IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 18 April 2020

Eyi ni itan igbesi-aye YK Ajao, Profẹsọ awọn olorin

Proffesor YK Ajao ki i ṣe olorin kekere lorilẹ-ede  yii, lọjọkọjọ ti wọn ba n darukọ awọn olorin nla nilẹ yii, o daju pe wọn yoo darukọ baba oludasilẹ orin juju makosa yii si i.

Laipẹ yii ni baba ọmọ bibi ilu Iṣẹyin, nipinlẹ Ọyọ ba wa sọrọ, ọjọ naa lo ṣalaye bo ṣe di olorin, awọn ohun ti oju ẹ ri.

Ẹ wo o, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ, o jare, ẹ wa nnkan fidile, ki ẹ gbadun ara yin pẹlu ifọrọwerọ ti a ṣe pẹlu Proffesor awọn olorin.     


Professor YK Ajao lọpọ awọn eeyan mọ yin si, ṣugbọn nitori awọn ti ko mọ orukọ tawọn obi sọ yin, ẹ darukọ yin fun wa lẹkunrẹrẹ

Emi ni Yẹkeen Kọlawọle Ademọla  Ajao Ajeigbe ti gbogbo aye mọ si Professor Y.K Ajao, emi naa ni wọn n pe ni Juju Makosa King

Ta a ni Y.K Ajao,  ẹ ṣalaye fun wa nipa yin

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ọmọ bibi ilu Isẹyin nipinlẹ Ọyọ ni mi, wọn bi mi ni nnkan bii ọdun marundinlaaadọrin ladugbo ti wọn n pe ni Koso, nilu Isẹyin. Mo kawe mẹfa,mo si tun ka eyi ti wọn n pe ni ‘modern school’, ibẹ la ti duro.

Bawo niṣẹ orin ṣe bẹrẹ, ṣe idile olorin ni wọn ti bi yin?

Ohun ti mo mọ ni pe ohun ti eeyan ba fẹẹ ṣe laye lati ode ọrun ni yoo ti mu un wa, nipa ibeere ti ẹ beere pe ṣe idile boya idile olorin ni wọn ti bi mi, ọna meji lo pin si, mo le sọ pe idile olorin ni wọn ti bi, mo si le sọ pe awọn obi mi ki i ṣe olorin. Ohun to jẹ ki n sọ pe idile olorin ni wọn ti mi ni pe baba to bi baba wa, ti wọn jẹ Yusuf Ọlatunji tawọn eeyan tun n pe ni Baba lẹgba, baba baba wa ni wọn, agboole Nisabi  nile wa ni wọn ti bi i, Ọmọ Nisabi ti wọn n pe wọn yẹn, ki i ṣe Lisabi ti Abẹokuta, Onisabi ni Iṣẹyin ni.

Mo si tun fẹẹ fi asiko sọ fun yin pe ọmọ agboole Nisabi yii kan naa ni iya ọmọ mi to n kọrin Islam, iyẹn Abdulakbiri Alayande Ere Asalaatu,agboole kan naa ni gbogbo wa ti jade.

Lati kekere ni mo ti fifẹ han si iṣẹ orin, lati igba ti mo wa ni ọmọ ọdun mẹsan-an ni mo ti n tẹle awọn olorin juju, iyẹn lati ọdun 1970, ko too di pe mo wa si Eko lọdun 1971. Elere ti  mo kọkọ darapọ mọ ni ọga mi ti orukọ wọn n jẹ Captain R. Ade,wọn ti doloogbe bayii, ọmọ bibi ilu Ibadan ni wọn, ọdọ wọn ni mo ti kọkọ kọ bi wọn ṣe n ta gita,lẹyin ti mo kuro lọdọ wọn ni mo lọ si ọdọ Captain Olu,oun naa kọ mi ni gita, ko too di pe mo lọ sọdo Oloye A.U.S Abiọdun, awọn naa kọ mi ni gita. Oṣu kejila, ọdun 1973 ni mo da duro,ti mo da ẹgbẹ temi silẹ, ti mo  pe orukọ ẹ ni ‘YK Ajao and his Proffesional Band’, ko too di pe mo gba oye profẹsọ.

Nigba ti ẹ kọkọ bẹrẹ iṣẹ orin, iha wo lawọn obi yin kọ si i?

Wọn ko gba rara, mo fẹẹ fi asiko sọ fun awọn obi pe iṣẹ ti ọmọ ba ṣọ pe oun fẹẹ ṣe, keeyan ma di i lọwọ ka bẹ Ọlọrun fun un, ti ki i ba ti ṣe iṣe ole, baba temi ko gba rara.Ṣe ẹ ri YK Ajao ti mo n jẹ yii, mo yọ orukọ naa lati inu Yẹkeen Kọlawọle  Ajao ni, nitori pe wọn ko gba ki n fi orukọ wọn si iṣẹ orin ti mo n ṣe, ṣugbọn nigba ti nnkan ti n lọ daadaa fun mi,ti awọn naa ti ri iyi,ẹyẹ ati aponle to wa nidii iṣẹ orin,wọn ni n yi orukọ yẹn pada si ti wọn, ṣugbọn ẹpa ko ba oro mọ.Ṣe e mọ pe ti mo ba sọ pe mo fẹẹ yi orukọ ẹgbẹ pada yoo mu ifasẹyin wa fun wa, ṣugbọn gbogbo iranlọwọ ti baba le ṣe fun ọmọ ni wọn ṣe pẹlu adura gidi ni wọn fi ran mi lọwọ, o tun wa jẹ ki n ohun gbogbo lọ daadaa.

Ọdun wo lẹ kọkọ gba ere laye yin?

