• GBAGEDE WA
  • NIPA WA
  • E KAN SI WA

IROYIN OJUTOLE

  • Home
  • OJUTOLE-TOKO
  • _NIPA WA
  • _IPOLOWO
  • IROYIN
  • LAGBO OSERE
  • ORO TO N LO
  • OSELU
  • ISELE KAYEEFI
  • FUN IPOLOWO +2348080597807

IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 5 May 2020

Home / Unlabelled / Eyi ni itan igbesi-aye Saidi Oṣupa ati bo ṣe di ọga-agba ninu awọn olorin

Eyi ni itan igbesi-aye Saidi Oṣupa ati bo ṣe di ọga-agba ninu awọn olorin

by IROYIN OJUTOLE on May 05, 2020

Lọjọkọjọ tabi nibikibi ti wọn ba ti n darukọ awọn onifuji nla,awọn oṣere fuji ti gbogbo aye fẹran daadaa, o daju saka pe wọn yoo darukọ King Saidi Oṣupa Okunọla Akorede si i. Bo si jẹ onifuji to n kọrin ijinlẹ ede Yoruba ati orin ọlọgbọn ni, wọn ko ni i rin jina rara ti wọn yoo fi darukọ ọkunrin onifuji ọmọ bibi ilu Ibadan yii nitori pe imọ ijinlẹ nla ni Oṣupa fi n gbe orin rẹ kale.

Laipẹ ni akoroyin TAOFIK AFỌLABI ṣe ifọrọwanilẹnuwo raipẹ fun ilu mọ-on ka olorin fuji naa. Diẹ ninu ohun ti Matagbamọlẹ awọn onifuji ba wa sọ ree. 

Fun anfaani awọn ololufẹ wa, a fẹ ki ẹ sọ diẹ fun wa nipa itan igbesi aye yin

Saidi Osupa lorukọ mi, orukọ baba mi ni Moshood Akanji Akorede Ọlaniba, nigba ti orukọ iya mi n jẹ Taibat Abẹni Ọlatokunbọ Adelanwa. Mo ti le ni ẹni aadọta ọdun, mo bimọ, mo si niyawo, pupọ ninu awọn ọmọ mi ni ko si ni Naijiria, mo ti ṣe awọn rẹkọọdu to le ni ogoji. Ko rorun nigba ti mo bẹrẹ, Ọlọrun lo pada fi rọ mi lọrun, nitori pe ohun ti ko ṣẹlẹ ri ni mo n ṣe, ẹni to ba si ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, oju ẹni naa yoo ri ohun ti ẹnikan ko ri ri. Eni to  ba n ta ọja ti awọn eeyan ko ri ri, wọn yoo kan ma a wo o pe ki lo n ta ni, ṣugbọn ti wọn ba tọ ọ wo ni wọn yoo too mọ pe iru ọja to n ta ree, ki wọn too gba a lọwọ ẹ. Ti a ba ni ka sọ ohun ti oju ri, a o ni i kuro nibi loni-in, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun ibi to jẹ ki ọrọ mi ja si.  

Ki lo n ṣẹlẹ si  Saidi Osupa bayii lagboole orin bayii?

Ayọ ni, nitori daadaa lo n bẹ ninu ABD, a ṣẹṣẹ gbe rẹkọọdu wa tuntun ti a pe ni Permutation jade, lati ọjọ Aje, Monde lo ti wa lori igba tawọn ololufẹ wa ti n ko o jẹ kẹtikẹti.

Ki lẹ gba le ro pẹlu akọle ti ẹ fun rẹkọọdu yin tuntun yii?

Itumọ Permutation ni pe ki eeyan pa nnkan tuntun  meji ti ko jọ ara wọn, ki eeyan fi ọgbọn ati oye pa nnkan meji ti ko jọ ara wọn papọ, ohun ti a fi sọ rẹkọọdu wa tuntun loukọ ti a pe e niyẹn.

Ni nnkan bii ọdun meji sẹyin ariwo gbalu pe Saidi Osupa pada sileewe yunifasiti, ki lo fa igbesẹ yii?

Mo wo o pe pupọ ninu awọn akoko ti a fi maa n sinmi nigba mi-in pọju asiko ti a n fi sisẹ lọ, loootọ isẹ pọ daadaa, ṣugbọn o lawọn asiko kan ti ọwọ wa ma a n dilẹ, a n ki saaba raaye lasiko ọdun, mo wo o pe  ki n lo awọn asiko to si silẹ ṣe ohun ti yoo mu ilọsiwaju ba aye mi, dipo ki eeyan kan maa ro ẹjọ ti ko nitumọ gidi laye eeyan.

