IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 14 September 2018

ATIKU ABUBAKAR FIGBE TA, ' E GBA MI O, WON FEE PA MI NITORI IBO AARE ODUN TO N BO'

Igbakeji aare orile-ede yii tele, to tun n dije ipo aare labe egbe oselu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti ke gbajare pe kawon eeyan gba oun lowo awon eeyan kan ti won fiku deru ba oun atawon ebi oun nitori ibo aare odun to n bo.
Ninu leta ti Atiku ko si Aare Muhammed Buhari lo ti so pe oun nilo aabo to peye, nitori se lawon eeyan kan toun ko mo fi leta iberu ranse soun lori foonu, ti won so pe awon yoo pa oun, tawon yoo tun fipa ba awon omo oun ati iyawo sun kawon to o pa won.  
Nomba yii ni 08148228704‎, Atiku so pe awon eeyan naa fi te atejise soun. O ni se lawon eni naa kilo foun pe koun tete jawo ninu ipo aare to n fe se tabi bee ko, awon yoo da emi oun legbodo tawon yoo tun pa awon omo oun ti won n je Mariam ati Fatima.
Atiku ni awon to n deru ba oun yii so pe awon yoo ju ado oloro si baalu oun, tawon yoo fi majele pa iyawo oun atawon omo leyin tawon ba ti fipa ba won lo po tan. O ni won tun so foun pe gbogbo ibi toun atawon ebi oun rin si lawon mo pata.  

 

No comments:

Post a Comment

Adbox