IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 1 January 2024

Aare Adetola Emmanuel-King ranse ikinni odun tuntun sawon omo orileede,Ireti si wa fun wa ni Naijiria



Oga Agba ati oludari ileese ADRON Homes and Properties, Aare Adetola Emmanuel-King ti ranse ikinni odun tuntun sawon omo orileede yii.

Oloye nla naa ninu ikinni e fodun tuntun so pe ' A dupe fun Olorun to je ka ri odun tuntun, mo si fee ro awon eeyan pa ka duro sinsin, ka si ni igbagbo ninu orileede yii, bo tile je pe nnkan ko senuure nipase oro aje wa to denu kole, sibe, a gbodo nigbabo ninu orileede wa yii.

Aare Adetola ni oun nigbagbo ninu ijoba to wa nita lasiko yii pe, won yoo gbe wa de Ebute ayo.

' Mo n fi asiko yii ranse odun sawon omo orileede boya awon to wa nile tabi awon to wa loke-okun pe ka sa gbogbo ipa lati ri I pe Naijiria goke agba laarin awon orileede yooku lagbaaye. Bee la si gbodo je asoju gidi fun orileede yii. Mo si tun fee je ki gbogbo wa mo pe ijoba wa naa ni ojise lati mu idagbasoke ati itura ba awon eeyan orileede yii.

Mo ri ojo iwaju to dara si orileede yii, ti gbogbo ohun to ti sonu mo wa lowo yoo pada sipo, mo si nigbagbo pe ijoba Bola Ahmed Tinubu yoo gbe wa de ebute ayo laipẹ, la I jinna. Mo si tun fee fi asiko ro gbogbo awon omo orileede yii pe ka jawo ninu iwa ti yoo mu iyapa ati wahala ba orileede yii. E je ka Fi ife han si ara wa, ka nawo ife si omolakeji wa.

Beeni, mo tun lo asiko yii lati kedun pelu ijoba ipinle Plateau lori ikolu to fi opo emi sofo, mo bawon kedun gidigidi, ki Olorun ma se ka ri iru e mo, ko ba wa fori ji awon to ba isele naa lo, ko si tu ebi to padanu emi won ninu. Ki ijoba ji giri Lori eto aabo to mehe lorileede yii.
A ku odun, a ku iyedun, emi wa yoo sopo e laye.

No comments:

Post a Comment

Adbox