IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 21 January 2024

Àyàngbajúmọ̀ gbé ètò nla kalẹ̀ fáwọn àgbà onílù


Lati ṣe koriya ati lati jẹ ki wọn mọ pe eeyan pataki ni wọn lawujọ, gbajumọ obinrin onilu nni,  Queen Ẹniọla Lias Abiọdun tawọn eeyan mọ si Ayangbajumọ ti gbe eto nla kan kale fun awọn agba onilu ti wọn ti filu jẹun, ti wọn si lulu fawọn ilu mọ ọn olorin. Eto naa, to pe ni Awọn ‘Ayan-to-gbajumọ’ lo fi n ṣe koriya fun awọn agba-ọjẹ onilu naa ti wọn ti ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa lagbo ariya. Eto ọhun ti wọn yoo maa ṣafihan lori ẹrọ ayeluja

ra ati tẹlifṣan ni Ayagbajumọ ti fun awọn agba onilu naa lowo nla ati ẹbun to ṣe pataki si awọn onilu ọhun.

Ninu ọrọ ẹ, Ayangbajumọ to fi orileede Amẹrika ṣebugbe sọ pe awọn baba yii ti jiṣẹ-jiya nidii iṣẹ ilu lilu, bẹẹ lo jẹ pe awọn eeyan ki i fi bẹẹ ka awọn onilu kun gẹgẹ bi wọn ṣe ma n ṣe fun awọn olorin. ‘ Ko digba tawọn baba yii ba ku ka too mọ riri wọn, o yẹ ka pọn wọn le lasiko ti wọn si wa laye, nitori ẹ la ṣe gbe eto Awọn ‘Ayan-to-gbajumọ’ kalẹ’.      

 

 


No comments:

Post a Comment

Adbox