IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 21 April 2020

Sule Alao Malaika naa ti di oga ileeṣẹ iwe iroyin

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, gbajumọ onifuji nni, Alaaji Sule Alao Malaika  naa ti darapọ mọ awọn to ni ileeṣẹ iwe iroyin. ‘Alayeluwa News’ lọkunrin naa sọ orukọ iwe iroyin naa. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, gbogbo ohun to ba n ṣẹlẹ nipa oṣere ti wọn tun n pe Madiba yii ni yoo maa wa ninu iwe iroyin naa.

 

Gbelegbọ ri i gbọ pe ni nnkan bii  ọsẹ meji ṣẹyin ni iwe iroyin naa gori igba. Bakan naa la gbọ pe gbogbo awọn ololufẹ oṣere ọmọ bibi Ẹgba ti wọn Imẹku Alaaji yii. Gbara ti awọn ololufẹ Malaika ni wọn ti lenu pe gbogbo ọna ni oṣere awọn fi ju awọn olorin yooku lọ, wọn ni Malaika ti tayọ  awọn onifuji yooku pẹlu iwe iroyin to bẹrẹ yii.

No comments:

Post a Comment

Adbox