IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 7 February 2019

AGBA-OJE OLORIN JUJU, PROFESSOR YK AJAO PADANU MAMA E

Iroyin to te Ojutole lowo ni pe agba-oje olorin juju nni, Oloye Yekeen Ajao Ajeigbe ti gbogbo aye mo si Professor YK Ajao tabi Makosa King ti padanu mama e, Alaaja Munirat Morounmubo Amoke Ajao Ajaigbe. Ojo kin in ni, osu keji, odun yii ni mama naa dagbere faye, ti won si sinku e nilana esin Islam. 


Ninu oro ti Professor YK Ajao ba Ojutole so lo ti wi pe iku mama oun ba oun ninu je pupo, o ni bo ti le je pe mama dagba, sugbon oun ko fe ki won lo lasiko yii. Baba yii so pe oun dupe lowo Olorun pe eleyin ko siwaju, bee ni oniwaju ko gbeyin. King Makosa dupe lowo gbogbo awon eeyan ti won duro ti i lasiko adura ojo mejo mama naa. 

No comments:

Post a Comment

Adbox