Titi di akoko ta a wa yii, ọpọ awọn eeyan ni wọn wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju nitori bi wọn ṣe lawọn ajagungbalẹ yawọ ilu naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ ni wọn sọ pe awọn ajagungbalẹ ọhun yawọ agbegbe kan ti wọn pe ni Rala, nidojukọ ile epo filling, to wa ni Ketu -Ẹpẹ.
Ninu ọrọ ti Ọgbẹni Mutiu Ẹkisanya, ọkan lara awọn ti wọn ṣe nijanba, to gba itọju lọwọ, ṣe wi, o nibi tawọn ti n gba atẹgun niwaju ile awọn ṣadeede lawọn ri tawọn eeyan ọhun sọkalẹ ninu bọọsi ti wọn gbe wa.
O sọ pe 'Bọọsi ti wọn gbe wa to mẹrin pẹlu awọn ija oloro lọwọ wọn, bi wọn ṣe sọkalẹ ni wọn bẹrẹ si nii yinbọn soke, nibi to le de wọn tun de ọja ti ko jinna si wa, ti wọn ju ẹrọ to maa n ta ni loju.
" Ohun to tun ya wa lẹnu ni pe awọn ọlọpaa kan tun tẹ le wọn, ṣe lawọn ajagungbalẹ yii bẹrẹ si nii lu wa, ti wọn ṣa awọn eeyan ladaa, bẹẹ ni wọn tun gba foonu, ti wọn tun wọnu ṣọọbu awọn eeyan ti wọn ko ẹru wọn.
Ṣugbọn ninu ọrọ ti Idris Isiaka, toun naa faragba nibi iṣẹlẹ ọhun sọ pe bi ala lọrọ naa si n jẹ fun oun ati pe aluki ni wọn lu oun.
O sọ pe 'Ni ọsan ọjọ tiṣẹlẹ ọhun waye, awọn ti kọkọ mu awọn eeyan kan ti wọn ra ilẹ lọ si ori ilẹ wọn, nitori wọn fẹẹ bẹrẹ iṣẹ nibẹ.
'A fi bo ṣe di alẹ, tawọn ajagungbalẹ yawọ ilu, a si mọ pe Akeem Oluwo, to n ba ọba wa taa ṣẹṣẹ yan dupo, iyẹn Ọmọọba Babajide Adekọya Adefowora lo ko awọn ajagungbalẹ naa wọlu.
Oun naa sọ pe gbogbo awọn agbegbe bii ọna Ejirin, Odo Ayanluṣẹ Kugba atawọn ẹnu bode to wọnu Ketu- Ẹpẹ ni wọn ko awọn ajagungbalẹ ọhun si.
Awọn araalu Ketu-Ẹpẹ wa rawọ ẹbẹ si ọga ọlọpaa patapata lorileede yii ati kọmiṣanna fawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, lati gba wọn lọwọ awọn ajagungbalẹ ti wọn ko idaamu bawọn niluu, nitori wọn ti fẹ maa fọ ilu.
Bakan ni wọn sọ pe gbogbo ọna lawọn to n da wahala silẹ yii fi fẹẹ jọba to si jẹ pe wọn ko ti idile ọba wa, nitori idile kan ṣoṣo lo n jọba niluu naa latigba ti alaye ti daye.
No comments:
Post a Comment