Laipẹ yii lọkunrin naa ṣalaye fun wa nipa irin-ajo rẹ nidi iṣẹ iṣegun, bo ṣe n ṣe e lati ọpọlọpọ ọdun to ti wa lẹnu iṣẹ naa ati ohun ti ko sọ fun oniroyin kan ri laye. Ẹ ka ohun to ba wa sọ.
Ẹ jẹ ka mọ itan igbesi aye yin
Orukọ mi Ọlayẹmi Lateef ti gbogbo aye mọ si Dokita Kolaq, emi ni alase ati oludari ileese ‘Kolaq Nigeria Limited’, ileeṣẹ to jẹ gbajugbaja nipa ka fi ewe, egbo, eso ti Ọlọrun da si orile-ede wa ka fi ṣe ‘capsule, ka fi ṣe oogun olomi, ka fi ṣe oogun alatike, ko si jẹ iwosan fun oriṣiriṣii ipenija nipa ilera ti a n ko ju ninu ile wa.
A bi mi lọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 1962 si orile-ede Naijiria, nipinlẹ Kwara, nijọba ibilẹ Ọffa. Orukọ baba mi ni Ọlayẹmi Akanno, mama mi ni Saadat Abẹbi, emi ni ẹnikẹrin ninu awọn ọmọ wọn, ipo kẹrin ni mo wa, mo dupẹ fun Ọlọrun
Bawo lẹ ṣe bẹrẹ iṣẹ iṣegun?
Awọn agba bọ, wọn ni bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba, arọba si ni baba itan, gẹgẹ bi itan ti mo gbọ, baba to bi mi ki i ṣe oniṣegun ibilẹ lati ilẹ, awọn ohun to koju nipa ohun to n wa lo sọ ọ di oniṣegun. Kin ni baba mi n wa nigba naa? Nitori igbagbọ wa nilẹ eeyan dudu ni pe bi a n ba n wa ọmọ ti a ko ba a ti i bi ọmọkunrin, a o o ti i ni arole, a gbagbọ pe iru baba ẹ bẹẹ ko ti i ni ọjọ ọla, iṣoro ti baba mi ba pade niyẹn.
O bi ọbinrin lakọọkọ, o duro, o tun bi ọkunrin le e, iyẹn ku, o bi ọkunrin mi-in le e, iyẹn naa tun ku, lẹyin ẹ lo bi obinrin mi-in, tiyẹn duro, ọkunrin meji mi-in ni wọn tun ku, ohun to sọ baba mi di oloogun niyẹn, o wo o pe ọmọkunrin yii ko tun gbọdọ ku, gbogbo ọna ni baba mi gba lati ri i pe mo duro, ko si orukọ ti wọn o ki i n pe mi, awọn mi-in ma n pe mi ni ta ogiri nipa a, bẹẹ lawọn mi-in ma n pe ni Inu mi dun ati o ti ji. Itan sọ pe lẹyin ọjọ mẹjọ ti wọn bi mi mi o sunkun, nitori ẹ ni wọn ṣe sọ pe ki wọn ma a gbe mi lọ sile nitori mo kere pupọ, bi baba mi ṣe gbe mi lọ sile niyẹn to bẹrẹ si ni i lo awọn oogun to ti lo fun awọn ọmọ to ti bi ti wọn ku, ohun to sọ baba mi di oloogun niyẹn, iṣẹ aranṣọ ni wọn ṣe laarọ ọjọ.
Latigba naa ni wọn ti sọ baba mi ni alagunmu, mo ti kiri agbo ri ni Kaduna, ti mo ba sọ pe mo jogun ẹ bi ẹ ṣe beere ko si irọ nibẹ, ṣugbọn lẹyin ti mo kuro lọdọ wọn mo tun tẹ siwaju ninu ẹkọ nipa iṣegun ibilẹ, mo lọ si ọdọ oloogun kan ni Kaduna ti wọn n pe ni Buka , mo tẹlẹ wọn, lẹyin ẹ ni mo pada si Kwara, mo kewu, mo si tun kọ iṣegun nibẹ. Bakan naa ni mo lọ sileewe ‘Lagos State School of Natural Medicine’, to wa ni Kofo Abayọmi nipinlẹ Eko, mo kọ iṣẹ isegun, bẹẹ ni mo tun jogun ẹ, ajogunba ni, mo si tun kọ ọ.
