IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 19 April 2020

Bukky Blacky onítiátà, dàràbà nínú àwọn aṣerunlọ́sọ̀ọ́ ni Germany


 

Gbogbo awọn eeyan  ti wọn fẹran lati maa wo fiimu Yoruba ni wọn n beere pe ibo ni ọkan ninu awọn oṣere Yoruba wa, Bukky Babalọla tawọn ololufẹ ẹ mọ si Bukky Blacky  wọlẹ si, wọn ni ilẹ ta si i tawọn ti gburo obinrin naa ninu awọn fimu to jade, bẹẹ lawọn mi-in beere boya oṣere ọmọ bibi ipinlẹ Kwara naa ko ṣe fiimu mọ ni. Ibeere ti ọpọ eeyan n beere yii lo fa a ti Ojutole fi ṣewadii lati mọ ibi bi Bukku Black wa ati ohun ti obinrin  to dudu daadaa naa n ṣe lọwọ bayii.

 

Ninu iwadii wa lati ri i pe orile-ede Germany, nilu Hamburg, loṣere naa wa lati bii ọdun mejọ seyin, iṣe aṣerunlọsọọ to kọ laarọ ọjọ ẹ ko too di irawọ oṣere lobinrin naa n ṣe nibẹ, o si ti rọwọ mu nidii iṣe naa daadaa. Ojutole fidii ẹ mulẹ pe sọọbu nla kan lobinrin naa si si adugbo ti oun gbe yii, nibi tawọn oyinbo, dudu ati akata ti n ṣerun lọwọ ẹ, wọn si sọ pe owo nla ti wa lọwọ Bukky bayii. Ilu yii naa lo wa ti akọbi ẹ fi ṣe igbeyawo, bẹẹ la gbọ pe o ma n kopa ninu awọn fiimu ti awọn oṣere Yoruba ba lọọ ya ni Germany, abi ki i kuku tan lara ọmọọba ko ma ku dansaaki, bi Bukky ṣe n siṣẹ aṣerunlọsọọ to, nigbakigba ti wọn ba pe e si oko ere ni Germany, kinni ọhun si wa lara  a fi bii pe ojoojumọ loun naa soko ere ni yoo ṣe e ṣe.



No comments:

Post a Comment

Adbox