Ṣe ki i di ara wọn lọwọ sa?

Rara o, loootọ ki i ṣe gbogbo igba ni mo ma n raaye lọ sileewe, mo lawọn olukọ ti wọn n kọ mi nidakọnkọ,ti mo n fun wọn lowo.

Ki lawọn akẹkọọ ẹgbẹ yin sọ nigba ti wọn ri yin ninu ọgba ileewe?

Wọn wo o pe kin ni mo tun n wa kiri, ko si orukọ tawọn mi-in ko pe wa, koda  awọn kan pe mi ni a dagba jẹ Raufuu, ṣugbọn gẹgẹ bi ẹni to mọ ohun to ku ninu ọrọ ẹ, mo mọ pe ohun to ku to yẹ ki n ṣe niyẹn, nitori pe ọjọgbọn nla lo yẹ ki n jẹ ninu iwe, ṣugbọn ẹgbẹ ti mo ko lo gbe mi de ibi ti mo de loni-in. Ohun wu awọn obi mi pe ki n kawee gboye nla ninu ẹkọ, ṣugbọn wọn ko si laye mọ bayii,  mo wo o pe ki n ṣe ohun ti yoo tẹ awọn naa lọrun nigba ti mo ti ṣe ohun to tẹ mi lọrun.

Ṣugbọn, awọn agbekalẹ ọrọ yin ati ede oyinbo yin ko jọ ti ẹni ti ko ti i kawe gboye ni yunifasiti, ọgbọn wo lẹ ẹ da si i?

Ìpìnlẹ̀ lo ṣe pataki ninu aye ọmọ, ipinlẹ gidi ni mo ni, ipinlẹ ọhun to yẹ ki n kọ ile si,ti mi o  ṣe nigba naa ni mo pada ṣe bayii.

Ẹ jẹ ka sọrọ nipa ere ori itage, ti  a ba wo o daadaa Saidi Oṣupa jẹ ogbontarigi ninu awọn elere ori itage, bẹẹ lẹ fẹran lati maa kopa ninu awọn ere ori itage to ni i ṣe pẹlu aṣa Yoruba. Ki lo fa eyi?

Mo jẹ ẹnikan to fẹran lati maa gbe aṣa ati iṣe Yoruba larugẹ ni, ohun to ba ti jẹ mọ aṣa ati iṣe Yoruba jẹ ohun ti mo fẹran pupọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yii lẹ sọ pe ẹ ko raaye ija pẹlu onifuji kankan mọ, bẹẹ lawọn orin yin to ma n le koko naa ti dinku. Ki lo fa igbesẹ yii?

Ki i ṣe pe awa naa jẹ oniwahala, ṣe ẹ mọ pe ti eeyan ba sọ fun eeyan pe ohun to n se ko dara, iru ẹni bẹẹ yoo mu eeyan lọta  ẹ ni. Ẹni to ba bu wa la ma n da lohun ọrọ ẹ, gbogbo iyẹn ko si mọ bayii, ki i ṣe gbogbo aja to ba n gbo leeyan  ma n da lohun.Pupọ ninu orin wa ti ẹ sọ pe o le koko yii, awọn eeyan fi sọ wa lẹnu ni,ida mẹwaa ninu ọgọrun-un lorin wa ti ẹ sọ pe o le koko yẹn, ṣugbọn awọn  ti ko fẹ ti wa lo n sọ wa lorukọ ti ki i ṣe ti wa, karamọ lasan ni wọn n ṣe.

Pupọ ninu awọn ololufẹ yin, ti wọn fẹran yin daadaa ni wọn sọ pe orin yin ki i tete ye awọn

Nitori pe ijinlẹ ede Yoruba to jinlẹ  daadaa la fi n kọ orin wa, a ma n wa awọn ijinlẹ ede Yoruba ti awọn eeyan ko mọ. A n  ṣe eyi lati fi mu ilọsiwaju ati igbega ba ede Yoruba ni.

N jẹ ẹ ti ni i lọkan lati ṣe iwe jade lọjọ iwaju?

Bẹẹ ni,laipẹ ni iwe mi yoo jade, gbogbo orisirisii itan ti mo ti kọ ninu orin mi ni mo fẹẹ fi ṣe iwe yii jade,ṣẹ ẹ mọ pe awọn ọmọ wa ko ri iwe itan ka mọ bayii.  Gomina kan ti a ṣiṣẹ fun ti mo ro pe yoo ran mi lọwọ lori ẹ ko kọ ibi ara si ọrọ mi mọ, ohun to jẹ ki n fi ọkunrin naa silẹ niyẹn, ṣe e mọ pe bi ọrọ oṣelu ṣe ri niyẹn.

