IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday 6 May 2020

Paul Ọmọ Abúlé ní: Ọdún mọ́kànlá ni mo fi gun ọ́kadá nìgboro Èkó

Ọkan ninu awọn gbajumọ olorin ẹmi lorilẹ-ede yii ni Ẹfanjẹliisi Friday Paul ti gbogbo aye mọ si Ọmọ Abule, odu lọkunrin naa ki i ṣaimọ foloko rara laarin awọn akorin ẹmi, ṣugbọn pupọ ninu awọn ololufẹ ọkunrin yii ni ko mọ pe odidi ọdun mọkanla lọkunrin ọmọ bibi ilu Karanla nipinlẹ Ogun naa fi gun ọkada,to fi ọkada gigun wa ohun ti yoo jẹ.

Funra ẹ Ọmọ Abule tawọn tiẹ tun n pe ni Oluọmọ of Gospel lo tu asiiri nla ọhun fun Gbelegbọ. Ẹ gbọ bo ṣe wi ’ Idile ko la, ko sagbe ni wọn ti bi mi, ohun to gbe mi kuro labule wa niyẹn, ti mo fi dero Eko, bi mo ṣe wọlu Eko bayii, ọkada ni mo n gun kiri ki n too ri ounjẹ oojọ mi jẹ, odidi ọdun mọkanla ni mo fi gun ọkada. Lati Osodi si Abule-Ẹgba ni mo n na nigba naa, ṣugbọn nigba ti ijọba gomina Babatunde Fashọla fofin de wa ni mo fi sa kuro nidii ẹ, mo kọkọ ma dogbọn sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ, nigba ti wahala wọn pọ ni mo ba ẹsẹ mi sọrọ ti mo lọọ darapọ mọ awọn akọrin ijọ ‘Bible Church International’. Ki n ma parọ fun yin, ki i ṣe nnkan kekere ni oju mi ri lasiko ti mo n gun ọkada yii, bẹẹ lọkan mi wa nidii orin, ṣe lawọn ti mo ba gbe ni ọkada ma n beere lọwọ mi pe ṣe olorin ni mi, nigba ti mo ba n korin lori ọkada. Mo dupẹ loni-in pe Ọlọrun pada gbe mi de ibi ogo mi, idi iṣẹ orin ọhun naa ni mo ti di nnkan nla bayi, ti orukọ mi buyọ laarin awọn ẹlẹgbẹ mi’.    

 

1 comment:

Adbox