Okan pataki ninu awon akorin omo orile-ede yii ti won n se daadaa loke okun ni Efanjeliisi Michelle Oluwatoyin Aduragbemi ti gbogbo aye mo si Moty, akorin nla yii sese pari ise lori fidio rekoodu e to pe akole e ni 'Ope mi'.
Ojobo, Tosde to koja yii ni won ya fidio yii, eni to ba wa nibi ti won ti n ya fidio naa yoo mo pe nnkan gi sese rago, awon irinse igbalode ti won n lo loke okun ni won ya fidio naa. Gbajumo adari fidio ti oruko re gbile kari aye, Akin Alabi lo dari fidio yii.
Sugbon kinni kan sele lojo yii,eni to ba ri i bawon eeyan se po ninu ogba igbafe Tunji Braitwahte to wa ni Obalende, yoo ro pe awon onifiimu ni won ya ere ni,pelu bawon eeyan se po nibe. Lara awon eeyan ti Ojutole ba soro so fun wa pe eeyan daadaa, toferan gbogbo eeyan, ti ki i foju pa enikeni re ni Moty, nitori e lawon se fi ojo naa sile fun un latiwa nibi ti won ti ya fidio yii.
Bakan naa ni Enjinia Aduragbemi to je oko gbajumo olorin emi yii ati abigbeyin e naa wa nibi ti won ti ya fidio yii
Lasiko to n ba wa soro, Moty so pe bo tile je pe awon ti koko gbe rekoodu Ope mi jade tawon eeyan si tewo gba a daadaa, o lawon ololufe oun ni won so pe awon n fe fidio naa, o ni won so pe awon fee wo ara ti oun da ninu fidio yii.
Bakan naa ni Moty fokan awon ololufe e bale pe ise opolo nla lo kun inu fidio yii ati pe gbogbo won ni won yoo lu oun logo enu ti fidio naa ba jade.
Gbajumo akorin emi yii tun gbe osuba nla fun oko e, o ni opolopon la loko oun ti se foun lori ise orin ti oun gbe dani yii ati pe owo ti oun na pata,latowo oko oun lo ti wa.
No comments:
Post a Comment