Igba wo lẹ bẹrẹ ileeṣẹ Kolaq?
Mo bẹrẹ iṣẹ iṣegun lojule keji, opopona Ayọka, ni Bariga, ipinlẹ Eko, emi ati ẹgbọn mi kan ti wọn ti di ọba bayii la jọ da ọfiisi naa silẹ, lẹyin ẹ ni mo tun ni ọfiisi kan pẹlu ọrẹ mi kan ni Gbagada, orukọ Kolaq ko ti i wa saye nigba naa, nigba to ya a ni mo tun pada si Bariga lopopona Jagunmolu lati tun gba imọ si i lọdọ oniṣegun kan. Lẹyin ti mo pari nibẹ ni lọọ gba ọfiisi si adugbo ‘University Road’ ni Yabaa, ibẹ ni mo ti sọ ileeṣẹ mi ni Kolaq, ṣugbọn ki n too sọ orukọ yẹn ni mo ti kọ orisiriisi orukọ ti mo fẹẹ jẹ sinu iwe, ẹmi sọ fun mi pe ki n ma mu un awọn orukọ yẹn lọọ ba ẹnikan kan boya aafa, wolii tabi oniṣegun, nitori pe olukaluku wọn sọ kan sọ tiẹ ni. Gbogbo orukọ yii ni mo mu lọ siwaju kaaba ni Mẹka, orukọ meje ni mo kọ ni meji-meji sinu pepa bii igba ti wọn ba fẹẹ mu ajọ, ti a ba ti ṣe ohun ti wọn n pe ni tafaafu tan, ti mo pada si Kaaba, mo ma mu ọkan ninu orukọ naa maa sọ ọ nu, bi mo ṣe n ṣe to fi ku orukọ meji niyẹn, mo sọ fun Ọlọrun pe orukọ ti mo ba mu yii ki n fi ṣe nnkan rere nidii iṣẹ iṣẹgun.
Mo ni aafaa nla kan ti wọn jẹ sheu nla,wọn wa lara awọn aafaa ti mo ni igbagbọ ninu wọn, mo mu orukọ meji yii siwaju wọn la i yẹ eyi ti mo mu pada lati Mẹka wo, mo ni ki wọn fun mi lorukọ ti n ma a jẹ, baba yii jẹ olootọ eeyan ti ki i gbowo lọwọ eeyan, ohun ti wọn ba si sọ bẹẹ ni yoo ri, ko si iṣoro ti eeyan gbe de iwaju wọn ti ko ni i ri ojuutu si. Wọn beere orukọ mi ati oruko iya mi, mo sọ fun wọn, wọn wọ inu ile lọ, bi wọn ṣe pada de ni wọn sọ fun mi pe ko si eyi ti ko dara ninu awọn orukọ meji ti mo kọ wa yen, wọn ni ki n mu eyi to wu mi ninu ẹ, ohun ti mo sọ fun wọn ni pe Kolaq yẹn lo wu mi, wọn ni ki n mu un, nigba ti mo maa mu orukọ meji ti mo ko wa lati Mekka jade, Kolaq yii lo wa ninu ẹ, mi o mọ ohun ti mo mu tẹlẹ, baba yii ko si mọ orukọ ti mo kọ sapo, o ya mi lẹnu nigba ti orukọ meji to wa lapo mi jẹ Kolaq, Bi orukọ yii ṣe duro lati ọdun 1994 niyẹn ti mi si boju wẹyin mọ.
Lati igba ti ẹ bẹrẹ, awọn aṣeyọri wo lẹ ti ṣe nidii isẹ yii?
