Taofik Afọlabi
Gbajugbaja wolii agbaaye nni, to tun jẹ oludasilẹ ajọ kan to n pe fun atunto orileede yii, iyẹn, ‘Directorate of Concerned Partriots in Nigeria and Overseas’ Wolii Moses Akinwale Ọlagunju ti sọ ọ di mimọ pe atunto ododo nikan lo le yanju gbogbo iṣoro ati idaamu to n koju orileede yii.
Oludasilẹ ijọ ‘Bishop Divine Seed of God Chapel Ministry’ to wa ni niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ko si ohun meji to ku orileede yii ku ju atunto ododo lọ, gbogbo wa la si gbọdọ mura lati jẹ ki atunto ododo yii waye kiakia.
Ninu ọrọ ẹ, Wolii Ọlagunju ni loootọ ijọba ẹlẹkunjẹkun tawọn kan n pe fun dara, ṣugbọn ohun to daraju ni atunto ododo ti a gunle yii, ọrọ atunto ti mo n sọ yii, a ko fọwọ yẹpẹrẹ mu un, gbogbo awọn eeyan to yẹ ka ba sọrọ lati kọ iwe si. A ti kọwe sileeṣẹ aarẹ, a ti kọwee sawọn aṣofin, a ti jẹ kawọn otẹlẹmuyẹ mọ, a ti gbe ọrọ wa yii de ileeṣẹ ologun.
Bakan naa ni iwe wa ti de ọdọ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọgagun Ibrahim Babangida atawọn lookọlookọ lorileede yii. Ohun ti a n sọ nipe. Ohun ti a nilo ni orileede Naijiria ti yoo ti fun awọn ipinlẹ ni ominira lati di orileede laaye ara wọn, eyi ti yoo mu ilọsiwaju ba ipinlẹgbogbo, ṣugbọn awọn ipinlẹ wa yoo ni ominira gẹgẹ bi orileede eyi ti a o pe ni ‘United state of Nigeria’, ti a ba wo orileede UK, awọn orileede ti wọn n jẹ United Kingdom pọ daadaa, gbogbo awọn orileeede to wa ni labẹ United kingdom ni wọn ni ominira, ti wọn si n lo awọn alumọọni wọn lati tu orileede wọn ṣe. Ẹ wo Dubai naa bo ṣe ri naa niyẹn, awọn orileede ti wọn n jẹ United Arab Emirate pọ daadaa, kaluku wọn si n n ṣe ohun to n mu idagbasoke ba orileede wọn labẹ United Arab Emirate.
Ti a ba wo o daadaa, awọn ẹkun kọọkan lorileede yii lo ni awọn ohun alumọọni ti Ọlọrun fun wọn, ẹ wo ọdọ ti wa ni Ekiti, a ni goolu nibẹ, bẹẹ si ni ipinlẹ Eko omi wa daadaa fun ọrọ aje wa, bẹẹ si lori lọdọ awọn ara ilẹ Igbo, ti a ba gba awọn eeyan yii laaye wọn le sọ orileede yii di orileede China lọdọ wa nibi. A ti lo ijọba ẹlẹkunjẹkun ti awọn kan n pe fun yii, ko fun wa ni ohun ti o le mu ominira tootọ ba awọn ẹkun, ọna kan ṣoso ti a gbọdọ gba lati bọ ninu laasigbo ti a wa yii ni atunto otito ti yoo jẹ ki gbogbo awọn ipinlẹ wa di orileede, ti wọn yoo si lo alumọọni ti Ọlọrun fun wọn lati tun awọn orileede wọn ṣe.
Wolii Ọlagunju ni ‘ iṣoro orileede yii, ki i ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, eyi ko le mu irọrun kankan ba awọn mẹkunnu, mo si fẹẹ fi asiko ran Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu leti ohun to mọ pe aṣaaju jẹ ipo to gbẹgẹ, to si jẹ anfaani nla fun ẹni to ba wa nibẹ, bẹẹ lo jẹ ipo ti ko lọ titi, ti eeyan si gbọdọ jẹ olootọ si awọn eeyan to yan an sipo ati Ọlọrun ọba.
Wolii Ọlagunju ni, lara pohun ti a fẹ ki ijọba Bọla Ahmẹd Tinubu ṣe bayii ni lati mu owo epo wa silẹ, ko mu opin ba wahala ina mọnamọna to n ṣe segeṣege, ko gunle eto ọgbin alada nla ti yoo ni aabo to peye fun awọn ohun ọgbin wa, bẹẹ ni ki aarẹ ri si iṣoro awọn Fulani adaran, ki wọn si fun wọn lawọn ilẹ ti wọn yoo ti maa fi awọn maalu wọn jẹko.
Ki aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn eeyan, ki ijọba kọ orileede ti yoo wa ni isọkan, ki ijọba ro owo Naira wa lagbara, ki ijọba ri i pe ọwọn gogo ounjẹ di ohun igbagbe. Lara ohun ti ajọ ‘Directorate of Concerned Partriots in Nigeria and Overseas’ tun pe fun ni pipeṣe iṣẹ lọpọ yatunru fawọn ọdọ, gbi gbogunti awọn ojẹlu, ki ijọba ṣe ofin ti yoo fiya jẹ ẹnikẹni ti ajere iwa ibajẹ ba si mọ lori. Mimu adinku ba owo ti wọn n gba iwe ọkọ, ki ijọba ri si iṣoro to n koju awọn ologun wa atawọn nnkan mi-in ti yoo mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba orileede wa. Bakan naa ni Wolii Ọlagunju tẹ siwaju ninu ọrọ ẹ pe laipẹ yii ipade awọn oniroyin lagbaaye yoo waye, nibi ti awọn olorukọ orileede yii yoo ti forikori lori bi eto atunto ododo yii yoo ṣe wa si imusẹ. .
Ninu ọrọ tiẹ, akọwe agba fun ajọ DCPN, Dokita Oriade Daniel, naa sọ pe ko si awijare kankan nibẹ, eto ijọba ti a n lo yii ti kuna patapata, ko si ọna abayọ mi-in to ju atunto ododo yii lọ, eyi ti gbogbo ọmọ orileede yii gbọdọ ṣetan lati jẹ ki ko wa si imusẹ ki idagbasoke, ilọsiwaju ati ayipada rere le e ba gbogbo ọmọ orileede yii.
No comments:
Post a Comment