Taofik Afolabi ati Toyin Agbolade
Gongo so lojo Sannde, Aiku, ojo keta, osu yii, ojo naa ni won we lawani
oye Baba Adinni tuntun fun gbogbo musulumi ile Yoruba le gbajugbaja onisowo nni, Alaaji Rasaki Ayinde
Adeleke eniti gbogbo eeyan mo si Agba-Owo lori. Ojo Sannde yii kan naa ni iyawo
re, Alaaja Rashidat Adebimpe Adeleke naa
joye Arowosadinni fun gbogbo musulumi
labe ijo ‘Dairat Dasfat’. Gbagede to wa ni Marina, niwaju ileefowopamo UBA
layeye naa ti waye.
Awon ara,ore, ebi baba Adinni tuntun ni won
wa nikale lojo
naa, beeni awon oseere tiata bii Ayoka Ologede,Kemi korede, Mide ati Afiz Abiodun, Abbey Lanre, Baba Ajobiewe, Kakawa,Nike Peller, bee lawon olorin Islam bii KIfaya Singer, Basira Ogunremi Iya-n-Ghana, Alaga Wura atawon mi-in wa nibe.
Bakan naa lawon ore Alaaji Adeleke bii: Alaaji
Ganiy Ajibade Akewusola lati idiroko, Alaaji Owolabi lati orile- ede Kutonu, Alaaji
Abu Gidado lati ilorin, Alaaji Kazeem Buaya, iyawo Oloye Aminat Buaya, Alaaji
Oriyomi lati Osun, Dokita Abiola Yoyo Bitters.
Awon egbe istijaba lati idiroko ti Alaaji Ganiy oludasile re naa wa nibe pelu awon loba loba
lati ile Yoruba.
Ohun to foju han lojo yii ni pe ojo nla ti
Agbaawo, iyawo e atawon ebi e ko le gbagbe lojo naa lojo yii.
Gbogbo awon eeyan
ti won wa nibi ayeye yii ni won mo pe eeyan nla lo se nnkan lojo yii.
Alaaji Bukola Alayande tawon eeyan mo si Ere asalatu lo fi orin ati ilu da awon eeyan
laraya, agba-oje akwei nni, Alagba Sulaiman Ayilaran ti gbogbo aye mo si Ajobiewe
naa fi ewi gba ijo lese awon eeyan Ilu
mo on ka sorosoro ori redio nni, Ambasado Yomi Mate Ifa-n-kaleluyah lo dari
ayeye yii, bee ni Oloye Abiodun Adeoye ti won n pe ni Afefe Oro naa ati Alado
naa wa nibi ayeye yii.
No comments:
Post a Comment