẹrẹ si ni i ya wa lati ṣe isin awọn mi-in n wa lati awọn ile ijọsin mi-in. Aago mẹjọ la ma n bẹrẹ ijọsin wa pẹlu ede Yoruba, ti a ba si ti ṣetan, olukaluku yoo pada lọ sile-ijọsin ree lati gbọ waasu lede gẹẹsi nibẹ. Mo maa  ṣalaye anfaani nla ti ede Yoruba ti a fi waasu yii mu ba awọn eeyan wa lAmẹrika, anfaani ti iran Yoruba jẹ pẹlu ede wa yii lọdọ awọn alasẹ orileede Amẹrika.    

Ohun ti ẹ n ṣe yii, iṣẹ nla ni, n jẹ ẹ ni awọn idojulọ tabi ipenija?

Ẹ ṣeun, a ni idojukọ, bi a ba n le adura ni ede Yoruba, a ma n lo awọn ijilẹ Yoruba lati gbe adura yii kalẹ, ṣe lawọn eeyan sọ pe ọfọ ati ogede la n pe, awọn kristẹẹni bii temi naa ni wọn bẹrẹ itako yii. Ẹ jẹ ki n fun yin apẹẹrẹ kan, awọn agba Yoruba sọ pe ẹgbaagbeje mariwo ki i pe ipade a i tu, wọn ni bi irawe se pọto, bi wọn ba korajọ, bi afẹfẹ ba fẹ yoo tu wọn ka, a ma n gbadura pe  ẹgbaagbeje mariwo ki i pe ipade a i tu, ẹgbẹkẹgbẹ ti wọn ba n korajọ nitori temi, Ọlọrun tun wọn ka, o si wa ninu bibeli pe kikorajọ wọn yoo korajọ, ṣugbọn bi emi Ọlọrun ko ba si laarin wọn, ti tuka la o tun wọn ka. Awọn agba Yoruba a ma a sọ pe ewe a maa sunko, ti a ba gbadura pe ohunkohun ti wọn ba ti ewe ati egbo ṣe lori mi  ko sunko, bibeli naa sọ pe ewe a mama sunko, itanna a si mama rẹ, iyatọ wo lo wa ninu ọrọ Yoruba yii ati ohun ti bibeli sọ.

Idujọ ikeji nipe, ọpọlọpọ wọn sọ pe a fẹẹ gba ọmọ ijọ awọn, mo si jẹ ki wọn mọ pe ko sẹni to le gba ọmọ ijọ ẹnikan. ọmọ ijọ Jesu ni gbogbo wa, ohun ti awọn eeyan n gbọ lo jẹ ki wọn maa wa. Mo ranti pe nigba ti a ba lọọ ṣe olude ni ilu wa, mama mi n sin ewure, ewurẹ wọn kan wa to n jẹ Lẹru, o ma a n bimọ pupọ, . mama si ma n tọju  ẹ, ti wọn ba ti fẹẹ fun lounjẹ, wọn yoo po epo pọ mọ gure, won yoo wa a duro sẹnu agannadi,  wọn yoo pariwo orukọ rẹ, ti ewurẹ yii ba ti gbọ yoo ma sare bọ wa sile, ti awọn ewurẹ adugbo mi-in yoo tẹle, ẹmi mimọ sọ fun mi pe ti mo ba ṣe ounjẹ adidun, aguntan to ba jẹ ninu ẹ, yoo lọọ pe awọn yooku wa. Bi a ṣe bẹrẹ eto yii ṣe lawọn eeyan n pe ara wa pe ohun ti awọn ti n gbohungbẹ ede Yoruba lati ọjọ pipẹ darapọ mọ wa, awọn olusọ aguntan bii temi ni wọn gbogun ti mi, ṣugbọọn ọrọ naa pada ye wọn, a si ti n ṣe papọ bayii.

Ẹ ti sọrọ nipa idojukọ, awọn atilẹyin wo lẹ wa a ri lọdọ awọn ijọba orileede Amẹrika  lori ohun ti ẹ gbẹ dani yii?

Ẹ ṣeun, atilẹyin akọkọ ti mo ri ọdọ Ọlọrun lo ti wa, Jesu Kristi ẹni to fiṣẹ ran mi, ṣe ẹ mọ pe Ọlọrun ko ni i sọ kalẹ wa a ran eeyan lọwọ, ẹnikan ni yoo ran, a ri ọpọọlọp atilẹyin lọdọ ijọba orileede Amẹrika, ki i ṣe ti owo, ṣugbọn wọn ran wa lọwọ lọpọlọpọ lori pi ipolongo iṣẹ iranṣẹ yii. Fun apẹẹrẹ bi ijọba ba fẹẹ ṣe ikede, lasiko arun kofidi, wọn fun awa naa lanfaani lati ṣe  ipolongo lede Yoruba ti a si n ṣe e bi Ọlọrun ṣe fi ran wa, nigba mi-in a n ko awọn agbalagba yii jọ, ti a o ko wọn lọ si ibi ti wọn yoo ti gba abẹrẹ wọn. Ijọba pada sọ fun wa pe ohun ti a n ṣe yii jọ awọn loju, wọn fun wa niwee ẹri lati mọ riri ohun ti a n ṣe, bẹẹ ni wọn ya ọjọ kan sọtọ fun ayajọ ọjọ Yoruba ti wọn pe ni ‘Yoruba Day;, n gbogbo ọjọ kẹfa, oṣu kejila ni a ma n ṣe e, awa wa n lo anfaani ọjọ naa lati fi ede Yoruba polongo iṣẹ iyinrere.

