Olu tiluu Itori, Ọba Abdulfatai Akamọ, ti ṣalaye idi to fi kunlẹ ṣiwaju Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun lakooko ti wọn jọ fọrọjomitoro ọrọ nibi ayẹyẹ kan laipẹ yii.
Lakooko to n ba awọn oniroyin kan sọrọ, o sọ pe ki i ṣe pe oun fi ori ade wọlẹ nita gbangba amọ bi eeyan ba pade oloore ẹ ko si nnkan ti ko le ṣe.
Olu Itori sọ pe oun ko le tabuku ori ade rara ṣugbọn oun fẹẹ kawọn to n sọ isọkusọ mọ pe abẹ Gomina loun wa, adari ipinlẹ si ni pẹluu,amọ alaaye oore to ṣe fun emi atawọn agbegbe ni mo n ṣalaye fun un ti mo n dupẹ.
Olu Itori ṣalaye siwaju pe, " Emi kọ ni mo sọ pe mo ni iroyin ayọ fun Gomina,nibi ti mo jokoo si lo ti sọ fun mi pe ki wọn pe mi, oun ni iroyin ayọ fun mi,nibi to jokoo si aaye awọn gomina ni, ko si tọna fun mi lati jokoo sibẹ.
"Mo si ni lati bẹrẹ mọlẹ lati gbọ nnkan to n sọ nitori ariwo waa nibẹ.Igba ti wọn si maa sọrọ, wọn lawọn niroyin ayọ fun mi pe ọna marosẹ atijọ, wọn maa bẹrẹ ẹ laarin ọsẹ mẹta si akoko yii.
"Ati pe ọsibitu jẹnẹra to ti fẹẹ wo tan awọn yoo kọ o, inu mi dun gan an ni ohun to ba si wu ẹlẹnu ni ko maa sọ, gbogbo eeyan lo ni anfaani lati sọ nnkan to ba wu u"
"Ṣe ko to ọpẹ, gbogbo awọn to n gba oju ọna marosẹ agbegbe mi kọja ni wọn mọ pe ko dara rara, to si kọja sisọ, o si tipẹ taa ti n bẹbẹ fun atunṣe mo wa ri Gomina to fẹẹ ba mi ṣe, ẹ waa ni ki n ma ra baba niwaju ẹ.
Olu Itori tun ṣapejuwe Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to mọ apọnle ọba, ti ko si fọrọ wọn ṣere. O waa ni oun ko kabamọ rara nitori oloore oun ni.
Opari ọrọ e pe ka ni akoko toun ba gomina sọrọ, oun duro,gomina jokoo, ọtọ ni ariwo ti wọn yoo ma pa. O ni oun ko ri tawọn to n sọ isọkusọ naa ro, bi ko ṣe bi ilu Itori yoo ṣe tẹ siwaju.
No comments:
Post a Comment