IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 2 October 2018

ELEYII MA TUN GA O: SANWO-OLU NIGBAKEJI AMBODE, IDIAT ADEBULE NAA DIBO FUN

Oro to wa nile yii ti koja oju tawon eeyan fi n wo o, ibo abele gomina ninu egbe  APC Ekoo la n so , o jare. N je eyin gbagbo pe Jide Sanwolu to je alatako Akinwumi Ambode ninu ibo naa nigbakeji e, Alaaja Idiat Adebule naa dibo fun loni-in. 

Alaye ti obinrin naa se leyin to dibo fun Sanwo-Olu tan ni pe eni tawon agba egbe fe ni gbogbo awon te le, ohun tawon asaaju awon fe loun se yen.

Bakan naa ni Ojutole gbo pe komisanna feto ibara-eni-soro naa, Kehinde Bamigbetan, naa dibo fun Sanwo-Olu, boya si ni omi ko teyin wo igbin Ambode lenu
bayii.   

No comments:

Post a Comment

Adbox