IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 30 May 2025

Ìdẹ̀rún ọ̀tun yóò dé bá àwọn èèyàn ìjọ̀ba ìbílẹ̀ Ìdàgbàsókè Àpápá-Ìgànmú-Ọnarébù Ọlawálé Jímọ̀h



Oludije fun ipo alaga nijọba ibile onidagbsoke Apapa-Iganmu,labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ọnarebu Ọlawale Jimọh Saliu ti sọ pe idẹkun ati igbe- aye irọrun ọtun  yoo de ba gbogbo awọn eeyan ijọba ibilẹ oun toun ba di alaga ijọba ibilẹ.

Lasiko to n ba akọroyin wa sọrọ, Ọnarebu Ọlawale tawọn eeyan tun mọ si Olugbani 1 ti sọ pe ko si ohun meji toun ṣe fẹẹ toriẹ  di alaga ijọba ibilẹ onidagbsoke Apapa-Iganmu ju pe koun mu idẹrun ati aye to nitumọ ba gbogbo awọn eeyan ijọba ibilẹ oun.

Agba oṣelu naa to tun jẹ oniroyin tawọn mi-in tun mọ si Alfa Jimọh sọ pe gbogbo eeyan lo mọ pe oloṣelu to fẹran awọn eeyan ẹ, toun fi gbogbo igba wa igbe aye to dara fun wọn loun, awọni ilana aye to nitumọ yii loun yoo gunle toun ba ti di alaga.

Ọnarebu Ọlawale, to ti figba kan jẹ igbakeji akọwe ẹgbẹ oṣelu AD  nipinlẹ Eko sọ pe oṣelu ki i ṣe ki eeyan wa nipo bi ko ṣe lati jẹ ki aye rọrun fun gbogbo eeyan. O ni lara ohun ti oun yoo ṣe ni pipeṣe iṣẹ lọpọ yanturu fawọn eeyan, si satunṣe awọn oju ọna, riro awọn opo atawọn ọdọ lagbara ati pi pesẹ awọn ohun amayedẹrun fun gbogbo eeyan.

Ọnarebu Ọlawale to ti figba kan gbe apoti ibo gẹgẹ bi aṣofin waa gbosuba nla fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, awọn agba ẹgbẹ fun bi wọn ṣe fibo gbe e wọle gẹgẹ bi oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC

No comments:

Post a Comment

Adbox