Lati ọdun yii naa ni mo ti n ṣe ipolowo ninu awọn iwe iroyin, ọkan ninu awọn ipolowo ti mo ṣe ni ọkunrin ara ilu oyinbo kan ti ri nomba mi. Ohun ti ọkunrin naa sọ ni pe dokita oun niluu oyinbo sọ pe ko si ẹyin kankan ninu atọ oun, o lawọn naa ti na ọpọlọpọ milinọu sori ẹ, o ni oun ati iyawo oun wa si Naijiria lati waa gba ọmọ tọ ni. Mo ni ko jẹ ki n gbiyanju wo, bi mo ṣe bẹrẹ niyẹn,ti mo fun un loriṣiriṣi agbo, mo sọ fun un pe lẹyin ọsẹ kan to ba ti lo awọn ohun ti mo fun un yii, ko lọọ ṣayẹwo boya atọ rẹ yoo lẹyin ninu tabi ko ni i ni. Nigba ti Ọlọrun yoo gbe ogo fun ọlẹ mi, lẹyin ọsẹ meji to lo awọn ogun ti mo fun un yii ni ayẹwo sọ pe ẹyin ti wa ninu atọ rẹ, atọ ti ko lẹyin ninu rara tẹlẹ, ayẹwo yii lo fi ranṣẹ si dokita ẹ niluu oyinbo, iyen ni ko le e ṣee ṣe, o ni ohun ko gba ayẹwo naa gbọ,o ni ki wọn lọọ ṣe nibo mi-in . Gbogbo ayẹwo ti wọn ṣe lọna mẹta bakan naa lo ri. Ohun ti ọkunrin yẹn sọ fun mi ni pe oun fẹ lọ si Portharcout, nigba to de lọọ gbe owo nla yii wa fun mi, mo fẹẹ ya were nigba ti mo gba owo yii, tilẹ fi mọ mi o le sun, se ni mo duro loke ile ti mo n sọ gbogbo ẹni ti yoo wole, owo naa le ni miliọnu meji, mi o ri ru owo naa ri laye mi. O tun fun mi ni mọto bọginni ti wọn n pe ni lexus, ti mo ba n kọja lọ lasiko naa, ṣe lawọn ọmọ Ibo ma n fi ọwọ ra mọto naa ti wọn yoo maa fi pa ori wọn pe ki Ọlọrun ṣe iru oore bẹẹ fun awọn.
N jẹ asiko kan wa ti iṣẹ yii su u yin?
Asiko ka wa to fẹẹ su mi,asiko kan wa ti mo si ile ounjẹ, ṣe ni mo beere lọwọ ara mi pe ṣe ori mi pe sa, ṣe ni mo sa kuro nidii ẹ ti mo pada sidii iṣẹ iṣegun mi.
Awọn wo lawokọse yin nidii iṣẹ yii?
Mo maa n sọ kinni kan ti ẹda yoo ba la laye yii, awọn eeyan to ba n ba rin ṣe pataki, awọn igbesẹ to ba n gbe ṣe koko. Awọn eeyan ti mo n wo naa ni Baba Aafin ati Dokita Awoṣika, wọn wa ninu awọn to ja fun iṣe iṣegun to fi fẹsẹ mulẹ, ṣugbọn mo ni kinni kan laye mi, mi o ki n gba pe ẹnikan lowo ju mi lọ tabi dara ju mi lọ ni gbogbo ọna. Ohun ti mo ma n ro o nigba naaa ni pe ko si ọna ti awọn dokita oloyinbo fi dara ju wa lọ, nitori pe a jọ n tọju awọn eeyan ni. Bi mo ṣe lọ si ọsibitu awọn oniṣgun oyinbo niyẹn,ti mo wo bi wọn ṣe se ileeṣẹ wọn, ohun ti emi naa ṣe nigba naa niyẹn,to fi jẹ pe ẹni to ba de ọfiisi mi, yoo ro pe oniṣegun oyinbo ni mi. Awọn oniṣegun oyinbo ni mo n wo lawokọse nigba naa ki i ṣe awọn oniṣegun ibilẹ. Mo pọn iṣe mi le nigba naa, itosi geeti ‘Unilag’ lọfiisi mi wa nigba naa, ṣe lawọn akẹkọọ ma n wo mi nigba naa, ti wọn yoo sọ pe ẹ wo ọmọkunrin to rẹwa yii to n ṣe babalawo.
