Bimbọ Akisanya ki i ṣe ọmọde ninu awọn obinrin onitiata ilẹ wa, ilẹ ta diẹ si i ti obinrin naa ti wa lagbo awọn elere ori itage, orukọ ẹ ko si lọ silẹ lati bii ogun ọdun sẹyin to ti wa lẹnu iṣẹ naa. Laipẹ yii lobinrin yii tawọn ololufẹ tun ma n pe ni Ọmọ Ọlọja ninu fiimu ba wa sọrọ. Lasiko ifọrọwerọ raipẹ ti a ṣe pẹlu ẹ lo ti sọ awọn nnkan mi-in ti ọpọ ko mọ nipa ẹ, paapaa idi to ṣe wa lẹyin Pasitọ Biọdun Fatoyinbo ti wọn fẹsun agbere kan nigba kan. Bi ifọrọwerọ ọhun ṣe lọ ree
Daadaa ni, a o niṣẹ meji ju ere ori-itage naa lọ, mo ṣẹṣẹ kuro loko ere kan niluu ikorodu ni, a si n mura fun omi-in bayii.
Ṣugbọn ohun ti a ṣakiyesi ni pe oju yin safẹrẹ nidii ere ori itage lawọn asiko kan, ki lo ṣẹlẹ?
Asiko kan wa ti mo wa niluu oyinbo, mi o kopa ninu awọn fiimu wa mọ nigba naa, nigba ti mo tun pade ni Ọlọrun fun mi lọmọ, sẹ ẹ mọ pe gege bii abiyamọ gidi, eeyan gbọdọ mojuto ọmọ ẹ, ọmọ mi si kere di bi a n ṣe n sọrọ yii, ohun to fa a niyẹn. Ṣugbọn bayii, nnkan ti yatọ si daadaa.
Gẹgẹ bi elere ori itage to ti bẹrẹ tipẹ, iyatọ wo lo wa laarin igba ti ẹ bẹrẹ ati asiko yii?
Ha, ṣe ẹ mọ ọlaju ti yatọ si bi o ṣe wa tẹlẹ, nnkan ti dara si i, imọ ẹrọ paapaa ti ran iṣẹ wa lọwọ ju igba ti a kọkọ bẹrẹ lọ. Gbogbo wa la n ṣe daadaa atawọn tode asiko yii naa.
Orukọ ti awọn ololufẹ yin maa n pe yin Ọmọ Ọlọja, Bimbọ lawọn obi yin sọ yin, iyatọ wo lo wa ninu Bimbọ ati Ọmọ Ọlọja?
Iyatọ to pọ ni, oju ti awọn eeyan fi ma n wo mi ni oju alapẹpẹ, Aṣẹwo ati alapẹpẹ ni Ọmọ Ọlọja, ṣugbọn eeyan jẹẹjẹẹ ti ko fẹ wahala rara ni Bimbọ, a yatọ si ara wa daadaa.
Ki lawọn obi yin sọ nigba ti ẹ bẹrẹ tiata?
Baba mi lo fọwọ si i,mama mi ko fẹ ki n ṣe tiata rara, o ṣe mi laanu pe baba to fọwọ si i gan-an ti jade laye ki n too lorukọ nidii iṣẹ naa, mama mi lo n jeere ẹ bayii.
Ṣe awọn ohun ti ẹ foju sun nigba ti ẹ fẹẹ bẹrẹ tiata lo ti ṣẹlẹ si yin bayii?
Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o gba fun mi ju ohun ti mo foju sun lọ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun.
Ṣe e le gba ki ọmọ yin ṣe tiata lọjọ iwaju?
Ki i ṣe ohun to wu mi lọkan ki ọmọ mi ṣe, ṣugbọn to ba ṣọ pe ohun ti oun fẹẹ ṣe lọjọ iwaju niyẹn, mo ma a tọ ọ sọna, mo si maa fi sọwọ Ọlọrun, ṣugbọn ti Ọlọrun ko ba fọwọ si i, mi o ni jẹ ko ṣe e.
Fiimu meloo lẹ ti gbe jade funra yin?
Mo ṣe agbara ifẹ, mo ṣe sọkọ-sale, bẹẹni mo ti kopa ninu ọpọ fiimu.
Lara awọn eeyan to wa lẹyin pasitọ Biọdun Fatoyinbo ti wọn fẹsun ifipa-bani-lo pọ niyin, ki lo fa a?
Mo fi akoko sọ fun yin pe mi o mọ Pasitọ Biọdun Fatoyinbo ri, mi o bawọn sọrọ ri, di bi a ṣe n sọrọ yii, mi o ri wọn ri,nigba ti ọrọ ifipa-bani-lo-pọ yii waye ni mo too gbọ orukọ wọn, ṣugbọn mo jẹ eeyan kan to ma n tẹ le ohun ti ọkan rẹ ba sọ fun un, bẹẹ ni mo ni ibẹru Ọlọrun gan-an.
Mi o ni tori pe gbogbo awọn eeyan ti wọn jẹ gbajumọ bii temi wa lẹyin Busọla to fẹsun kan pasito Fatoyinbo, kemi naa waa to si ẹyin wọn, ibẹrun Ọlọrun ni mo fi n ṣe nnkan temi. Mi o gba ohun ti ọmọbinrin sọ gbọ rara, ẹyin naa ẹ gbọ bo ṣe ṣalaye, o ni inu ile baba oun to tobi daadaa, ti ẹgbon tabi aburo oun wa nile ni Pasitọ Fatoyinbo ti fipa ba oun lo pọ, ohun akọkọ ti mo beere ni pe ki lo de ti Busọla ko pariwo ki aburo tabi ẹgbọn ẹ yii gbọ nigba ti wọn fipa ba a lo pọ yii, nigba ti ki i ṣe ọmọde. Ẹlẹẹkeji ni pe o tun sọ pe pasitọ naa jade lọọ mu ọti ẹlẹrindodo ti wọn n pe ni krest wa lati inu mọto ẹ, Busọla ko dide lati tilẹkun, ko pariwo ki awọn to wa ninu ile gbọ. O tun sọ pe o fipa ba oun lo pọ lori mọto, bawo ni yoo ṣe tun sunmọ ẹni to ti kọkọ fipa ba a lo pọ ninu ile wọn. Loootọ mi o si nibẹ nigba ti gbogbo ọrọ yii ṣẹlẹ, ṣugbọn ohun to da mi loju ni pe wọn fẹra ri, ṣugbọn pe o fipa ba a lo pọ, emi o gbayẹn laelae.
Awọn kan sọ pe ṣe o ye ki pasitọ ni ọrẹbinrin, ohun ti a n sọ yii ti ṣẹlẹ ti pẹ, iwe mimọ si sọ fun wa pe Ọlọrun ni oun ko fẹ iku ẹlẹṣẹ, a fi ko ronu pi wada.Inu mi dun pe ile-ẹjọ da pasitọ Biọdun Fatoyinbo lare, koda mo sariya ẹ lori erọ ayelujara, gbogbo awọn ẹbi obinrin yii ni ko tẹ le lọ sile-ẹjọ lasiko tigbẹjọ naa waye.
Ka ni ẹ o ṣe tiata, iṣẹ wo lẹ o ba ṣe?
Haa, mo fẹran iṣẹ ologun, Navy tabi Air force, mo fẹran iṣẹ naa daadaa
No comments:
Post a Comment