Gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Alaaja Taiwo Akinwande ti gbogbo aye mọ si Yetunde Wunmi ti sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ foun pe ko si ọkan ninu awọn ọmọ oun to nifẹẹ si ere ori itage. Oṣere yii sọrọ yii nibi eto kan ti orukọ rẹ n jẹ 'Lagbo Irawọ' ti gbajugbaja oṣere tiata nni, Rammy Shitta-bey tawọn eeyan mọ si Adebayọ Ọmọ Iya Aje ma n ṣe lori radio Tungba to wa ni Ikorodu ni Yetunde Wunmi ti sọrọ yii lasiko ti wọn pe e gẹgẹ bi alejo sori eto naa.
Yetunde Wunmi ni ohun to wu oun ju laye ni pe ki awọn ọmọ oun naa jẹ oṣere bii toun, ṣugbọn, ko si eyi to fifẹ han si ere ori itage to sọ oun di olokiki yii.
No comments:
Post a Comment