IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 3 May 2025

Ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to si n fi gbogbo ọjọ aye ẹ wa ilọsiwaju ìlẹ kootu-oo- jiire- lo maa n joye Ọbalẹfun- Ifa White


 
        
 
Laipẹ yii ni oludije ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu 'Labour', nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes-Vivour, joye Ọbalẹfun ijọ oloriṣa parapọ to si jẹ pe ẹni ti ki i ba ṣe ọmọ oduduwa ko le jẹ iru ẹ.

Gbọngan ootẹli Ayabot Events Centre, to wa lọna Ado-Odo, Badagry, nipinlẹ Eko, gbalejo awọn eeyan nla nla lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii, lọjọ naa ni Gbadebọ di Obalẹfun,aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parapọ.

Lọjọ ti Gbadebọ joye tuntun ọhun, gbọngan ibi ayẹyẹ naa kun fọfọ nibi tawọn oloṣelu atawọn eeyan pataki lawujọ to fi mọ awọn oniṣẹṣe ti peju pese lati waa ṣapọnle baba oloye tuntun naa.

Ibeere tawọn kan n beere ni pe kin ni itumọ oye Obalẹfun ti Gbadebọ je ati pe iru awọn eeyan wo ni wọn fi n jẹ ẹ lawujọ.

Ohun ta a gbọ pe o mu ki wọn fi agba ọjẹ nidii iṣẹ ayaworan ile jẹ Ọbalẹfun ati aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parapo ni igbagbọ ti wón sọ pe o ni si aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba.

Wọn ni oye naa ko wa fun iru wa ogiri wa bi ko ṣe fẹni to ba jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to si n fi gbogbo ọjọ aye ẹ wa fun ilọsiwaju kootu-oo- jiire.

Ni itẹsiwaju iwadii lori pe, awọn wọn lo maa n joye Ọbalẹfun, ni Oloye Abiọdun Oloyede, Olori Ọlọbatala nipinlẹ Ogun ẹni tawọn eeyan tun mọ si 'Ifa White' ṣalaye pe ẹni to ba kofa ti wọn si ni ki ifa ẹ faaye
gba Ọbatala le jẹ Ọbalẹfun wọn tun le pe e ni Ọba Aala .
 
Ifa White ni ojulowo ọmọ Yoruba ni wọn fi n joye naa tori naa bi Gbadebọ ko ba ki
 n ṣe ọmọ ọkọ Yoruba to si dade Ọbatala, o yẹ kọrun ti wọ ọ.

 Eyi ti wọn ṣapejuwe Gbdebọ Rhodes-Vivour, gegẹ bi ẹni ti ko fa sẹyin ninu gbigbe iṣẹṣe ilẹ Yoruba larugẹ, ko sibi to de ti ki ti n jẹwọ pe ọmo Yoruba loun, oun si kọja ẹni to n fi ọwọ osi juwe ile baba oun.

Bi a ba si ni sọ ododo, Gbadebọ Rhodes-Vivour, to tun jẹ oniṣowo nla, to si tun ni imọ nipa imọ ẹrọ igbalode , o n gbiyanju lati ri i pe aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba rọwọ mu lagbaaye, to si n kopa to jóju.

 

Agbegbe Isalẹ Eko ni ẹbi Ọbalẹfun tuntun yii iyẹn Rhodes Vivour ti wa, ni ojule kejidinlogoji,agbegbe Igboṣere, nibẹ ni wọn fi kọ City Hall lonii,

 

Gẹgẹ bi oun naa ṣẹ sọ lori igbagbọ to ni si aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, o sọ pe ‘’Aṣa Yoruba jẹ ọkan pataki lara awọn iwa Ọmọluabi, eyi to nii ṣe pẹlu orukọ rere, eyi to tunmọ si diduro lori ọrọ ẹni, ati jijẹ eeyan daradara lawujọ.

 

‘’Yatọ si eyi, o tun jẹ nipa kikọ ede, mimọ ede. Eyi si jẹ ohun ti ọpọ wa, iyẹn awọn iran mi, koda titi di onii,pupọ awọn ọmọde ti wọn jẹ Yoruba ni wọn ko le sọ ede Yoruba.

 

Idi ni pe wọn ko sọ ede naa si wọn bi wọn ṣe n dagba, tabi ko jẹ pe ile-ẹkọ ti girama ti wọn ti n pe ede Yoruba ni fanakula ni wọn lọ, ti wọn yoo si jiya rẹ niru ile-ẹkọ bẹẹ. Fun idi eyi, a ni ojuṣe lati jẹ ki awọn eeyan bẹrẹ si kọ ede Yoruba.

 

 Ti emi naa si n kọ awọn ọmọ mi ni ede Yoruba, ko ma lọọ di pe wọn yoo koju iṣoro ti mo koju, eyi to jẹ pe agbalagba ni mo fi n kọ ede Yoruba.

 

‘’Ko si nnkan to buru ju ninu ki a gbe awọn iṣẹṣe wa larugẹ bii Ogun, Ifa iyẹn Ọrunmila, Sango, Óbatala,Ọya atawọn ooṣa mii in larugẹ nitori iṣẹmbaye ni wọn.

 

‘’Ohun ti Ifa jẹ, Odu, eyi to dara ati eyi ti ko dara, ipilẹ rẹ lo bi ẹrọ kọmputa ti a n lo lonii, koda, ohun naa lo bi foonu ti a n gbe dani, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko mọ.

 

 Nigba ti awọn oyinbo alawọ funfun de, ti wọn si kẹkọọ nipa gbogbo ohun ti Yoruba ni, eyi lo jẹ ki awọn naa bẹrẹ sii ṣe oriṣiriṣi ti wọn fi aṣiri rẹ pamọ.

 

‘’Bi awọn obi kan to jẹ pe bi ọmọ wọn ba sọ pe oun fẹẹ lọo ko Ifa, niṣe ni wọn yoo bẹrẹ sii gbadura, ti wọn yoo maa sunkun, ti wọn yoo ni ọmọ naa nilo adura itusilẹ, ṣugbọn awọn nnkan wọnyi ṣe pataki, ti a si gbọdọ ṣamulo rẹ.Awa naa nilo lati gbaruku ti awọn nnkan ibilẹ ati aṣa wa’’

 

Iwadii fi ye wa pe ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin Gbadebọ Rhodes- Vivour atawọn ọba ilẹ Yoruba lapapọ paapaa julọ nipinlẹ Eko, ti wọn ti bi i titi di akoko yii.

No comments:

Post a Comment

Adbox