Iroyin to te wa lowo ni pe Oloye Adebolu Fatunmise ti gbogbo aye mo si Babalawo l'Amerika ti ku o. Ni nnkan bii ojo meta seyin ni baba naa jade laye. Fawon ti ko ba ranti mo daadaa, Oloye Fatunmise lo joye Iyanfoworogi tiluu Ile-Ife, oun ni Olootu magazinni 'Atoka Yoruba' laarin odun 1980.
Opolopo odun ni Oloogbe fi se ise babalawo lorile-ede Amerika, okan pataki ninu awon omo orile-ede yii tawon olorin maa n ki lorile-ede Amerika to n gbe ni nigba aye e.
No comments:
Post a Comment