IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 25 October 2018

ODUN OLOKUN DUN YUNGBAYUGBA, IFAKALELUYAH, ABEY FAGBORO, YEMI AJIDE, SKIN DUDU, BABA GBOIN, ATI Q-DOT DI ASOJU FUN ODUN OLOKUN


Latowo Taofik Afolabi


Image may contain: 14 people, people smilingEni to ba wa nibi asekagba odun Olokun to waye lanaa, leti okun 'Suntan Beach' to wa ni Badagiri, nipinle Eko  yoo mo pe Eledua jokun nnkan nla fun iran Yoruba, onitohun-un yoo si gbe osuba rabanda fun Aare Ona-kaka-n-fo ile Yoruba, Iba Gani Adams Abiodun Ige fun ipa nla to n ko fun idagbasoke ati ilosiwaju asa, ise ati ede Yoruba pelu ayeye naa se dun, to tun larinrin. 

Lati ibi gbogbo lawon omo Yoruba ti wa a  sodun nla yii ti ajo 'Olokun Festival Foundation' sagbateru e. Odidi ose kan gbako layeye yii fi waye, nibi tawon eto bii adura, ifigagbaka nipa asa ati ise Yoruba, ayo olopon, idije orekelewa, boolu eti okun, idije oko ori omi ati iweje-wemu ti koko waye. 

Papanbari ayeye yii lawon asoju tuntun tajo naa sese yan, awon asoju ohun ti won n pe ni ambasado ni: Oloye Abey Fagboro, Ambasado Abdulyomi Mate Ifakaleluya, Oloye Bashiri Adisa Baba Gboin, Oloye Tokunbo Babs Olurinde Skindudu, Ambasado Olayemi Ajide Olayinka, Fakoya Qudus ti gbogbo aye mo si Qdot ati alaga igbimo ayeye yii, Ambasado Muyiwa Oshinaike,Image may contain: 9 people, people smiling

Lara awon eto to waye nibi asekagba yii ni: orin ati ilu latowo egbe 'Oodua International  Troupe' nibi tawon omo egbe yii ti forin aladun ati ijo da awon eeyan lara ya, eyi to ba awon eeyan leru ju ninu ohun tawon egbe yii se ni ti omokunrin kan ti won de mo inu apoti, to si yi pada di eyele, ko too di pe olori won to n padan yii da a di eeyan, tariwo nla si so laarin awon eeyan,


















Bakan naa ni eegun ilu Badagiri ti won n gbe ni Sagbento naa dara nla lojo yii, ejo, aleegba ati agbon meji ti won ko gaari ati epo pupa jade ninu e lo jade lara awon eegun sagbento yii.

Ninu oro oba alaye ojo naa, Alayeluwa Oba Muniru Adesola Lawal Laminisa Akoko, Timi ilu Ede lo ti lu Iba Gani Adams logo enu fun bo se n lo ipo re lati gbe ogo iran Yoruba ga, o ni ti gbogbo omo Yoruba ba da bii Aare-Ona-kaka-n-fo yii, ilosiwaju ati igbega yoo ti de ba asa ati ise wa, sugbon a i nimo ati oye to ti gba asa danu lowo wa, eyi ti ko bojumu rara.

Ninu oro e, Iba Gani Adams so pe ko si ohun meji ti odun Olokun da le lori ju lati gbe asa ati ise Yoruba ga, idunnu lo si je foun pe odun Olokun je asaaju ninu gbigbe asa ati ise Yoruba ga. O ni Olokun je orisa nla ti enikeni ko le e foro ro seyin, ati pe oosa yii ni awon amuye kan to je ko di oosa pataki ninu awon orisa ile Yoruba. 

Aare ni Olokun je orisa aje, to je pe eni to ba fee ri aje jeun gbodo bowo fun un, idi pataki tawon se mu un ni pataki lati maa se sayeye yii lodoodun niyii.

Lara awon oba alaye ti won wa lori ikale lojo naa ni:Oba De-Whenu Aholu, Aholu Menu Toyi 1, Akran tiluu Badagiri,  Oba Isreal Adewale Okoya, Onibereko tiluu Ibereko, Oba Sejiro Ogugbe Okiki Arolagbade Aholu-Henwa tiluu Kweme, awon oba alaye lati ilu Ede, awon oba alaye  lati ile Benni, asoju Alaafin, asoju ijoba ipinle Eko, awon oloye ile Yoruba gbogbo,awon elesin abalaye, awon elesin igbagbo, awon musulumi, awon omo egbe OPC kari aye atawon otokulu.        





























No comments:

Post a Comment

Adbox