Ṣe ajọṣepọ wa laarin ẹyin ati awọn oniṣegun oyinbo?
Ko sija laarin wa, ki la fẹẹ ja fun, a jọ n tọju awọn eeyan ni, ko si iyatọ laarin wa, oniṣegun ibilẹ to ba sọ pe ohun ko ba awọn oniṣegun oyinbo ṣe oun lo mọ, ko sija laarin wa rara.
N jẹ awọn aisan kan wa ti agbara ẹyin oniṣegun ibilẹ ko ka?
Ko si ohun ti ewe ati egbo ko le ṣe, aisan ti awọn oniṣegun oyinbo ko ba ti ri ojuutu si,awa naa ko i ri i, awọn eeyan n ku sọdọ awọn naa.
Kin ni ero yin nipa oju ti awọn ẹlẹsin fi n wo ẹyin oniṣegun ibilẹ, igbagbọ wọn ni pe ohun ti ẹ n ṣe ko ba ẹsin mu
Ẹ ṣeun pupọ, iyatọ wa laarin babalawo, abọriṣa ati oniṣegun ibilẹ, bi mo ṣe wa yii, mi o mọ bi wọn ṣe n ta epo sori ẹkọ ti wọn yoo gbe ẹkọ si orita, mi o mọ bi wọn ṣe n sin gbẹrẹ fun eeyan. O ko le e pe mi ni oloriṣa ti mo ba mu ewe efinrin, ewuro,abeere ti mo pa mẹtẹẹta pọ fun agbo jẹdi, ko wa a sọ pe ẹlẹbọ ni mi, nitori pe mo ba ẹ fi ewe tọju idi rẹ ti o n yọ, ki i ṣe iya ati baba mi lo da ewe ati egbo. Oogun iba ni ewedu, oogun ni kukumba, bi ẹyin naa ba le jẹ gbogbo eleyii ninu ile yii, ti emi naa ba pa ewe ati egbo pọ pa a pọ ti mo rọ sinu igo ti ẹ wa a sọ pe mo ṣoogun, ewe ati egbo wa ninu kuraani ati bibeli, koda oogun oyinbo ti ẹ n lo, ewe ati egbo ni wọn fi kẹmika si lara. Ohun to wa ninu awọpa lo wa ninu oogun iba oyinbo ti ẹ n lo. Ọpọ abuku ni erọ ayelujara n mu ba iṣẹ wa yii, ẹlomi-in yoo kan lọ si ọdọ awọn elewe ọmọ lati ra agbo,yoo di i sinu lailọọnu, yoo gbe si ori intanẹẹti pe o n wo gbogbo arun. Mo fi orukọ bo ọkan ninu awọn oṣere wa lorukọ, ṣe lo gbe ewe ati egbo kan sori ẹrọ ayelujara to ni o n wo aisan bii mẹwaa la i kọṣẹ iṣegun, eleyi ko dara to.
Gẹgẹ bii gbajumọ oniṣegun ibilẹ, ẹ wo ninu awọn ọmọ yin lo n ṣe iṣegun?
Bẹẹ ni, iṣẹ ti mo fi le awọn ọmọ lọwọ ni, koda wọn gbona ju mi lọ, gbogbo awọn ọmọ ni wọn ṣe iṣẹ yii,ọkan ninu ni Kolaq herbal Solution, ọmọ kan naa ni Kolaq Alagbo, Kolaq Beauty Care, gbogbo wọn ni wọn ni ọja wọn ti wọn n ta kaakiri, ti wọn ṣe daadaa laarin awọn ẹlẹgbẹ wọn.
No comments:
Post a Comment