IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 10 January 2019

GONGO SO LOJO TI IYA-N-GHANA, GBAJUGBAJA OLORIN ISLAM SAYEYE OJOOBI, OBINRIN NAA TU ASIIRI NLA KAN NIPA ARA E


Ojo nla ti ilu mo- on ka olorin esin Islam nni, Queen Seidat Bashirat  Ogunremi Olomitutu ti gbogbo aye mo si Iya-n-Ghana ko ni i gbagbe boro laye e lojo Wesde, ojo kesan-an, odun tuntun yii. Awon ololufe ti won n je Iyan-n-Ghana Fans Club ni won dana ayeye nla fun arewa obinrin yii niluu Agege, nipinle Eko, pitimu lawon eeyan ri nibe, ti ko si yo awon irawo olorin Islam naa sile.

 


 
Ninu oro Alhaja Basirat Ogunremi, iyen Iya-n-Ghana lo ti so pe, “Bo tile je ojo ayo lo ye ki ojo oni je, sibe ojo kan ti mo maa n sunkun lopo igba ti mo ba ranti ohun ti oju iya mi ri ki n too le wa saye ni. Bi e ti se n wo mi yii, mi o sun mojumo, ekun ni mo sun titi ile fi mo Nitori bi e se n wo mi yii, odun meji aabo ni mo lo ninu iya mi, ki emi naa too le wa saye. Ni gbogbo ojo ni aanu iya mi maa n se mi, nitori mo maa n wo o wi pe, iru ipo wo ni iya yen le wa fun odun meji aabo pelu oyun ninu.
“Isele yen gan-an lo maa n pa mi lekun gan-an. Bi mo se wa yii, okunrin ni mi o, emi ki i se obinrin, e le ri mi pe sura obinrin ni mo gbe wa saye, sugbon okunrin ni mi; nitori eegun mesan-an ni Olorun fun mi, isowo korin mi, bii okunrin ni, bee lawon isesi mi mi-in, ti awon eeyan le maa ri, bi okunrin ni mo se maa n se.”
Nigba to n soro lori ohun ti oju e ti ri, Iya-n-Ghana so pe, “Mo le so pe latinu oyun ni mo ti n la orisirisi iriri aye bo. Gege bi mo se so saaju, osu mesan-an ni gbogbo omo maa n lo ninu iya won, sugbon odun meji aabo lemi lo. Won ni nigba ti won tun bimo tan, mi o tun ke, bee ni mama mi so fun mi pe, ti awon eeyan ba wa, ti won n so pe omo tuntun, won ni nise ni mo n woju kaluku bii eni pe mo n gbo ohun ti won n so.
“Latigba ti mo ti wa de ile aye ohun, mi o gbonju mo awon obi mi ni olowo ri, sugbon mo mo won gege bi wolii Olorun ti won maa n sin Olorun daadaa. Gbogbo ohun ti oju ri patapata gege bi talika Olorun ti awon obi mi n se, gbogbo e pata ni mo ko sinu America Experience, emi tawon obi maa n se wahala ki a too le jeun, emi
naa ni mo deni to lo n bimo si America, awa to pe je pe a ko ya ile gbe ki a ko lo jade ri pelu irorun, nise ni won maa le wa jade nigba ti a ko ba ri owo ile san. Emi naa ni mo wa deni to n ko ile igbalode, mo deni to n sun, to tun n yi ninu ola, ope nla ni mo da fun Olorun, nitori e lo fi je pe ni gbogbo ojoobi mi, nise ni mo n ronu ohun ti oju awon obi mi ti ri ati ipo ti Olorun fi mi si loni-in.








No comments:

Post a Comment

Adbox