Agbolade Toyin
ALAAJI RASAK AYINDE AGBAAWO |
Gbogbo ilu
Eko ni yoo mi titi lojo keta, osu keji, yii, nibi ti ayeye iwuye Alaaji Rasak Ayinde
Adeleke ti gbogbo aye mo si Agbaawo, to tun
je Akeweje ilu Iseyin, nipinle Oyo yoo waye.Ojo
naa ni won yoo we lawani fun un gege bii Baba Adinni tuntun fun gbogbo musulumi
ile Yoruba leyin iku Oloogbe Iyanda Folawiyo to je oye naa tele.
Ojo yii kan naa niyawo e, Alaaja Rashidat Adebimpe Adeleke yoo joye Arowosadinni fun gbogbo musulumi kaakiri ile Yoruba. Gbagede Marina nigboro Eko layeye naa yoo ti waye.
ALAAJA RASHIDAT ADEBIMPE |
Gbajumo olorin
Islam nni, Alaaji Bukola Alayande ti gbogbo aye mo si Ere Asalaatu ni yoo korin
lojo naa.
Oye yii ki i soye
akoko ti Akeweje ilu Iseyin yoo je, oun ni Baba Suna mosalaasi nla to wa laafin
Emir Sulu Gambari ilu ilorin labe, ti iyawo re si je oye otun iya Suna ni
mosalaasi yii kan naa
Onisowo
epo pentiroolu ni Baba Moria, ti iyawo re si je onisowo pataki, nitori ipa ti won n ko nidii esin islaamu lo
tun mu Sheik Alfullany fi Agbaawo joye Saraki
Adinni, ti iyawo re si joye Osupa Adinni. Lojo yii kan ni Sheik Alfullany fi gbajumo oseere tiata nni,
Lizzy Anjorin joye Borokini Adinni.Awon eeyan pataki kawujo ni won n reti nibi ayeye yii: Alaaji Ganiy Ajibade Akewusola, Alaaji Gidado atiAseyin tiluu Iseyin.
Nitori ipa
ribiribi ti Akeweje ilu Iseyin ati iyawo re n ko kaakiri orile- ede yii lo je
ki awon oye yii to si won a-ka-n-ka-tan loye Ayinde baba Ayinde. Adupe wa ni wipe oye a a
mori o
No comments:
Post a Comment