IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 19 April 2020

Awon ohun ti o ye ki o mo nipa ilu Oyotunji l’Amerika, nibi ti oyinbo ti n soba alade

Beeyan ba gbo ti won daruko  ilu kan ti won n pe ni Oyotunji, onitohun-un yoo ro pe ilu kan nile Yoruba ni won n so, eni naa ko ni i mo pe adugbo kan ti won n pe ni South Carolina, lorile-ede Amerika niluu yii wa. Eni ti ko ba ti i ka itan Oyotunji ri, biru eni naa ba gbo oruko oba ilu naa, Oba  Ofuntola Oseijeman Adelabu Adefunmi, eni naa yoo ro pe okunrin naa gbo ede Yoruba ni, bee ede oyinbo lo n so lenu bii kaa-si-nnkan, ko gbo Yoruba,sugbon iran omo Oodua lo n pe ara re

Kinni kan to waa ni, eni to ba wo ilu Oyotunji loni-in, onitohun yoo ro pe ilu Oyo lodo wa nibi loun wa ni, gbogbo ohun ti won n se lOyoo Alaafin pata ni won se nibe, ohun tawon eeyan yii ma n so ni pe iran omo alade lawon, okan pataki ninu awon Oduduwa lawon n se, Oyo lawon si ti se wa, idi gan-an ti won se pe ara won ni Oyotunji ree o.  Oja kan wa ti won maa n na ni alaale niluu Oyotunji, oja yii ko yato sawon oja ale ti won n na nile Yoruba, bee akara won ko yato si eyi ti a n je nile kaaro-oo-jire, ‘akara je’ ni won n pe e lodo ti won.

Bawo wa loro ilu aramada yii se je, bawo lawon oyinbo alawo funfun ti won ko gbo ede Yoruba se so pe omo Oodua lawon,to si je pe gbogbo ohun ti a se nile Yoruba pata ni won n se nibe. Awon iwadii ti Yoruba Ronu se niyen, ohun ti a fee salaye fawon eeyan wa ree. E tete wa nnkan fidile le lati gbadun ara yin nipa ilu Oyotunji, nibi Oba Adejuyigbe Adefunmi ti n pase oba le won lori.

Kinni kan ti a sakiyesi ninu oro awon eeyan yii ni pe lasiko owo eru ni won ko awon baba nla won leru tabi ka so pe won ta won soko eru lo sorile-ede Amerika, awon omo ti won fi sile yii ni won wadii itan, titi ti won fi mo pe omo Oodua lawon n se. .Itan tun  fi ye wa pe ilu  kan ti won n pe ni Savannah lawon baba nla awon to te ilu Oyotunji do koko ti fee duro, saaaju odun 1960, sugbon ija ka to waye laarin awon ara ilu naa pelu awon eeyan adugbo  Sheldon lo gbe de ibi ti won wa loni-in yii. Ori ile  eeka metadiblogbon ni ilu Oyotunji wa lori e.

Awon eeyan marun-un pere la gbo pe eni to te ilu yii do,to si je oba akoko, Alayeluwa Oba Adefunmi ko de ilu yii lodun 1970, sugbon nigba ti yoo fi to odun marun-un leyin ti won te ilu Oyotunji do, awon eeyan to wa nibe ti le ni igba daadaa di odun 2005 ti Oba Adefunmi waja, ti omo e to wa lori aleefa bayii Oba Adefunmi Adejuyigbe gori aleefa, lati igba naa lawon ilosiwaju ati idagbasoke ti n ba ilu yii. Bakan naa la fidii e mule pe alejo akoko ti yoo wonu ilu yii wa lobinrin oyinbo kan ti won pada n pe ni Iya Adaramola, odun 1975 lo wo ilu Oyotunji wa, oun naa pada di okan ninu awon iyawo to waja yii ni lodun 1981,

Odun 1981 ni Ooni to waja, Oba Okunade Sijuwade Olubuse keji pa a lase pe kawon afobaje lati ilu Ileefe loo jawe oye le oba Oba Ofuntola Oseijeman Adelabu Adefunmi I.  Odun yii ni won fun un nida gege bii ojulowo oba ilu Oyotunji, oruko Ooni ni won ko sara ida yii bii oba to jawe oba le  Oba Oyotunji ori.

Ohun to tun se pataki to ye ki awon eeyan mo nipa ilu Oyotunji ni pe gbogbo awon orisa ti a n bo nile Yoruba pata ni won n bo nibe, won n bo:Esu, Orunmila, Obatala, Osun, Egungun,  Yemoja, Ogun, Oya, Sango ati  Olokun. A gbo pe o lawon ojo ti won la sile  gege bii awon ojo ti won bo awon orisa yii gege bii won se maa n se nile Yoruba nibi, gbogbo awon etutu ti a n se fawon orisa wa lawon ara  Oyotunji naa n se.

Oruko babalawo won to maa n difa lorekoore ni won n pe ni Orisafodun, odun 1972 la gbo pe okunrin naa wa siluu Abeokuta lati waa ko ifa. Lara awon odun ibile mi-in ti won maa n se niluu Oyotunji lodoodun ni odun Orita Ifa.

Lati tunbo fidii ajosepo laarin awon oba wa nibi mule ati lati mo daadaa nipa orunrun won lo mu Oba ilu Oyotunji sabewo si ilu Oyo ati ilu Ileefe, o ti le ni emeeta otooto ti Oba naa ti waa foribale ni orirun re, bee ni Ooni to wa lori oye bayii, Oba Babatunde Eniitan Ogunwusi ati Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi naa ti sabewo si ilu Oyotunji. Odun to koja yii la gbo pe Ooni ko awon eeyan sodii loo sodun orisa niluu Oyotunji ni Carolina,

Ohun kan to daju ni pe omo Oodua lawon ara Oyotunji,ojulowo omo Kaaro-oo-jire ni won so pe awon n se ,     

 

No comments:

Post a Comment

Adbox