Sat Guru Maharaj ji
ti wọn n tun n pe ni ‘The Perfect Living
Master’, ti ri ojuutu si arun aṣekupani to gbaye bayii, iyẹn ‘koronafairọọsi’. Father
of the creation bi wọn tun ṣe ma n pe e lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi
ipade awọn oniroyin to waye ni Maharaji ji Village to wa niluu Ibadan lo ti sọ pe asiko
ti to fun arun koronafairọọsi lati fi gbogbo aye silẹ, iyẹn ti awọn eeyan ba gbọ
ohun ti oun sọ fun wọn yii. O ni ohun ti
awọn eeyan nilo lati ṣe ni ki aarun di
ohun igbagbe ki wọn wa isu mẹtadinlogun, ata, omi, epo ati ìgbá, o ni ki wọn
sun isu yii, ki wọn gbe fun ọdọmọde obinrin tabi ọkunrin meji ti ko ti i
balaga, ki kaluku gbe e lọ sidii ooṣa to ba ni igbagbọ ninu ẹ, o ni ti wọn ba
ti ṣe eyi aarun korona yoo di afisẹyin ti eegun alare ma n fi asọ.
Baba yii ni o ṣe
ni laaanu pe arun buruku yii raaye wọle si Naijiria, nitori pe aarun awọn
oyinbo ni, ṣugbọn awọn ijọba wa ni ko mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe ti koronafairọọsi
ṣe wọ Naijiria. Maharaj ji ṣe lo yẹ ki wọn tete ti gbogbo ẹnu ibode to wọ orilẹ-ede
yii, ṣugbọn wọn ko ṣe bẹẹ ti arun naa fi wọle si orilẹ-ede wa. O fi kun ọrọ ẹ pe ohun to buru jai ni bi
awọn ijọba ṣe da awọn eeyan jokoo sile nitori pe iṣẹ ati oṣi n ba awọn eeyan
finra, o ni bi ẹlomi-in ko ba jade lọjọ
kan ko ti i mọ ohun ti yoo jẹ, Maharaj ji ni ijọba tete fopin si ofin ko-nile-o-gbele
ti wọn ṣe yii nitori pe latigba ti wọn ti ṣe ofin yii ni iwa ọdaran ti n gbilẹ
si i.
Bakan naa lo sọ pe ọna ara ọtọ ni ayẹyẹ ọdun mẹtalelọgbọn ti Maharaji ji Village bẹrẹ yoo gba , o lawọn yoo lo asiko naa lati fi gbogun ti arun koronafairọọsi yii. Bẹẹ lo sọ pe gbogbo ẹni ti ko ba fẹ idaamu ati a i balẹ ọkan ko tete gba Maharaj ji sinu aye ẹ, nitori pe ma-ra-ji ni Maharaj j jẹ fun gbogbo aye.
No comments:
Post a Comment