A o ki n da ere gba nigba yẹn, ẹni to ba ni awọn irinṣẹ lo ma n gba ere fun wa,oun ni yoo dabii adari, ohun to jẹ ka wa labẹ baba wa kan ti wọn n je Laspama, Baruwa lorukọ wọn gangan, Bamigbose ni won gbe lEkoo, awọn ni wọn gba ere fun wa.

Nigba ti e de ilu Eko, bawo lẹ ṣe n lo igbesi aye?

Ko rorun rara,ibi ti ilẹ ba sun mi mo ma n sun si, igba ti mo kọkọ wa si Eko, omọọdo ni mo ṣe lọdọ ọmọ Ibo kan, igba ti iya yii pọ ni baba mi waa mu mi.

Ọdun wo lẹ kọkọ gbe rẹkọọdu jade?

Ọdun 1973, ‘Sọrọ-mi-dayọ-Oluwa’ lorukọ rẹkọọdu naa, awọn eeyan ko fi bẹẹ gba  rẹkọọdu yẹn, ṣe ẹ mọ pe bi eeyan ba ṣe  rẹkọọdu akọkọ tawọn eeyan ba tẹwọ gba a, ẹni naa ko ni i ṣe ju mẹta lọ ti yoo fi kogba wọle. Mo se to rẹkọọdu mẹrinlelogun kawọn eeyan too gbọ  orukọ mi.

Professor ti wọn n pe yin, ki  lo fa orukọ naa?

        Baba wa Art Alade ni won fun mi lorukọ naa, nigba naa wọn a ma n ṣe ere kan ni eti okun ni gbogbo alẹ ọjọ Satide, awọn elere maa n pọ nibẹ, bi mo ṣe di asiko temi lawọn eeyan sọ pe emi lawọn n fẹ ninu gbogbo awa olorin mẹrin ti a wa nibẹ. Ọjọ naa ni baba yẹn sọ pe iwọ ọmọde yii, wa a di purọfẹsọ awọn olorin,wọn ni, mo sọ ẹ di purofẹsọ awọn olorin lati oni lọ. Bi orukọ naa ṣe di ohun ti wọn fi n pe wa doni-in ree.

Ko si bi wọn yoo ṣe darukọ yin,ti wọn ko ni i darukọ Sir Shina Peters, bawo lẹ ṣe pade?

 

Ko too dipe o da ẹgbẹ orin rẹ silẹ, ni gbogbo igba to wa lẹyin baba wa Prince Adekunle ni mo ti fẹran ẹ, mo fẹran mo ṣe maa n ta gita, nitori pe mo fẹran gita gan-an, latigba naa la ti jọ n ṣe diẹdie, mo maa lọ sibi ti wọn ba ti ṣere,oun naa maa n wa si agbo mi,bi a ṣe di ọrẹ niyẹn.

Ọdun wo lẹ kọkọ lọ siluu oyinbo, bawo lo ṣe ri lara yin?  

   Ọdun 1973,ilu London ni mo kọkọ lọ, mi o lọọ kọrin nigba naa, ọdun 1978 ni mo kọkọ lọ sere nillu oyinbo, mo ti lọ si Amẹrika naa atawọn ilu mi-in

Rẹkọọdu meloo lẹ ti gbe jade?

Gbogbo ẹ jẹ mẹtadinlọgbọn, yatọ si eyi ti a ṣe fawọn ẹgbẹ to jẹ pe a gbe fun wọn ti n ta a laarin ara wọn

Ọjọ wo ni inu yin dun ju nidii iṣẹ orin?

Ọlọrun ti ṣe ọpọlọpọ oore to mu inu mi dun fun mi nidi isẹ orin, lọjọ ti mo kọrin fun baba wa Ọbasanjọ inu mi dun, lọjọ ti mo kọrin fun Ọba Oyekan, inu mi dun lọjọ ti mo ṣere fun Ọgagun Buba Marwa, Ṣugbọn lọjọ ti inu mi dun ju lọjọ Arabinrin Ambibọla Fashọla, obinrin akọkọ nipinlẹ Eko ṣaponle fun mi. Ohun to ṣẹlẹ ni pe wọn wa sibi ti a ti n ṣere, mo lọọ ki wọn bi wọn se ri mi, ni wọn sọ pe haa,Ọnku YK, ẹyin lẹ fẹẹ kọrin nibi, se ni wọn dide nibi ti wọn jokoo si, ti wọn wa ki mi loju agbo, inu mi dun pupọ.

Ọjọ ti a n ṣere nibi kan ti Gomina Alao Akala, gbọ pe emi ni mo n kọrin, wọn ti rin jina, bi wọn ṣe gbọ ohun mi ni wọn pada pẹlu gbogbo awọn eeyan ti wọn tẹle wọn, ẹsẹ ni wọn fi rin wa ba  wa lori ibi ti a ti n kọrin lọjọ naa. Ọjọ ti inu mi tun dun laye lọjọ ti baba wa, Asiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ri wa nibi ti a ti n kọrin, wọn wa ninu mọto pẹlu awọn eeyan nla nla bi mo ṣe darukọ mi bayii pe emi ni mo n ki wọn ni wọn bọ silẹ ninu mọto, ti wọn jo niwaju mi,ti wọn fun mi lowo, nitori pe wọn ti mọ mi daadaa tẹlẹ

Meji ninu awọn ọmọ yin lawọn naa kọrin juju, bawo lo ṣe ri lara yin?

Ha, inu mi dun pupọ, ti wọn ba n kọrin,orin wọn maa pon mi le,ti awọn eeyan yoo wa ba mi pe ‘ YK, awọn ọmọ ree, ku oriire           












 


No comments:

Post a Comment

Adbox