Ẹlẹẹkeji nipe, bi ijọba Amẹrika ba fẹẹ gba eeyan wọle si ilu wọn, ipele mẹta ni, ipele akọkọ ni  ẹni to kan ṣe irinajo lọ sibẹ, ipele keji ẹni to sọ fun wọn pe ki wọn foun niwee lati maa gbe ilu naa ti wọn n pe ni green card, o niye ọdun ti eeyan yoo lọ lati sọ pe oun fẹẹ di ọmọ oniluu, o ni idanwo  ti wọn ma n ṣe fun wọn. A wa ni awọn alagbalagba to jẹ pe gbogbo ọna ni wọn fi yẹ lati di ọmọ oniluu, ṣugbọn a i gbọ ede oyinbo ja wọn kulẹ, o fun wọn ni iṣoro, wọn ko le ṣe idanwo lede oyinbo, wọn si n ka bibeli Yoruba daadaa, awọn eeyan si n pe wọn ni ẹni ti ko kawee, ṣugbọn emi jẹ ko ye wọn pe ẹni to ba le ka ede Yoruba, to si le e kọ ki i ṣe puruntu rara, a tọ ijọba lọ, a jẹ ko ye wọn pe  awọn ara China ti ko gbọ ede oyinbo ẹ n ṣe idanwo fun wọn, ẹ n fu wọn niwe ọmọ onlluu bawo wa a ni ọbọ ṣe ṣe ori, ti inaki ko sori bẹẹ, mo beere pe kilode ti wọn ko fun awọn eeyan wa niru anfaani bẹẹ, wọn ni o wa awa la o wadii ẹ. O si ti wa ninu ofin Amẹrika pe  ẹni to ba ti pe ẹni ọdun marundinlaaadọrin o ti lanfaani lati kopa ninu ioadanwo a ti di ọmọ oniluu yii. Mi o le gbagbe mama wa Ojẹyinka. Awọn la kọkọ fi bẹrẹ, wọn si yege idanwo wọn lede Yoruba, o ti wa ninu akọọlẹ pe eeyan  le ṣe idanwo lede Yoruba ko fi gba iwe la ti di ọmọ Amẹrika, mama yii ati ọmọ wọn Samson Ọjẹyinka la gba iwe ọmọ oniluu yii fun latọdọ wa. Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, o ti di ọmọ Yoruba mẹtadinlọgbọn ti wọn ti fi ede Yoruba ṣe idanwo yii, ti wọn si ti di ọmọ oniluu lorilede Amẹrika, ohun to jẹ ki awọn ijọba Amẹrika mọ riri wa, ti gọgirẹsi  Amẹrika fun mi ami-ẹyẹ, o jọ mi loju pe oyinbo mọ riri ohun ti a n ṣe.

Nigba ti ẹ  n sọrọ lẹẹkan , ẹ sọ pe ẹ pade oyinbo ara Braṣil kan to sọ pe gbogbo ẹni to ba ti jẹ ọmọ Yoruba onifa ni, ọtọ si ni ede, ọtọ ni aṣa, ọtọ ni ẹsin. Bawo la ṣe e fẹẹ ya a sọtọ?

Ti mo ba beere lọwọ yin pe ẹsin wo ni ẹsin abalaye, ẹ sọ pe ẹsin ibilẹ, sugbọn ko ri bẹẹ lọdọ temi,  emi o gba bẹẹ,  ẹ jẹ ki n ṣalaye ki ẹ too da mi lẹjọ, ọjọ kẹrin ọdun 1953 ni wọn bi mi, bi wọn ṣe bi mi, mo daye ba ẹsin kristẹẹni, musulumi ati ẹsin ibilẹ, ti wọn ba sọ pe ẹsin abalaye ẹsin mẹẹtẹẹta yii ni mo ba laye, mo wa a yan  ẹsin kristẹẹni laayo bi ẹsin temi. Ṣugbọn ṣe mo wa a le sọ pe nitoripe mo jẹ kristẹẹni ki n sọ pe bawo ni ti aṣa, ede mi ṣe jẹ, Yoruba lede mi ti mo ba lẹnu awọn obi mi, o yẹ ka le fi ara si ede wa. A ni eto kan ti a pe ni apejọ awọn ọmọlẹyin Kristi, nibi ti a o ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ pe a jẹ kriṣtẹẹni ko sọ pe ka ma gbe ede ati aṣa wa larugẹ, ọjọ yii la o fi ṣalaye fun awọn eeyan nipa aṣa, ẹsin ati ede. Ọpọ nnkan la o gbe yẹwo lọjọ naa, a o jẹ ki wọn mọ iyatọ ninu ede, aṣa, ẹsin.

