IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday 24 December 2023

Bi odun se n lo sopin,Ileese ADRON gba ami-eye nla meji



Bi odun 2023 se n palemo eru e, to n dagbere ni oga awon ileese to n ta Ile lorileede yii, iyen ADRON homes and properties gba ami-eye nla meji nibi awoodu kan ti won pe oruko re ni ' The Nigerian Business Leadership awards eyi to iweeroyin Business Day Media limited sagbateru e ati eyi ti egbe awon to n ta Ile ati ile ti oruko won n je Real Estate Development Association of Nigeria (REDAN)

 Ami-eye ileese to dangajia ju laarin awon ileese to n ta Ile ni ADRON gba lojo naa.

A gbo pe nitori ipa nla ati idagbasoke ti ko legbe ti ileese ADRON mu ba owo Ile ti ta lo fa a ti won se fun un lawon ami-eye nla meji ohun.

Ninu awon alase iweeroyin Business Day ni won ti so pe ipa nla ti ko legbe ni ileese ADRON ti mu ba idagbasoke ati ilosiwaju oro aje orileede yii nipa je ko rorun fawon eeyan lati di onile lori, beeni ileese naa tun pese ise fawon odo orileede yii.


Bakan naa ni won tun gbe osuba nla fun ileese naa fun bo se je ileese to se e fokan tan laarin awon elegbe e.
 
 Ojo kesan-an osu yii layeye ami eye ti iweeroyin Business Day waye ni Ile igbafe   to wa ni Kofo Abayomi ni  Victoria Island, nipinle Eko.

 Ojo kokandilogun ni ami-eye ti ajo REDAN waye nibi ti won ti seye nla fun Ileese ADRON fun ipa re lawujo pipa ooto ti won n gba ta Ile won fawon araalu.

Ninu oro awon alase ileese ADRON ni won ti so pe awon ko ni I kaare lori igbinyaju awon lati je ki teru-tomo donile lori nirorun. Beeni ni won fori ami eye naa sori gbogbo awon ololufe won kari aye.


No comments:

Post a Comment

Adbox