Oodu ni Alaaji Wasiu Buaya jẹ nidi iṣẹ iṣegun,baba yii ki n ṣe aimọ f'oloko rara,oun ni Baṣegun Agbado nipinlẹ Ogun tẹlẹ, ṣugbọn ni bayii,o ti di ọba iṣegun fun gbogbo awọn oniṣegun ati oniṣẹṣe kaakiri ijọba ibilẹ ifọ nipinlẹ Ogun lapapọ
Ọba iṣegun tuntun wa a ki Gomina ipinlẹ Ogun
Omọọba Dapọ Abiọdun fun atilẹyin iṣeṣe nipinlẹ naa,bẹẹ lo n ki alaga ijọba ibilẹ ifọ,,Aarẹ ẹgbẹ oniṣegun,ọbaaṣegun Ẹgba atawọn oniṣẹse kaakiri ilẹ Yoruba
Ọba iṣegun ti jẹ ko ye awọn ọmọ
Yoruba atata pe,anfaani wa ninu ewe ati egbo nitori Ọlọrun lo da a bẹẹ lawọn eeyan ko le ṣe ki wọn ma ṣe lo ewe ati egbo lọjọ kan nitori ounjẹ ti a n jẹ,ewe ati egbo ni wọn,pasito ati aafa n lo ewe ati egbo pẹlu ṣugbọn ọna ọtọọtọ ni wọn n gba lo o lati fi tu awọn eeyan silẹ
Ọbaaṣegun ti wa ṣeleri pe lasiko toun yii,ifẹ,ilọsiwaju yoo wa ninu ẹgbẹ iṣegun kaakiri ilẹ Yoruba
No comments:
Post a Comment