             Olorin ni baba to bi yin, ṣe wọn fọwọ si i nigba ti ẹ bẹrẹ?

Wọn ko tiẹ mọ pe mo n kọrin rara, bẹẹ lemi naa ko tete mọ pe wọn kọrin ri, ogo mi ti buyọ daadaa ko too di pe wọn pada mọ. Mama mi nikan lo mọ latilẹ pe mo n kọrin, wọn ko si fọwọ si i, bo tilẹ jẹ pe lati ilẹ mama mi ko fọwọ si i pe ki n kọrin,ṣugbọn ki i fọrọ mi ṣere rara, dokita onimọ ijinlẹ mama mi fẹ ki n jẹ.

Gẹgẹ bi ẹ ṣe ma a n sọ lọpọ igba pe mama yin jiya lori yin, bawo lo ṣe man ri lara yin pe wọn ko si laye mọ?

O ma a n dun mi lọpọ igba, ṣugbọn ko si ohun ti a fẹẹ ṣe si i,a ṣe eyi to wu u ni Ọlọrun.

Awọn ọmọ yin naa n kọrin, ṣe ẹyin lẹ fi ẹsẹ wọn tọ oju ọna orin ni?

Ṣe ẹ mọ pe awọn ọmọde asiko yii ma n wo ohun ti awọn obi wọn n ṣe, ti wọn ba ri i pe awọn obi wọn n ṣe daadaa nidii ohun ti wọn n ṣe yii, ti awọn eeya n bu ọla fun wọn,  awọn ọmọ  naa yoo foju si i,wọn yoo maa ṣe. Ṣe ẹ mọ pe oriṣa ti eeyan ba n ṣe ti ko ba fihan ọmọde yoo ku ni.

Pupọ ninu awọn eeyan ti ko mọyin daadaa,ti wọn ko sunmọ yin ni wọn maa n foju alagidi wo yin. Iru eeyan wo ni Saidi Osupa?

Hu,emi ko le sọ pe iru eeyan ti mo jẹ ree, awọn eeyan ni yoo sọ,  ṣugbọn ọpọ ohun ti  ko ṣẹlẹ nipa mi ni wọn n sọ. Orogun owo ku ohun ti awọn eeyan n sọ nipa mi, sẹ ẹ mọ pe ti ọja eeyan ba n ta ju ti awọn mi-in lọ, wọn ko ni i beere lọwọ ori, ibi ti ọja ti n ta ni wọn n beere,wọn ko beere lọwọ ori ti  boya ẹlẹdaa wọn kọ rọ mọ nnkan naa. Ibajẹ ẹni ti ọja rẹ n ta yii ni wọn yoo maa ṣe, afikun ibajẹ nipa eni naa ni wọn yoo maa gbe e kiri. Loootọ ko  si eni ti yoo ri ohun ibinu ti ko ni i binu, bẹẹ ọmọ ale eeyan ni wọn yoo bẹ ti ko ni i gba, ki i ṣe pe a n ka n ja kiri bii were, nigba ti wọn ko fi nnkan bẹẹyẹn tọ wa lati kekere, ọrọ ibajẹ lo pọ ninu ohun ti wọn n sọ nipa wa.

Ninu gbogbo awọn rẹkọọdu yin, e wo lo sọ yin dolokiki?

Imisi Ọlọrun lo ri rẹkọọdu ‘Master Blaster’ lo sọ mi di olokiki ju, ṣugbọn rẹkọọdu Fuji Blues lo kọkọ mi lu titi, bẹẹ ni London Delight naa gbajumọ daadaa.

Ọkan pataki ninu awọn eeyan ti Alaafin Ọyọ,Ọba Lamidi Adeyẹmi fẹran daadaa ni yin. Bawo ni ajọṣepọ yin ṣe bẹrẹ?

Baba ri i pe mo n gbe aṣa larugẹ ni, wọn mọ pe mo mọ orin ti ọba n jo, mo mọ tijoye, mo mọ orin to tọ lasiko to yẹ, wọn mọ mi gẹgẹ bii olorin to n kọ orin ọlọpọlọ.

Ṣugbọn ohun ti awọn ololufẹ yin n sọ ni pe o yẹ ki ẹyin naa ti joye lỌyọọ. Ṣe ẹ ko ro pe oye tọ si yin ni?

 Huuu, mi o ronu lọ sibẹ ri, ṣugbọn baba ti fi mi joye sẹyin lọdun to ti pẹ, a o beere fun ni, nitori pe ko si ohun ti mo beere lọwọ baba ti wọn ko ni i fun mi.

Ẹnikan ti  awọn eeyan tun mọ pe o fẹran yin daadaa ni gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, bawo lẹ ṣe bẹrẹ ajọṣepọ yin?

Oluwa mi niyẹn, Ọlọrun kan fi ifẹ mi si wọn lọkan ni, mi o mọ ohun ti mo ṣe ti wọn fi nifẹẹ mi, Ọlọrun ni.

Ti ẹ ba wo irin-ajo yin laye, ṣe ohun ti ẹ foju sun lẹri gba mu?

Mo ri i pe Ọlọrun ṣaanu mi pupọ, gbogbo ohun ti awọn kan ṣe laṣeti ni mo ṣe laṣeyanju.  

            Ohun ti awọn kan n sọ ni pe ko si onifuji tuntun to jade lati ọdun pupọ sẹyin, wọn ni ẹyin atawọn onifuji kan tawọn n gbọ lati ọpọ ọdun sẹyin lawọn si n gbọ, eyi ti ko ri bẹẹ fun orin takasufee ti wọn n pe ni hip-hop. Awọn kan tiẹ sọ pe fuji ko ni i pẹ ẹ ku. Ki lẹ fẹẹ sọ si eyi?

Awọn onihip-hop naa mọ pe erunrun orin wa lawọn n kọ, awọn naa n gbiyanju, ṣugbọn  erunrun fuji ni wọn n kọ. Loootọ awọn kan wa ninu wọn ti a mọ pe wọn n gbiyanju ti a mọ pe olorin ni, Ọlorun kan sọ pe ko ya sibi to ya si ni. Ẹrọ ayelujara n tun iṣe ti wọn n ṣe,ṣugbọn  o n ba iṣẹ fuji jẹ ni, ori ẹrọ ayelujara lawọn ti n ta orin ti wọn,eyi ti ko ri bẹẹ fun fuji, onifuji ti yoo ba ta orin  rẹ lori ẹrọ ayelujara gbọdọ jẹ onifuji to lorukọ nla bii temi atawọn ti wọn jẹ sawawu mi.

Ti  ẹ ba wo agboole fuji, ipo wo ni Saidi Oṣupa wa?

Ipo ti Ọlọrun to mi si ni, mi o ki n gbe ara mi ga.         

Tags
Whatsapp
Author Image

Nipa IROYIN OJUTOLE
NJE O NI IROYIN FUN WA BI? TABI O NI AYEYE TI O FE KI A BA O GBE JADE? ABI IPOLOWO OJA TABI IKEDE LE FE SE, TETE PE SORI AWON NOMBA WONYI: 08023939928, 08185819080.

Related Posts:
By IROYIN OJUTOLE on - May 05, 2020
Email ThisBlogThis!Share to XShare to FacebookShare to Pinterest

No comments:

Post a Comment

Newer Post Older Post Home
Subscribe to: Post Comments (Atom)

KI LE N WA?

KARI AYE NI WON TI N KA A

Live Visitors Counter
Powered by Blogger.

