Pẹlu bí idibo ọdun 2027ṣe n sunmọ etile ẹgbẹ African Democratic Congress, ADC ti mura lati gba iṣakoso ipinlẹ Eko kuro lọwọ Aarẹ Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC.
Fun idi eyi ni ẹni to jẹ akọwe ẹgbẹ ADC, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ati oludije ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour party nigba kan, Gbadebọ Rhodes-Vivour ṣe tu sita, ti wọn si bẹrẹ si i ni polongo ẹgbẹ oṣelu ADC fun awọn eeyan.
Erongba awọn mejeeji ni lati ri i daju pe awọn pawọpọ pẹlu awọn eeyan lati yọ Tinubu loye aarẹ pẹlu ibo awọn ni ọdun 2027 ati pe ki ẹni ti yoo jẹ gomina ipinlẹ Eko lẹyin Gomina Babajide Sanwo-Olu ko tun nii jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Gbadebọ Rhodes-Vivour sọ ọ di mimọ pe, awọn ara igberiko naa ni iṣẹ́ lati ṣe lori eto idibo to n bọ yii.
Bọ tilẹ jẹ pe Rhodes-Vivour ko ti i fi ẹgbẹ oṣelu Labour Party silẹ sugbọn ko ni i pẹ mọ ti oun naa yoo fi lọ nitori ọpọlọpọ awọn ololufẹ Peter Obi lo ti fi ẹgbẹ naa silẹ.
Rhodes-Vivour pinnu pe oun yoo sa ipa oun lati fi opin si iṣakoso ọdun mejidinlọgbọn (28) ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko.
Rhodes-Vivour sọ siwaju si i pe ki iṣe óni lawọn bẹrẹ eto ati rẹyin iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, o ni ni ọdun 2023 lakoko idibo, oun ati Ogbeni Rauf Aregbesola ṣe ipade niluu Ikeja, o si fi aworan si ori ayelujara lati fi idi ọrọ naa mulẹ.
O ni ki awọn eeyan lọọ fi ọkan balẹ nitori akoko tuntun ni orile-ede Naijiria n lọ yii, akoko iṣe rere si ni.
No comments:
Post a Comment