lu
Laaro, ana ojo Aje Monde, ni deede aago mejo abo aaro ni won ti gbe gomina tele nipinle Ekiti, Ogbeni Peter Ayodele Fayose de kootu l'Ekoo, esun mokanla ni won ka si i lese, bee ladajo tun ti pase pe ki won da a pada si ahamo.
Lara esun mokanla otooto ti won ka si okunrin oloselu yii lese ni owo bitibiti ti won so pe o gba lowo alakooso eto aabo lorile-ede yii nigba kan, Aliyu Gusau lasiko to fe dije dupo gomina l’Ekiti.
Lojuese ti won ti ka awon esun ohun si i lese ni gomina tele yii ti so ni kootu wi pe oun ko jebi okankan ninu gbogbo esun buruku ti won ka si oun lorun.
Nibe gan-an ni agbejoro to n soju ijoba, Rotimi Oyedepo ti ro ile-ejo ko tete pase ki won lo fi gomina tele naa pamo sogba ewon, titi digba ti ile-ejo yoo fowo si i boya ki won gba oniduro e tabi rara.
Sugbon agbejoro to n soju fun Fayose, Kalu Agabi, (okan lara onimo nla ninu ise ofin) ko je ki oro ohun bale, ti oun naa fi bebe wi pe ki won siju aanu wo Ogbeni Fayose, ki won je ko si maa lo sodo ajo EFCC na, niwon igba ti eto ti n lo lori bi won yoo se gba oniduro e.
Ni bayii, Adajo agba, Mojisola Olatoregun ti so pe ki won lo fi Fayose si ipamo naa, lodo ajo EFCC, nigba ti igbejo e yoo maa te siwaju lotunla Wesde Ojoru ose yii.
No comments:
Post a Comment