AWON TO TI KA OJUTOLE-TOKO

Featured

E KAN SI WA 08080597807

Name

Email *

Message *

Most Popular

  • Ó ṣẹlẹ,Arẹgbẹṣọla ati Gbadebọ Rhode-Vivour fẹẹ fi ẹgbẹ ADC gbajoba   Eko lọwọ   Tinubu ati APC
    Ó ṣẹlẹ,Arẹgbẹṣọla ati Gbadebọ Rhode-Vivour fẹẹ fi ẹgbẹ ADC gbajoba Eko lọwọ Tinubu ati APC
    Pẹlu bí  idibo ọdun  2027ṣe n sunmọ etile ẹgbẹ African Democratic Congress, ADC ti mura lati gba iṣakoso ipinlẹ Eko kuro lọwọ Aa...
  • Saheed Arẹgbẹsọla la n fẹ nipo ọba Isọlọ-Oloye Taorid Farounbi Alado
    Saheed Arẹgbẹsọla la n fẹ nipo ọba Isọlọ-Oloye Taorid Farounbi Alado
    Olori ẹbi Papa Alagbẹji, niluu Isọlọ, nipinlẹ Eko, Oloye Taorid Farounbi ti gbogbo aye mọ si Alado ti rọ gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹ...
  • EGBE  BEBE AANU FUN ORIYOMI HAMZAT
    EGBE BEBE AANU FUN ORIYOMI HAMZAT
    Awon Omo egbe alatileyin fun gbajugbaja gbaja sorosoro  ori radio nni, Alhaji ORIYOMI Hamzat lati orile ede America ati Canada t...
  • GBAJUGBAJA ONiROYIN, OLAIDE GOLD DI IYA IROYIN ILU MEIRAN, NIPINLE EKO
    GBAJUGBAJA ONiROYIN, OLAIDE GOLD DI IYA IROYIN ILU MEIRAN, NIPINLE EKO
    Olaide Aderonke Gold ti gbogbo Ololufe e mo si Olaide Gold di IYA IROYIN fun ilu Meiran ni tile toko ati agbegbe e. Yiniyini ki ...
  • Ìdẹ̀rún ọ̀tun yóò dé bá àwọn èèyàn ìjọ̀ba ìbílẹ̀ Ìdàgbàsókè Àpápá-Ìgànmú-Ọnarébù Ọlawálé Jímọ̀h
    Ìdẹ̀rún ọ̀tun yóò dé bá àwọn èèyàn ìjọ̀ba ìbílẹ̀ Ìdàgbàsókè Àpápá-Ìgànmú-Ọnarébù Ọlawálé Jímọ̀h
    Oludije fun ipo alaga nijọba ibile onidagbsoke Apapa-Iganmu,labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ọnarebu Ọlawale Jimọh S...
  • Ajagungbalẹ yawọ Ketu- Ẹpẹ, ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣe nijamba
    Ajagungbalẹ yawọ Ketu- Ẹpẹ, ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣe nijamba
    Titi di akoko ta a wa yii, ọpọ awọn eeyan ni wọn wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju nitori bi wọn ṣe lawọn ajagungbalẹ ya...
  • E wo Eniowo Odeneye, Ojise Olorun to n fi ede Yoruba waasu loke-okun
    E wo Eniowo Odeneye, Ojise Olorun to n fi ede Yoruba waasu loke-okun
    Ọkan gboogi ninu awọn ọmọ orileede yii ti wọn kopa pataki ati ipa to n gbe ede Yoruba ga loke okun ni Ẹniọwọ Henry A...
  • GONGO SO LOJO TI IYA-N-GHANA, GBAJUGBAJA OLORIN ISLAM SAYEYE OJOOBI, OBINRIN NAA TU ASIIRI NLA KAN NIPA ARA E
    GONGO SO LOJO TI IYA-N-GHANA, GBAJUGBAJA OLORIN ISLAM SAYEYE OJOOBI, OBINRIN NAA TU ASIIRI NLA KAN NIPA ARA E
    Ojo nla ti ilu mo- on ka olorin esin Islam nni, Queen Seidat Bashirat  Ogunremi Olomitutu ti gbogbo aye mo si Iya-n-Ghana ko ni i gbagbe...
  • Wọn fẹẹ fọrọ Afọbajẹ da wahala silẹ nilu Ketu-Ẹpẹ, Ọlọrun lo tu aṣiri wọn- Ọmọọba Adekọya Adefowora
    Wọn fẹẹ fọrọ Afọbajẹ da wahala silẹ nilu Ketu-Ẹpẹ, Ọlọrun lo tu aṣiri wọn- Ọmọọba Adekọya Adefowora
    Ọmọọba Adekọya Babajide Adefowora, ti sọ pe bi ki i ba ṣe pe Ọlọrun ti aṣiiri obinrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Tọpẹ, to gbidanwo lat...
  • Ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to si n fi gbogbo ọjọ aye ẹ wa  ilọsiwaju ìlẹ kootu-oo- jiire- lo maa n joye Ọbalẹfun- Ifa White
    Ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to si n fi gbogbo ọjọ aye ẹ wa ilọsiwaju ìlẹ kootu-oo- jiire- lo maa n joye Ọbalẹfun- Ifa White
                 Laipẹ yii ni oludije ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu 'Labour', nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhod...

Labels

  • BO SE N LO
  • IROYIN
  • KAYEEFI
  • LAGBO OSERE
  • ORO TO N LO
  • OSELU
Adbox

BO SE N LO

ipolowo oja

IROYIN TO GBAJUMO

Created By SoraTemplates | Distributed By Blogger Templates