E wo okunrin yii daadaa, e wo o ke e tun un wo, omo e lo fun loyun niluu Edo, owo awon olopaa si ti te e bayii.
Gege bi a se gbo, lati odun meje seyin lokunrin yii ti won pe oruko re ni Moses Friday ti n ba omo e Precious Friday sun, tomo naa si ti pe omo odun metala bayii.
Ni nnkan bii odun marun-un seyin ni mama Precious ku, toun ati baba e nikan jo n gbe, dipo ki okunrin yii feyawo mi-in,omo e lo n ko ibasun fun ni gbogbo igba.
Nibi ti ise ibi yii jngiri mo Friday lara de,se lo fun omo e loyun, ohun to je ki asiiri e tun sawon ara adugbo lowo niyen. Awon araadugbo ni won fisele naa to awon olopaa leti,ti won si fi panpe oba gbe baba buruku yii.
No comments:
Post a Comment