Pẹlu ilakaaka yin lati jẹ ki ede Yoruba fẹsẹ rinlẹ loke-okun, n jẹ ẹni ẹka ‘Yoruba Chritian fellowship’ sawọn orileede tabi ilu mi-in?

Ẹ ṣeun, mo fẹ bẹ gbogbo ọmọ Yoruba kari aye pe ki wọn ran wa lọwọ, ki i ṣe ẹka nikan, a fẹẹ da ileewe silẹ ti a o ti maa kọ awọn eeyan wa lede Yoruba, paapaa awọn ọmọ wa, bẹẹ la tun fẹẹ kọ gbọngan ti a o ti ṣafihan asa Yoruba lọna ti ki i ṣe ti ibọriṣa, a fẹẹ kọ ibi kan ti a pe ni ‘Hall of fame’, nibi ti a o gbe aworan awọn baba wa ti Ọlọrun lo lati gbe ẹsin kirisiteeni  kalẹ lorileede yii, bẹẹ la o gbe eto Yoruba kalẹ nitori pe a ni eto. Awọn iranṣẹ Ọlọrun ma n wa beere orukọ Yoruba lọwọ mi ti wọn ba fẹẹ sọ awọn ọmọ wọn lorukọ, mo ti ṣe iwe lori ẹ, a si maa ni ẹka kaakiri. A maa ṣeto laipẹ fun ọjọ mẹta, nibi ti a o ti pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun lati wa a fi ede Yoruba waasu, ti a o ti sọrọ nipa bi awọn kristẹẹni sọ le mọ bi a o ṣe mu asa ati ede wa lokunkundun, ọjọ keji la o pe awọn ọba wa ti wọn jẹ ọmọlẹyin Jesu lati ba wa sọrọ, a ti ba baba wa Ọọniriṣa sọrọ, wọn si tẹwọ gbẹ wa, Gbogbo wa ọba yii ni wọn yoo waasu lede Yoruba, ọjọ kẹta ni a pe ni pẹpẹ iyin nibi tawọn olorin wa ti wọn jẹ ọmọlẹyin Jesu yoo ti wa akọrin, baba wa Oloye Ebenzer Obey ni wọn yoo jẹ baba ọjọ naa fun wa.

Ninu ifọrọwerọ yii, a ri i pe ede Yoruab dan lẹnu yin daadaa, bo tilẹ jẹ pe oke-okun lẹ wa fun ọpọlọpọ ọdun, bawo lẹ ṣe ṣee to fi rọrun bẹẹ fun yin?

Ilu Jos ni wọn bi mi si, ṣugbọn ọmọ bibi ilu Ijẹbu ni baba mi, ilu Jos ti wọn bi mi ile nikan ni mo ti lanfaani  lati sọ ede Yoruba, ede Hausa la ma n sọ, mo si gbọ Hausa daadaa. Nigba ti mo kuro ni Jos, Ghana ni mo lọ, ko si ede mi-in ju ede Fanti lọ, nigba ti mo pada dele lọdun 1960, ede Yoruba mi ko dan mọran, awọn eeyan si mọ pe Yoruba mi ko ṣe daadaa, mo n kawee mi, wọn si ṣe ni dandan fun wa pe a gbọdọ mu ede kan, ohun to jẹ ki n mu ede Yoruba niyẹn. Bi mo ṣe n ba lọ ọ niyẹn, marketing  ni mo ṣe nileewe, a i gbọ Yoruba mi daadaa ko mu idiwọ kankan wa fun mi,  ṣugbọn nigba ti mo waa di olori ijọ Apostolic ni Ifakọ, ohu ti wọn sọ fun mi ni `pe ede Yoruba ni o fi maa waasu, ti wọn yoo maa ṣe eda lede oyinbo, mo ni ki wọn jẹ ki n maa ṣe waasu lede oyinbo ki wọn maa ṣe ẹda ẹ lede Yoruba, wọn ni ko ri bẹẹ. Bi mo ṣe dele ni mo sọ fun iyawo mi pe o ti delẹ, iyawo mi lo pada kọ mi, ti mo bẹrẹ lati ABD, to fi di ohun ti o ye mi yekeyeke. Ohun to ya mi lẹnu nipe bi mo ṣe gbọ ede gẹẹsi to, ti mo gbọ ede Hausa, ti mo gbọ ede Fanti, Ọlọrun ko ṣe sọ pe ki n lo ọkankan ninu awọn ede naa ṣe waasu afi ibi ti kudiẹkudiẹ ti wa fun mi, ibẹ ni mo ti ranti ọrọ Ọlọrun to sọ pe oun yoo lo ibi ailera wa lati ran wa nisẹ. Bi mo ṣe bẹrẹ niyẹn ti mo kawee, ti mo nifẹẹ ede naa, gbogbo asọ mi pata aṣọ Yoruba ni mo ma n wọ.                                                               


No comments:

Post a Comment

Adbox