Gbajugbaja olorin Islam nni, Alaaji Afeez Salami Ajiroba ti gbogbo aye mo si Saoti Arewa tabi Ojulowo Omo ti so pe odo gbajumo maketa awon olorin, Afeez Salami tawon eeyan mo si Afeezco ninu oun ti dun ju laye, odo okunrin naa si ninu oun tun ti baje ju.
Saoti to sese de lati orile-ede Amerika soro yii lori eto ti ilu mo on ka sorosoro nni, Ambasado Yomi Mate Ifakaleluyah maa n se ni gbogbo ojo Tosde, lori radio Faaji Fm. Eto naa to maa n waye laago meji osan si aago merinla irole ti won pe oruko re ni 'Ko ma a flow'ni Saoti ti soro yii.
Ninu iforowanilenuwo ti Ifakaleluyah to sese di asoju odun Olokun se fun Saoti Arewa lo ti beere lowo e pe ojo wo ni inu e dun ju laye. Alaye ti gbajumo akorin esin omo bibi ilu Epe yii se lo ti so pe ojo tinu oun dun ju laye lojo ti Afeezco gbo orin oun ninu moto e.
O ni opo igba loun ti fun okunrin rekoodu oun , sugbon ti ki i gbo o, debii pe yoo gbe oun jade, sugbon lojo kan bayii loun tun lo sodo e pe ko ran oun lowo lati gbe rekoodu oun jade, toun si tun fun un lorin oun.
Saoti ni bi Afeezco se gba orin naa lo mu wo inu oko ayokele e lo, to si pe oun pe kawon jo gbo orin naa wo ninu moto e pelu ero a- mu-oko-tutu,ti okunrin naa si gbo orin naa dele.
Irawo olorin Islam yii so pe se ninu oun dun, ti oun dupe lowo Olorun pe adura oun ti gba, nitori pe igba akoko ti Afeezco yoo gbo orin niyen, o tun wa a je pe awon tun jojo gbo o ni. O ni se lo dabii eni pe won foun niwee alujanna lojo yii.
Bee ni Ifakaleluya tun beere lowo e pe ojo wo ninu e baje ju, idahun ti Saoti fun Ifa ni pe odo Afeezco kan naa tun ni inu oun tun ti baje ju laye. Ohun to so ni pe lojo naa lohun-un, oun lo si ofiisi Afeezco gege bii ise oun, sugbon boun se wa nibe ni odomode olorin fuji kan toun ko fee daruko to kere pupo soun lojo ori de. O ni bi onifuji naa se de odo Afeezco lokunrin maketa rekoodu naa so foun pe koun dide fun onifuji yii ko kojoo nibi toun jokoo si. Saoti ni oro yii dun oun pupo debii pe omi fee jade loju oun, ntiori pe abuku nla ni won fi kan oun lojo naa ati pe ko si ohun to je ki Afeezco se ohun to se foun yii ju pe oruko omode onifuji naa wa nita lasiko naa. O ni ojo toun ko le gbagbe laye oun lawon ojo mejeeji yii.
Thursday 25 October 2018
Home
/
LAGBO OSERE
/
SAOTI AREWA, OLORIN ISLAM, TU ASIIRI NLA, ODO AFEEZCO NINU MI TI DUN JU, ODO E NAA NINU MI TI BAJE JU LAYE
SAOTI AREWA, OLORIN ISLAM, TU ASIIRI NLA, ODO AFEEZCO NINU MI TI DUN JU, ODO E NAA NINU MI TI BAJE JU LAYE
Tags
# LAGBO OSERE
Nipa IROYIN OJUTOLE
NJE O NI IROYIN FUN WA BI? TABI O NI AYEYE TI O FE KI A BA O GBE JADE? ABI IPOLOWO OJA TABI IKEDE LE FE SE, TETE PE SORI AWON NOMBA WONYI: 08023939928, 08185819080.
LAGBO OSERE
Tags
LAGBO OSERE
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment