IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 25 September 2023

Won fiya je mi gidigidi nitoripe mo da egbe OPC Reform sile- Komureedi Dare Adesope




 

 Àyà nini to oogun lọtọ, ka ni igboya ka si le ṣe bii ọmọ akin ki i tan lọrọ ẹni to ba ya akin.  Eyi lo fa a ti Aarẹ ẹgbẹ Odua People’s Congress Reformed, (OPC-R) lagbaaye, Kọmureedi Dare Adésopé, ṣe f’ọwọ rẹ gbaya, to ni eegun loun n fọwọ sọ o, ki i ṣe ẹran rara. O ni walahi, boun ba wa nibi ti aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn dide ni, awọn Oriade naa ko ni i dide fun un, kinni kan ko si ni i ṣẹlẹ.

Nibi ifọrọwerọ ti ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners (LYMP),  ṣe lori ayelujara pẹlu Aarẹ Adesope l’Ọjọruu lo ti sọrọ yii pẹlu alaye lorii idasilẹ ẹgbẹ OPC Reformed, Oloogbe Fredrick Faseun, Iba Gani Adams ati bẹẹ bẹẹ lọ:

‘’Orukọ mi ni Kọmureedi Dare Adesope, mo jẹ Aarẹ ẹgbẹ Oodua Peoples’ Congress Reformed. Emi ni Akọwe agba fun Ọmọwe Fredrick Fasehun nigba kan.

Nnkan to bi OPC Reformed, ẹ ri i pe OPC Reformed la n pe e, labẹẹ Ọmọwe Fredrick Faseun lati kuro nigba yẹn, nnkan to dẹ bi i ni pe o di pe ẹgbẹ yẹn fẹẹ ṣe lodi si nnkan ta  a n polongo. A fẹẹ ṣe lodi si nnkan ta a duro fun pe ninu gbogbo nnkan ki nnkan ta a ba n ṣe, Yoruba lo maa jẹ akọkọ ta a maa ja fun, ta a maa duro ti .

Nigba idibo Buhari ati Ọṣinbajo, ko too digba yẹn, gbogbo wa naa la ri i pe Yoruba wa lẹyin gan-an ninu ọrọ Naijiria, nnkan ta a dẹ n ja fun naa ni niyẹn, ẹẹmẹwaa la maa n ba ẹyin oniroyin sọrọ, pe wọn n ko iyan wa kere niluu Naijiria.

Igba to wa digba ibo yẹn, ta a wa ri i pe bo tiẹ ṣe le wu ko ri, ipo igbakeji ni Naijiria ki i ṣe ipo to kere naa, ọmọ Yoruba leleyii o. Ṣugbọn Baba to jẹ aṣiwaju wa nigba yẹn, awọn o lọ sibi yẹn, nitori pe Jonathan ṣe awọn ileri kọọkan fun wa. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe mọ pe ninu OPC na lotitọ ati lododo, ororo ara wa la fi n yan ara wa, a maa n funra wa gbẹ ni ka too ri nnkan kan ṣe ninu ẹgbẹ yẹn.

Jonathan wa ṣeleri pe ta a ba ṣiṣẹ foun toun ba debẹ, oun maa gbe iṣẹ ida-aabo-bo ọpa epo fun wa atawọn oriṣiiriṣii nnkan bẹẹ yẹn, o dẹ mu awọn ileri yẹn ṣẹ.

Ṣugbọn ṣe ẹ mọ, emi atawọn kan la wo o pe nibo la fẹẹ foju si i, awa ta a la n ja fun Yoruba lododo, ka tun wa tori ohun ta a fẹẹ jẹ, ka wa ba ohun ti a fẹẹ jẹ́ jẹ́. A wa la duro pe a o ni i ṣe iru eleyii, bo ṣe le wu ko ri, ẹgbẹ to gbe ọmọ Yoruba jade gẹgẹ bii Igbakeji lawa maa ṣiṣẹ fun.

Kinni yẹn da gbọnmi-si i-omi- o to o silẹ ninu ẹgbẹ to jẹ pe wọn ti wa mọle, wọn lo ọwọ agbara fun wa. Ṣugbọn nitori pe a ni afojusun, a dẹ n wo ba a  ṣe jẹ, ọmọluabi la pera wa, a dẹ n ranti ile, fun idi eyi, a duro lori ẹsẹ wa, a ko jẹ ki gbogbo awọn nnkan yẹn mi wa.

    Nigbẹyin ṣaa, nigba to di oṣu kẹwaa ọdun 2016, a fi ẹgbẹ tiwa lelẹ ti i ṣe OPC Reformed. Koda, Alaafin Ọyọ gangan lo waa gbe Ọpa-aṣẹ fun wa, Baba wa Yẹmi Ẹlẹbuibọn gan-an wa nijokoo.

Iyẹn lo dẹ jẹ igba akọkọ ta a ri ọba ilẹ Yoruba to jẹ onipo kin-in-ni ( First class ọba) to maa lọ sibẹ lati gbe ọpa aṣẹ fun Aarẹ.

Ba a ṣe bẹrẹ OPC Reformed niyẹn ta a dẹ n ba a bọ latigba yẹn, Ọlọun dẹ n ba wa ṣe e, ẹyin oniroyin naa dẹ n ba wa ṣe e. Ẹ ṣe e gan-an, oju o ni i tiwa.

Awọn ipenija ta a koju ka too da OPC Reformed silẹ

Ipenija ko le ṣe ko ma si, ti mo ba yan an lai ṣalaye delẹ nikan ni. Ṣe ẹ mọ pe mo sọ ọ laarin kan, mo ni wọn gbe wa, wọn ti wa mọle, aimọye igbesẹ loriṣiiriṣii.

Ẹyin naa mọ pe ẹni tiru wa yii n koju nigba yẹn, bii igba ta a ba ni eera ati eerin jọ n du nnkan mọra wọn lọwọ ni, bẹẹ lo ṣe ri nigba yẹn. Ṣugbọn ẹni t’Ọlọrun ba n ṣe tiẹ, ko si nnkan to nawọ si ti ko ni i ṣee ṣe. Ati pe teeyan ba wa lori otitọ ati ododo, iru eeyan bẹẹ yẹn maa n ja ajaye ati ajaṣẹgun ni.

 Ootọ inu gangan lo gbe wa bori, ohun to jẹ ko tun rọrun ni pe teeyan ba ti mọ nnkan to n ṣe, to o dẹ nigbagbọ ninu ara ẹ ati ninu Ọlọrun, awọn kinni yẹn maa n jẹ keeyan tete debi to n lọ.

Ko si igbesẹ kan tabi iṣipopada kan teeyan ba fẹẹ ṣe, to ba tako eyi teeyan n ṣe lọwọ, to jẹ pe eeyan o ni i maa ṣiyemeji lori ẹ pe boya o maa jẹ tabi ko ni i jẹ.

Ṣugbọn ootọ inu ati alaye ọrọ leke, igba ti mo maa fi lọ yẹn, ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ti n ronu bi mo ṣe n ronu, pe ọmọluabi la pe ara wa, tori nnkan ta a fẹẹ jẹ, a o gbọdọ fi ba nnkan ta a fẹẹ jẹ jẹ, a o gbọdọ ba ọjọ ọla wa jẹ, ao gbọdọ ta ọjọ ọla awọn ọmọ wa.

Ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ba mi ronu bẹẹ yẹn, wọn dẹ duro ti mi, wọn ni ki n niṣoo, ṣugbọn ko sowo, ko seeyan. Iyẹn lo fa a nigba yẹn to fi jẹ pe laarin kan, Agọ ọlọpaa Panti, ni Yaba, ranṣẹ pe wa, wọn ni ka wa,lori awọn ọrọ ti wọn sọ fun wọn nipa wa ni o.

A debẹ, ọtọ ni nnkan ta a gbe, ọtọ ni nnkan ti wọn ju, wọn gbe wa, wọn ti wa mọle, ṣugbọn awa naa ṣaa n sapa wa lọtun-un losi, iwọnba ọpọlọ ati ọgbọn t’Ọlọrun fun wa, a gbe lọọya dide,a ṣaa pada jade kuro ni Panti.

Lẹyin Panti naa, oriṣiiriṣii idunrunmọ, a n ko ibọn tira ẹni ti ki i ṣe kekere, ni ibudokọ Ikọtun ni, to jẹ pe awọn Area Commander Area M, n’Idimu Ikọtun, wọn duro sibẹ bayii, to jẹ pe wọn ti gẹgun de wa.

Awa fẹẹ ṣepade nibẹ lọjọ yẹn ni, awọn ti duro pe ta a ba ti de o, awọn maa pa ọta wa ni. Awa dẹ n ba tiwa lọ pe ka lọọ ṣepade ni. Emi o tiẹ ti i debẹ tawọn ọmọ mi ti n pe mi, ti wọn n sọ fun mi pe wahala ti n ṣẹlẹ o, awọn ọlọpaa wa nibẹ ti wọn n duro de mi o.

Igba ti mo maa debẹ, awọn ọlọpaa yẹn n ba mi sọrọ lọwọ, wọn lawọn naa ri ohun to wa nilẹ, awọn ti ribi ti ootọ wa, awọn ti ribi tawọn ọmọ ẹgbẹ fẹ. Wọn ni ṣugbọn awọn fẹẹ bẹ mi, ki n ma lọ si Olu ile.

Ibi ti wọn n pe ni Olu ile yẹn lati n ṣepade, Aarẹ wa oni yii lo ra ibẹ fun wa, wọn ra a fun OPC ni, orukọ OPC ni wọn fi ra ibẹ, to tumọ si pe gbogbo OPC lo lẹtọọ sibẹ. Emi n sọ nigba yẹn pe emi naa o ni i kuro nibẹ, mo ni ibẹ ni mo ti maa maa ṣepade ẹgbẹ temi naa.

A fẹẹ lọọ ṣepade, awọn ọlọpaa yẹn waa da wa duro, wọn ni ki n jọọ, pe ka ma lọ sibẹ yẹn, pe awọn maa wa aaye mi-in fun wa.

Emi ati ọlọpaa yẹn ṣi jọ n sọrọ lọwọ ni wọn ti n yinbọn bọ lọdọọ wa, emi dẹ n jẹ ko ye ọlọpaa yẹn, mo ni wọn n yinbọn bọ nibi yii o, mo ni ti wọn ba debi, emi o ni i kawọ sẹyin o, emi naa maa ṣe nnkan to yẹ k’emi naa ṣe gẹgẹ bii ọkunrin o.

Nigbẹyin ṣaa,  a da ẹgbẹ tiwa silẹ, a waa sọ ọ ni OPC, a wa fi Reformed yẹn sẹyin, ko ma baa da bii ROPC. Emi o ki n fẹ ki wọn maa sọ pe boya mo n ṣe nnkan kan mo n kọpi eeyan, ko ma da bii Reformed Ogboni Fraternity, mo ni ẹyin ni mo maa fi Reformed temi si, ba a ṣe fi Reformed yẹn sẹyin niyẹn.

Yatọ siyẹn, wọn le wa lọtun-un, le wa losi, awọn aa maa dunkooko mọ wa pe awọn maa pa wa, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe lonii yii, awa naa la ṣi n sọrọ yii.

Ọpọlọpọ awọn ti nnkan o ye nigba yẹn, nnkan ti ye awọn naa bayii. Ṣe ẹ mọ, nigba mi-in, nnkan teeyan fẹẹ jẹ ki i jẹ kẹlomi-in le ronu bo ṣe yẹ ko ronu, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oju kaluku ti la nisinyi. Ọrọ akọmọna wa niyẹn, ta a ba ti ni Ọmọ Oodua ni mi, to o ba ti ni tọkan-tọkan, ẹẹkeji, wa a ni oju ẹ ti la. Eeyan kankan o le muuyan kan lẹru mọ lori awọn nnkan to wa nilẹ yii.

Ipenija pọ loriṣiiriṣii, ṣugbọn mi o le maa sọ gbogbo ẹ naa lori afẹfẹ bẹẹ yẹn. A dupẹ pe ẹgbẹ n lọ bo ṣe yẹ ko lọ, awa naa la ṣi wa yii, ọmọ ẹgbẹ dẹ n le si i ni, a o pẹdin.

 

OPC Reformed ko ba awọn igun yooku ṣọta, a o si kere ninu aye, aṣiri wa gidi

 Ko si ẹgbẹ kankan ti emi o ba ni ajọṣepọ, nitori igbagbọ mi ni pe nnkan kan naa ni gbogbo wa jọ n ja fun, a kan maa n mu ojukokoro ati ọkanjua mọ nnkan ta a n  ṣe ni. K’Ọlọrun yọ iyẹn kuro lọrọ awa Yoruba lapapọ. 

Ẹgbẹ mi pẹlu ẹgbẹ Iba Gani Adams, ti nnkan ba da wa pọ, a jọ maa n ṣe e, ko si ẹgbẹ kankan ti mo ṣe lodi si, bo tilẹ jẹ pe laarin yẹn naa, igbesẹ yẹn, Gani Adams ati Baba Fasehun ni wọn jọ tẹle Jonathan lori idaaabo-bo ọpa epo nigba yẹn, to jẹ pe kinni yẹn bi oriṣiiriṣii silẹ ti ko dẹ yẹ ko ri bẹẹ.

Ṣe ẹ mọ, Gani ti wa laye ẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ, Baba Faṣehun naa dẹ wa, ọdọ Baba Faṣehun lemi dẹ wa, nnkan kan ko da wa pọ naa rẹpẹtẹ bẹẹ yẹn, ṣugbọn lẹyin igba yẹn, a ti pade lode ri ti wọn dẹ ti jọ pe awa mejeeji jade, pe ka ma jẹ ki wahala ṣẹlẹ, ka ṣe ara wa lọkan ki nnkan le dan mọọnran fun wa. 

Emi o ni nnkan kan ninu si ẹnikẹni, inu ara mi ni mo mọ, ṣugbọn lori ọrọ ilẹ Yoruba yii, ti mo ba lohun ti mo fẹẹ ṣe nibẹ, ma a lọ sibẹ, ti nnkan ba dẹ kan lọdọ temi naa, gbogbo wọn naa ni wọn n wa sọdọ mi, fun idi eyi, ajọṣepọ wa naa ni mo maa pe iru iyẹn.

Nipa jijẹ alagbara OPC taye mọ ẹgbẹ wa fun, nnkan ti OPC fi n jẹ OPC naa ni aṣiri.

Ti ko ba ti si aṣiri, ko si OPC. Tẹ ẹ ba ri OPC kan to sọ pe tohun ba kan, hmmm.

Ninu ẹgbẹ, a o fẹ iyẹn ku, Kristẹni wa ninu wa, Musulumi wa ninu wa, awọn ti wọn dẹ je pe Iṣẹṣe pọnbele ni wọn n ṣe, ti wọn o ṣe ẹsin kankan wa ninu wa. Ṣugbọn igbagbọ onikaluku lo maa n mu un lara da.

To o ba mọ pe Bibeli rẹ, to o ba ti ka Psalm 91, ti wọn ba n yinbọn bọ to o ba gbe e duro, wọn o ni i dọdọ ẹ, o lẹtọ ati lo o.

Bo dẹ jẹ Quran ẹ naa lo maa ni Fathia lo fẹẹ ka ti ibọn o ni dọdọ ẹ, o lẹtọọ ati lo o. Iwọ to o dẹ mọ pe nnkan mi-in wa to o fẹẹ lo, to o mọ pe ohun lo maa ṣiṣẹ to o maa fi lọ sibi to n lọ, to o maa fi bọ layọ, o lẹtọọ lati lo o.

Mo ranti igba ta a lọ sibi kan nikọja Ikorodu, ni 2016 naa kọ ni, nigba yẹn lawọn ọmọ kan paayan. Baalẹ ilu yẹn sọ pe o kere tan, pe wọn o paayan ninu ilu yẹn lọjọ kan, o ni wọn aa pa to eeyan mẹta, wọn n paayan niluu yẹn lojoojumọ ni.

Akoko yẹn ni awọn ajinigbe gbe ọba Oniba ana, ki i ṣe eyi to wa nibẹ nisinyi o, awọn ajinigbe kan wọ aafin wọn, wọn lọọ ji wọn gbe, igba yẹn ni.

Ti mo jade ti mo wọ ilu yẹn lọ nigba yẹn, ọkan ninu awọn akọroyin to wa nibẹ wa n sọ fun ọkan ninu awọn ọmọ mi pe ọga yin yii, boun ṣe n wo o yii, o de da bii pe ina n jade loju ẹ.

Mo wa n jẹ ko ye iyẹn pe ko ma da wọn lohun, ẹni ti wọn maa maa gbe lẹnu jo ni wọn n wa, Ọlọrun naa ṣaa ni ka maa kepe.

Pataki ibẹ julọ ni pe, nnkan ta a gbe dani yii, ko ṣee fi oju lasan ṣe, ko dẹ ṣee fi gbẹrẹ ṣe, afi teeyan ba fẹẹ da ẹmi ara ẹ legbodo lo ku, k’Ọlọrun ma dẹ da ẹmi wa legbodo.

Nnkan ta a maa ṣe, Ọlọrun ti fi han wa, iwọ to o ba wa ni o ṣe nnkan yẹn, to o dẹ fẹẹ gbe nnkan ta a gbe dani yii dani, tọọ, Ọlọrun aa tubọ maa da aabo bo gbogbo wa ṣaa.

Lọrọ kan, aṣiri wa sibẹ ti ko kuro nibẹ. Aṣiri yẹn o dẹ le kuro nibẹ titi laelae. A faaye gba ẹsin, ko si ẹsin teeyan n ṣe ti ko si ninu ẹgbẹ, bi mo ṣe sọ, Kristẹni wa nibẹ,  Musulumi wa nibẹ,awọn Oniṣẹṣe dẹ wa nibẹ, gbogbo ẹ lo wa ninu ẹgbẹ, ohun ti kaluku dẹ n ṣe ko di nnkan ta a n ṣe ninu ẹgbẹ lọwọ.

 Ta a ba n ṣe nnkan ta a n ṣe yii, a maa n pe awọn aafaa nigba mi-in pe ki wọn ṣadua fun wa, aa maa pe awọn Kristẹni naa, awọn wolii, ki wọn ṣadua fun wa nigba mi-in. To ba dẹ di igba ti Iṣẹṣe naa, a maa ṣe e, bo ṣe ri niyẹn, gbogbo ẹ lo wa ninu ẹgbẹ.    

 

Ọrọ owo ti Jonathan gbe fun Gani Adams ko kan mi, owo Gani ko si lọdọ temi o

Ṣe ẹ mọ pe mo sọ ọ lati ibẹrẹ pe emi ni Akọwe agba fun Baba Faṣehun, owo ti Jonathan ba gbe fun Gani Adams atawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ ko kan mi, mi o dẹ lẹtọọ lati lọọ yọju sibẹ, emi o dẹ ki n da si nnkan ti ko kan mi, iyẹn o kan mi, ko ra mi rara.

Ṣugbọn eyi to kan mi ni ti ọrọ Ọmọwe Faṣehun ati ọrọ ilẹẹ Yoruba. Nnkan to ṣẹlẹ nisinyi, ka ni emi loju kokoro owo ni, ẹ jẹ n ṣalaye kinni yii.

Ṣe ẹ ri i, ko ye ọpọlọpọ eeyan bi kinni yii ṣe bẹre gangan. Igba ti ọrọ iṣẹ ṣiṣọ ọpa epo yẹn maa bẹrẹ gangan, Ikọtun lo ti bẹrẹ.

O ni ọlọpaa kan to jẹ ọrẹ wa to maa n wa sọdọ wa, awa ni ẹkun kan (zone) lagbegbe yẹn, ibi ti zone yẹn wa jẹ adugbo ti ọpa epo gba kọja, o wa pe wa lọjọ kan pe ṣe wọn n fun wa lowo la fi duro nibi ta a wa yii ni, awa ni owo bawo, ko sẹni to n fun wa lowo o, a sọ fun un pe a o fẹ ki aṣemaṣe wa nibi ta a ba wa la ṣe n wa nibẹ. O wa ni kinni yẹn, owo buruku ni o, pe o le di owo fun wa.

Ọgbẹni ọlọpaa yẹn lawa wa ba sọrọ pe to ba jẹ pe loootọ ni kinni naa le di owo fun wa, ko ma jẹ ko jẹ pe adugbo wa n’Ikọtun nikan lo ti maa di owo, pe ka kuku ṣe e ki gbogbo ẹgbẹ jẹ anfaani ẹ. La fi mu ọlọpaa yẹn lọọ ba Ọmọwe Faṣehun nijọ kin-in-ni ana, emi, maanu kan, Alaaji Taofik to jẹ National Organizing Secretary, Alaaji Muda to jẹ Monitoring Commander nigba yẹn, pẹlu Ṣọla Edward to jẹ P.R.O la ṣaa jọ jokoo ta a ṣagbatẹru ẹ.

Nigba to di asiko kan, Alaaji Muda yẹn o yọju mọ, o ku awa mẹta. Gbogbo eto pata ti wọn ṣe lori ọrọ iṣẹ yẹn, awa la ṣe gbogbo ẹ pẹlu Baba Faṣehun. Ẹyin-o-rẹyin to di aarin kan, ṣe ẹ mọ pe ọrọ Naijiria, jẹ ki n jẹ ni wọn fi n ṣe. Igba to di aarin kan lawọn kan sọ pe awọn  o le wojuu Baba lori iṣẹ yẹn, ni wọn fi gbe Gani Adams wọle.

Gani o mọ biṣẹ yẹn ṣe jẹ, Baba dẹ pe oun naa wọle pe bo ba ṣe jẹ, ko kuku je pe  gbogbo OPC ilẹẹ Yoruba lo maa maa ṣe kinni yẹn.

 Igba to wa ti n di pe ọrọ ti Ọṣinbajo wa jẹ jade, ti wọn sọ fun wọn pe ohun ti wọn fẹẹ gbe wa yii, a gbọdọ fi ṣiṣẹ fun ẹgbe wọn ni o, kawọn le di aarẹ o, to dẹ jẹ awa naa la n sọ latijọ yii pe wọn n fiya jẹ Yoruba, Yoruba o nipo kankan ninu ijọba, ki la le ṣe ka fi ni ilọsiwaju, ti Ọṣinbajo dẹ jade gẹgẹ bii Igbakeji, iyẹn lawa fi wo o pe to ba jẹ nitori nnkan ta a fẹẹ jẹ ni, awa o ni i ba yin ṣe e.

 O daa ka kuku tẹle ọmọ Yoruba tiwa, ka dẹ nigbagbọ pe to ba debẹ, bo tiẹ jẹ pe a ri i bo ṣe ri naa, pe to ba debẹ, ayipada aa le de ba gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ, ohun ti awa duro le lori niyẹn, ibura ta a bu niyẹn, pe Yoruba lo maa ṣiwaju ninu gbogbo nnkan ta a ba n ṣe. Ki i ṣe ọrọ pe boya kinni.

Ka ni nigba yẹn, emi yii gba ni atawọn to ku,pe owo lo delẹ yii, ẹ jẹ ka lọọ pin owo, a maa gbowo gidi lọwọ baba nao, a maa gbadun, a maa ṣe nnkan ta a fẹẹ ṣe.

Emi ni akọwe nao, igba yẹn dẹ ree, ẹni to jẹ Igbakeji ti ṣalaisi, emi ni mo da bii Igbakeji Baba. Ẹni to jẹ National Organizing ni amugbalẹgbẹẹ, ẹni to jẹ ikẹta ni P.R.O. Awa ta a di ẹgbẹ mu nigba yẹn niyẹn ti wọn ba n sọ pe ẹgbẹ Faṣehun, ni gbogbo igba yẹn, ki wọn lọọ beere lọwọ ẹnibọdi, awa ta n jẹ bẹ leleyii.

 

Gbogbo ipinlẹ kaakiri, ti Ọmọwe Faṣehun ta a lẹgbẹ si, awa ta a lọọ fẹgbẹ ọhun lelẹ fun wọn ree. Baba ti dagba, irin meloo ni baba fẹẹ rin.

Bi mo ṣe n sọ lọ, ọmọluabi la maa n pera wa nilẹẹ Yoruba, mi o dẹ ki n fẹ ko jẹ pe wa a ti sọ pe o fẹẹ ṣe nnkan, oo wa ni i ṣe e mọ. Ohun lo da bii ọrọ Ikorodu ti mo n sọ lọ lẹẹkan yẹn, mo fun awọn eeyan yẹn ni gbedeke ọjọ mẹrinla, pe ti wọn o ba dawọ nnkan ti wọn n ṣe ninu ilu yẹn duro, pe mo maa wọnu ilu yẹn, mo n bọ waa ba wọn, pe a maa fopin si i.

Ẹ o le wa silẹẹ Yoruba kẹ ẹ maa jiiyan gbe, kẹ ẹ maa paayan kẹ ẹ maa ṣe oriṣiiriṣi. Ọjọ to pe ọjọ kẹrinla gẹlẹ, mo wọnu ilu yẹn lọ taara ni.

Igba ti mo denu ilu yẹn,Kabiyesi yẹn bi mi pe ṣe mo nilẹ niluu awọn ni, o ni nitori lọjọ ti wahala naa ti n ṣẹlẹ, awọn o ri eeyan kankan to dide waa gbeja awọn. Mo ni mi o nilẹ nibẹ, ṣugbọn tori pe ọmọ Yoruba ni mi, tiya ba ti n jẹ ọmọ Yoruba, gbogbo ẹgbẹ wa lo ti n jẹ niyẹn, nitori naa, a jọ maa dide jija yẹn ni.

Igba ta a wọnu ilu yẹn, Amosun ni gomina nigba yẹn, lo pe, lo ni ki Kabiyesi ba wa sọrọ o, ko ma jẹ ki wọn da wahala silẹ o. Ṣugbọn  a dupẹ lọwọ Ọlọrun, ọjọ keji ta a kuro nibẹ ni awọn ọlọpaa, awọn ṣọja wọnu ilu yẹn ti wọn jẹ kalaafia jọba nibẹ.

Irin ta a rin lọjọ yẹn ni awọn ti wọn ji Kabiyesi Oniba ana ri, ni wọn fi fi wọn silẹ, wọn ni wọn sọ fawọn pe, ṣe nitori tawọn lawa fi jade.

Gbogbo owo ti wọn n beere, wọn o rowo kankan gba mọ. Kabiyesi ni wọn fi awọn sinu ọkọ, wọn waa ti awọn nikan pẹlu ọkọ ẹyọkan pe kawọn maa lọ, awọn maa ri ilu, wọn ni bawọn ṣe wa ọkọ tawọn fi deluu funra awọn niyẹn.

Igbesẹ ta a gbe nigba yẹn, nitori a ti sọ pe a  maa gbe e ni, emi o dẹ ki n sọrọ ki n ma ṣe bẹẹ, mo yatọ sawọn to maa sọ pe a maa pa igba, a maa pa awo, a maa debi kan, a maa lọ Aso Rock, irọ.

Afi ti mi o ba sọ ọ, ti mo ba ti sọ ọ, ‘action’ maa tẹle e bẹẹ ni. Nnkan to ṣẹlẹ niyẹn, ipinnu mi, nnkan ti mo ba Ọlọrun sọ pe iya o ni i jẹ Yoruba, to ba jẹ pe nnkan ti mo le ṣe nikapa mi lati dawọ iya yẹn duro, iya yẹn o ni i jẹ ọmọ Yoruba yẹn o.

Nnkan ta a ro niyẹn lori ọrọ yii, owo fun ni o to eeyan, owo maa tan nao, ki lowo.

Gbogbo awọn ti wọn ṣe kinni yẹn nigba yẹn naa nisinyi, ta a ba wọn sọ ti wọn o gbọ, ti wọn ro pe nitori owo wa nibẹ, awọn maa rowo, lopin gbogbo ẹ naa, ẹ beere pe elo ni wọn ri.

Ọtọ niye ti wọn n reti, ọtọ niye ti wọn fun wọn. Ati ju wa ni wọn ba lọ, aito ni wọn ba bọ, ọpọlọpọ wọn lo n kabaamọ, pe ka ni awọn tiẹ ti mọ ni, kawọn ma gbọ nnkan tawọn eeyan yẹn sọ fawọn.

Owo maa tan,nnkan ta a bura le lori ni kẹ ẹ jẹ ka maa duro le lori ka dẹ maa tẹle, bi aarin yẹn ṣe ri niyẹn o, ki i ṣe lori ọrọ olowode o. Owo Gani ko si lọdọ temi o.   

 

Walahi, bi mo wa nibi t’Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba Ọyọ ni, wọn o ni i dide

Ṣe ẹ ri iṣẹlẹ yẹn, o jẹ nnkan to dun mi gidi gan-an, idi to dẹ fi dun mi ni pe mi o ni oore ọfẹ ati wa ninu apejọ yẹn, nitori ọmọ ilu yẹn gangan ni mi, ọmọ Iṣẹyin ni mi.

Walahi, ka ni mo wa nibẹ, awọn ọba yẹn o ni i dide. Mo maa n sọ ọ daadaa ti mo ba lọ sode, ti mo ba ri aṣoju ijọba yoowu nibẹ ti mo dẹ tun ri ọba nibẹ, ma a kọkọ ki ọba ki n too ki aṣoju ijọba yẹn. Nitori ọdun eegun lọrọ wọn, ọdun maa tan ni, ṣugbọn awọn ọba wa nibẹ kanrin-kese ni.

Owe ti Yoruba maa n pa, pe b’ọba kan o ku, omi-in ki i jẹ, awọn oloṣelu yii naa lo gbe e de pe bọba kan o ku omi-in le jẹ, nibi ọwọ agbara ti wọn n lo.

Iwe ofin ilẹ wa ti wọn dẹ n lo lori ọrọ ọlọbade lo fa a. Kinni yẹn jẹ nnkan to gba riro, o yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba maa sunkun ni, ṣugbọn ṣe ẹ mọ pe ọna irori kaluku wa yatọ, ọna ti kaluku maa n gba ro nnkan yatọ sira wọn.

Ẹlomi-in aa kan ronu pe ẹn, awọn ọba yẹn naa, ṣebi nnkan toju wọn wa lojuu wọn ri, ọba meloo ni wọn fi Ifa mu mọ, ṣebi ọna ẹburu ni ọpọlọpọ ninu wọn gba ti wọn fi debi ọba ti wọn de yẹn.

Wọn aa ni nnkan toju wọn wa lojuu wọn ri o, ko kan awọn.

Ṣugbọn mo fẹ sọ fawọn to ba ni iru ero bẹẹ, pe ko si bo ṣe le wu ko ri, Yoruba naa ni wọn ṣi maa maa pe wọn. Fun idi eyi, a maa kọkọ le akata lọ na, ka too waa fabọ ba adiẹ ni, la ṣee gbọdọ maa ṣọ iru awọn ọrọ bẹẹ yẹn.

 Labẹ ẹtọ, ọba ba lori ohun gbogbo, awọn ọba ati gbogbo Yoruba gbọdọ ja ija lori ba a ṣe maa pada si bi wọn ṣe n yan ọba gangan, to jẹ pe ẹni ti Ifa rẹ ba pọ ju lo maa n jọba, ti wọn o ni i figba kan bọ ọkan ninu mọ.

Iru nnkan to ṣẹlẹ nijọ yẹn bayii, awọn ọba yẹn naa, wọn o jẹwọọ pe ọba lawọn, o yẹ ki wọn jẹwọọ pe ọba lawọn ni.

 Ẹ maa ri i pe tẹ ẹ ba wo kinni yẹn lọjọ yẹn, mo wo o mo dẹ n tun un wo, awọn kọọkan tun n rẹrin-in ninu wọn. Mo waa wo o pe haa, nitori nnkan ti wọn fẹẹ jẹ, wọn dẹ... (Aarẹ  dakẹ) haa, gbogbo Yoruba ni wọn n ta!

Gbogbo Yoruba patapata ni wọn ta, ki i ṣe ara wọn ni wọn ta, omi-in tun n rẹrin-in ninu wọn, ọrọ to jẹ o yẹ ki oju gbogbo wọn le ni, ṣe o fẹ na wọn ni?  Ko le na wọn! Ṣugbọn ẹru o jẹ.

 Ka ni lọjọ yẹn, wọn pe ara wọn jọ pe awa ni maanu yii dọti bayii, nitori Ọlọrun, ki la le ṣe fun un, kawọn naa pe bíríkótó, ki wọn pe bìrìkòtò, ki wọn dẹ jẹ ki nnkan kan ṣẹlẹ ko dẹ mọ pe ọdọ wọn ni nnkan yẹn ti wa.  Ẹlomi-in o ni i dan iru ẹ wo mọ, ṣugbọn nitori pe awọn naa kan wo o, wọn dẹ fi ṣe osun, wọn fi n para, wọn ti gbagbọ pe awọn ko ni onigbeja, nitori awọn naa ko mu un bo ṣe yẹ ki wọn mu un mọ.

Ọba mi-in aa ni oun ki i ṣe ọba Oniṣẹṣe.    

Ṣe ẹ wa ri ti awọn ti wọn n sọ pe ijọba ju ọba lọ labẹ ofin Naijiria, mo ti sọ ọ siwaju pe ọna ti kaluku n gba ronu,ọtọọtọ ni.

Ẹni to sọ bẹẹ naa ri i sọ, nitori tẹ ẹ ba wo ofin Naijiria, o ti fi awọn ọba sabẹ ijọba.

Ko too di pe awọn oyinbo amunisin, awọn oyinbo waa mu wa lẹru, bawo la ṣe n ṣejọba ara wa? Ṣebi awọn ọba lo n ṣejọba fun wa. Mo ti sọ ọ siwaju, mo lo yẹ ka ja lori ofin to fi ọba si abẹ awọn oloṣelu.

Ọba funra ẹ naa dẹ tun le ja funra ẹ to ba loun o fẹ, ma foko mi ṣọna, ọjọ kan leeyan n kọ ọ. T’ọba ba dide to loun o fẹ nnkan kan latọdọ yin, ẹ fi mi silẹ, mi o nilo ọpa aṣẹ latọdọ yin, ẹ ṣe maa gbe ọpa aṣẹ fun mi,awọn oloye afọbajẹ wa nao, awọn ni ki wọn gbe ọpa áṣẹ fun mi, ko dẹ duro lori ẹsẹ rẹ.

To ba kọ kinni yẹn fun wọn, toun ba ri i ṣe, omi-in naa maa ri i ṣe. Ọba meloo lo le ṣeru nnkan yẹn, idi ati itumọ rẹ naa si ni pe ọba mi-in gan, ọba ko tọ si i, awọn oloṣelu yii naa lo lọọ ba, pe ẹ jọọ, ẹ ti mi lẹyin, ti mo ba debẹ, ma a ṣe’fẹ yin. Ṣe iru ọba bẹẹ yẹn, to ba waa debẹ, ki lẹ ro pe o maa ṣe?   

Ẹyin naa e wo igba ti awọn oyinbo n ṣelu pẹlu ti ọlọbade ta a n ṣe lọwọ nisinyi.

Ṣe a ni ọba ni igberiko kiri nigba yẹn, ọba gan-an ti pọju bayii, nnkan to fa ti ko ṣe fẹẹ niyi loju awọn ijọba yẹn mọ niyẹn.

Ka ni ọba mọ niwọn bo ṣe ri nigba yẹn lọhun-un ni, ti ki i ṣe pe adugbo kan, ọba kan, adugbo ibẹ yẹn,ọba mi-in wa nibẹ,ẹnu ọba gan-an aa tolẹ, ẹnu ọba aa de ka ilu, nitori ẹni ti wọn fẹẹ fi jọba, to jẹ Iṣẹṣe lo mu un to dẹ ṣe oro ile fun un to pe, gbogbo ilu aa duro ti i, nnkan to dẹ maa fi jẹ ọba yẹn, wọn aa pese ẹ fun un.

 Ṣugbọn to ba ti lọọ n ba oloṣelu, hmmm.

Fun idi eyi, kinni yẹn, igbaju lojuu gbogbo ọmọ Yoruba ni, oun lo fi jẹ pe awọn eeyan maa n sọ ọ nigba mi-in pe Baba Ọbasanjọ ki i ṣe Yoruba, pe ka ni wọn jẹ Yoruba ni, awọn igbesẹ kọọkan ti wọn maa n gbe, wọn o ni i gbe e.

Ẹ wo igba ibo Awolọwọ, Ọbasanjọ wa nibẹ, iyẹn lọ bẹẹ yẹn. Ẹ wo igba ti MKO Abiọla naa,igba ti Ọbasanjọ ṣẹṣẹ waa kuro nibẹ, ti Buhari, Hausa debẹ lo ṣẹṣẹ waa ranti Abiọla, to waa fi iyi rẹ fun un, nnkan to yẹ kẹyin ṣe.

Ẹ sọ nnkan ti baba yii ṣe!

Ọrọ yii n dun mi gan-an, ka ni mo wa nibẹ lọjọ yẹn sẹẹ, awọn ọba yẹn o ni i dide, nnkan to ba maa ṣẹlẹ lo maa ṣẹlẹ, nitori ma a jẹ ko ye wọn pe laye, ẹ o le maa dọtii Yoruba, aṣeju yin ti n pọju.

 Ẹ wo idibo to lọ yii naa, ṣe wọn duro ti Aarẹ to wa nibẹ lọwọlọwọ yii? Ṣebi ọtọ lẹni ti wọn ti lẹyin. Gbogbo nnkan to ba ti jẹ mọ Yoruba, ko yẹ ki wọn maa pe wọn sibẹ mọ. Nnkan to yẹ ki gbogbo awa Yoruba ṣe nisinyi ni pe, ode eyikeyi to ba jẹ ti Yoruba, wọn o fẹẹ ri wọn nibẹ, nitori wọn o ṣojuu wa.

Ṣugbọn ẹnu o ko, bẹnikan ba loun fẹẹ ṣe e, awọn kan aa gba ẹyin, wọn aa tun lọọ sọ aṣiri yẹn fun wọn pe awọn fẹẹ ṣẹ nnkan bayii, awọn kan aa tun ni awọn o ba yin ṣe e o, awọn o ba yin si ninu ẹ o, nitori awọn nnkan ti wọn maa jẹ ti ko jẹ ki wọn gbọn, wọn le ro pe awọn le ri awọn anfaani kan jẹ, nnkan to dẹ n fa ọwọ aago wa sẹyin nilẹẹ Yoruba niyẹn.

Gbogbo wa gbọdọ dide, ka fẹnuko pe gbogbo ode to ba jẹ mọ ti Yoruba, ẹ ma pe baba yii sibẹ mọ.

Nitori tẹ ẹ ba ro pe boya o ti tan, pe eyi to le ṣe to maa ṣe mọ naa lo ti ṣe yẹn, ẹ ẹ ti i ri nnkan kan o, omi-in ṣi n bọ o, to tun maa fẹẹ le ju eyi to ṣẹlẹ yẹn lọ.

Imọran mi fun gbogbo ọba ilẹ Yoruba ni pe ki wọn pe ara wọn jọ, ode yoowu ti wọn ba pe wọn si ti wọn dẹ pe Baba Ọbasanjọ sibẹ, ki ẹnikẹni ninu wọn ma debẹ.

Awa naa ta a wa jẹ ọmọ Yoruba,kawa naa waa dide pe ayẹyẹ yoowu ti wọn ba pe baba yii si, a n lọ da ibẹ ru ni, baba yii o ni i ṣojuu Yoruba nibi kankan. Nnkan ti mo ro pe a le  ṣe niyẹn, nitori idọti ti ko daa rara ni kinni yẹn.   

 

Ọba to fi Iṣẹṣe joye, to debẹ tan to ni ko sohun to n jẹ bẹẹ, ojuṣe awọn ọmọ ilu rẹ ni lati le e lọ

 Awọn afọbajẹ ni wọn ni iṣẹ yẹn lọwọ, nnkan ki nnkan teeyan ba n ṣe laye yii, ko gbiyanju ati ri i pe oun ṣe e debi ami.

Gbogbo ayinike ati ayinipada to ba dẹ wa nibẹ, ko ri i daju pe gbogbo ẹ patapata loun mọ. To ba ti n di pe eeyan mọ ayinike, ko mọ ayinipada, ki i jẹ keeyan le tẹsiwaju bo ṣe yẹ.

Ọba yoowu to wọ Ipebi, to de ori itẹ tan to wa ni rara o, nnkan to loun lọọ ṣe ninu Ipebi yẹn, oun lọọ ṣere nibẹ ni o, Musulumi loun o, oun fẹẹ ni mọṣalaaṣi laafin o, ko sẹni to lodi si i.

Ṣugbọn ko wa ni oun fẹẹ ni mọṣalaaṣi laafin, gbogbo nnkan ti wọn fi wa ṣe oro ile foun, ki wọn lọọ ko gbogbo ẹ sẹgbẹ kan, oun o fẹẹ ni nnkan kan i ṣe pẹlu wọn mọ.  

O yẹ kawọn afọbajẹ yẹn tun yi ìlù yẹn pada ni. Ki wọn waa lọọ ba awọn kinni yẹn sọrọ, pe ohun bayii-bayii ta a ṣe nigba bayii-bayii, o tun ni ko tun ri bẹẹ mọ o, o ya, ẹyin funra yin, idajọ to ba tọ si i, ẹ ṣe e, ki ọba yẹn dẹ bẹrẹ si i ri i lara ẹ lẹsẹkẹsẹ pe wọn ti ṣe kinni yẹn foun.

Ṣugbọn ṣe ẹ mọ, ẹlomi-in aa kan ṣepe, aa ṣe oriṣiiriṣii pẹlu wọn, lopin gbogbo ẹ, aa dẹ mu un jẹ. Bawo ni wọn ṣe waa fẹ gbagbọ pe loootọ, oun tẹ ẹ le gbe dani pe o n ṣiṣẹ n jẹ loootọ.

Iyẹn ki i ṣe ọrọ gbogbo ọmọ Yoruba, nitori ni gbogbo adugbo nisinyi, gbogbo ilu lo lọba tiẹ, kaluku niluu tiẹ lo maa ṣe idajọ to tọ ati eyi to yẹ lori aarin yẹn.

Ara Ẹdẹ ko ni i lọọ ba ara Iwo le ọba wọn kuro nibẹ,nitori o ni musulumi loun. Awọn araalu gangan ti wọn jẹ ọmọ Iwo ni wọn maa dide pe rara, bo o ṣe jọba kọ  niyẹn, nnkan to o fi jọba, oo le pa a ti.

Wọn o ni i ko o ma ṣe Islam, wọn o ni i ko o ma ṣe ẹsin, ṣugbọn eyi to gbe ẹ debẹ yẹn naa, oo gbọdọ fọwọ rọ ọ sẹyin, to o ba ti mọ pe nnkan to o fẹẹ ṣe niyẹn, o bẹta ko o ma debẹ rara.

 Awọn agbalagba ni nnkan teeyan ko ba ni i jẹ, ko ni i fi runmu. Iwọ to o ba ti mọ pe pastọ lo fẹẹ di, o dẹ ti mọ pe pastọ ẹ o, oo le mu nnkan mi-in mọ ọn, ma sunmọ idi ọba nao.

Lagbo ile ẹ, ti wọn ba ni iwọ lọba kan, iwọ nikan kọ lọba maa kan lagboole ẹ nao, wọn  aa gbe e fẹlomi-in ti Ifa ẹ kun tẹle tiẹ, wọn aa ṣe nnkan to yẹ funyẹn, iyẹn aa dẹ bọ sori apeere ọba yẹn. Ṣugbọn ko o waa tan wọn tan, ko o gba ọba yẹn, iyẹn o daa.

Ohun to tiẹ tun yaayan lẹnu ju ni pe ẹlomi-in, ki wọn too fi i jọba, wọn aa ti mọ pe teleyi ba jọba, o maa yi gbogbo nnkan tawọn ba ṣe pada ni, ṣugbọn nitori awọn ẹsun teretere owo to n fun awọn afọbajẹ yẹn, o maa jọ wọn loju debii pe wọn o ni i ka gbogbo kinni yẹn kun tiyẹn maa fi debẹ, ta a wa ba gbogbo nnkan ti wọn ṣe yẹn jẹ mọ wọn lọwọ.

Fun idi eyi, ọpọ igba lo jẹ pe owo lo maa n sabaa fa gbogbo kinni yii, lo maa n sabaa ba gbogbo nnkan ta a n ṣe jẹ.

Ẹyin tẹ ẹ dẹ n pe ara yin ni afọbajẹ, tẹ ẹ n ṣe awọn eto yii, tẹ ẹ ba ni nnkan agba to, ẹ ẹ dẹ sun mọ awọn mi-in ti wọn ni in, ẹ maa ni ki wọn fi bo yin  laṣiiri, ẹ ẹ dẹ gba a sọwọ, ẹ ẹ dẹ maa lo o.

Eeyan o ki n ni i tan nao, nitori ibi ti tẹnikan pin si ni ti ẹlomi-in ti bẹrẹ, eyi to o ba mọ pe o nilo, to o ni, wa a dẹ sunmọ awọn mi-in ti wọn ni, wa a ni ki wọn jọọ, ki wọn ṣaanu ẹ pẹlu kinni yẹn o, iya ẹ lo n jẹ ẹ o, ẹ ya mi o, wọn aa fun ẹ nao, wa a dẹ maa lo o.

Nnkan to n da gbogbo ẹ silẹ niyẹn o, ki i ṣe ọrọ pe gbogbo Yoruba lo maa dide si i , ilu silu lo maa dide si tiẹ.

Ti wọn ba ti fi jọba tan to waa dide to ni Musulumi loun tabi Kristẹni, oun o ba yin ṣe kinni yẹn mọ, haha, ẹ dagi jọ fun un nao to ba fẹ le ju. Ẹ lu u bii kinni, kẹ ẹ le e kuro laafin. Ọlọrun aa ba wa ṣe e o.

 

 

Ọmọ ale Yoruba nikan lo maa ni bi Aarẹ Tinubu ṣe n pin ipo pataki fawọn ọmọ Yoruba ko daa

 Hmmmm, ẹ o mọ pe nnkan to bi OPC Reformed gan-an  ree, a ni wọn koyan wa kere niluu wa, wọn rọ wa sẹyin. A wa debẹ nisinyi,ẹni to ba n sọ iru ọrọ yii, pe Aarẹ Tinubu n pin ipo pataki fawọn ọmọ Yoruba, ẹ ni ko wo igba ijọba Buhari, ki wọn wo ti Jonathan, ki wọn wa gbe e yẹwo si ohun to wa nilẹ nisinyi.

Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣi pin in kari, ẹtọ to yẹ ki wọn ṣe fun wa ti wọn o ṣe fun wa ni wọn ṣẹṣẹ ba wa ṣe nisinyi, ko gba ẹnu ẹnibọdi pe boya gbogbo ipo to ni kimi ni wọn ko fun Yoruba.

Ẹni to ba n sọ ọ, bii igba teeyan yẹn kan n jowu ni. Nitori awọn ti wọn wa nibẹ, a ti ri nnkan ti wọn ṣe

Ṣe ẹ mọ pe lori ọrọ Baba Ọbasanjọ ti mo sọ yẹn, ẹ mọ pe nigba ti wọn ṣejọba laye alagbada ti wọn ṣe gbẹyin, igba yẹn ni wọn ni ki wọn bẹrẹ si i yinbọn fawọn ajijangbara Yoruba.

Ẹ wo igba ti Jonathan debẹ, ẹ wo nnkan to ṣe fawọn ajijangbara Niger Delta, awọn Tompolo, awọn Asari, ẹ wo bo ṣe ro wọn lagbara to ko irinṣẹ fun wọn.

 Ẹ wo igba ti Buhari naa debẹ, awọn Fulani to jẹ ọpa ni wọn fi n da maaluu tẹlẹ, wọn ko AK 47 fun wọn ni. Igba Ọbasanjọ, ki lo ṣe fawa ajijangbara ọmọ Yoruba, wọn o ṣe nnkan kan fun wa, kaka bẹẹ, wọn ni ki wọn maa lọọ pa wa.

A tun wa rẹni to wa nibẹ nisinyi to ni ka ma wọri, iya tẹ ẹ ti n jẹ latijọ yii to gẹẹ o.

Ni tododo, ọmọ Yoruba to ba sọ iru iyẹn, mi o le sọ ti awọn ẹya mi-in o. Ṣe ẹ mọ, ẹya mi-in lẹtọọ ati sọ ọ, iyẹn fi han pe o ti to asiko to yẹ ko dun awọn naa niyẹn, o ti n dun awa naa latijọ yii, o dẹ ti to asiko to yẹ ko dun awọn naa niyẹn. Ṣe ẹ ri i, nile aye yii, tara ẹni lakọkọ, oun ni Yoruba ṣe maa n sọ pe tina ba jo ni to jo ọmọ ẹni, tara ẹni la a kọọ gbọn.

Ọmọ ale Yoruba nikan lo maa sọ pe nnkan ti Aarẹ yẹn n ṣe lọwọlọwọ bayii lorii bi wọn ṣe yan awọn minista wọn yẹn n bi oun ninu, ẹni to ba jẹ ojulowo ọmọ Yoruba, inu ẹ gbọdọ maa dun si i ni. Nnkan to wa nilẹ yii, inu tẹmi dun si o.

 To ba tiẹ jẹ pe wọn n sọ pe awọn ti wọn yan ko yẹ nibi ti wọn fi wọn si ni, iyẹn ọtọ, to ba dẹ jẹ iyẹn naa ni, emi nigbagbọ pe Aarẹ ṣi fiṣu sina, wọn n wa ọbẹ ni, gbogbo ẹ ṣi maa yanju.

Ṣugbọn to tiẹ ti jẹ pe ọmọ Yoruba lo wa nibẹ lọwọlọwọ bayii, o jẹ idunnu temi, o jẹ nnkan ta a ti n reti tipẹ, mi o dẹ gbadura ko yipada.

 

Awọn afojusun wa ninu ẹgbẹ OPC Reformed wa ti n jẹ ṣiṣe.

 Akọkọ ni lati maa yi ero ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ pada. Ṣe ẹ mọ pe nnkan to ṣe pataki naa niyẹn. Idi teeyan fi maa n darapọ mọ ẹgbẹ maa n pe oriṣiiriṣii.

 Ẹlomi-in ri ẹgbẹ OPC bii ẹgbẹ to jẹ pe owo maa wa nibẹ, aa ni ẹ jẹ k’emi naa lọọ darapọ mọ wọn, ma a ri owo nibẹ.

 Ẹlomi-in ri i ni irii pe ẹgbẹ akọya ni, gbogbo awọn ti won n ṣakọ si mi laduugbo yẹn, ti mo ba dara pọ mọ OPC, nnkan ti mo maa foju wọn ri lo n lọ lọọkan yẹn.

Ẹlomi-in dẹ ri ni irii pe, gbogbo awọn baba mi, iya mi, gbogbo wọn ni wọn n ṣe e, ẹ jẹ k’emi naa lọọ ba wọn ṣe e. O di mẹta, abi?

Ẹlomi-in waa ri i ni irii pe, ẹgbẹ yii o, awọn fẹẹ fi kọya fawọn ọmọ Yoruba ni, awọn fẹẹ fi gba ẹtọ ọmọ Yoruba fun wọn ni, awọn fẹẹ fi da aabo bo ọmọ Yoruba ni. Iru nnkan to wu oun lọkan lati ṣe niyẹn, ẹ jẹ ki n lọọ darapọ .

Eyi ti mo sọ gbẹyin yii ni emi n gbin si awọn ọmọ ẹgbẹ lọkan nisinyi, ti mo de ro pe oun lo ṣe pataki, ti mo dẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun, pe Ọlọrun n ba mi ṣe.

O pọ, mẹta ti mo sọ siwaju yẹn ṣaa ni ọpọlọpọ to wa ninu ẹgbẹ fi n ṣe. Ẹlomi-in, eyi ti mo sọ gbẹyin yẹn lo gbe wọnu ẹgbẹ, ṣugbọn nigba to de aarin kan, pẹlu awọn iriri to ri, pe awọn to wa niwaju gan-an, ki ni wọn n ṣe, pe nigba tawọn aṣiwaju ba n gbowo orii wa, ṣe temi naa ba rowo awọn ọmọ to n bọ lẹyin temi naa gba, ṣe emi naa o ni i gba a ni. Gbogbo iru nnkan yẹn lo n ṣẹlẹ.

Awọn mi-in n wo OPC bii pe awọn wo leleyii, awọn elebi, awọn ọmọ ita ni wọn, awọn oloorun ni wọn, gbogbo iru nnkan bẹẹ yẹn lemi ni lọkan lati yi pada, Ọlọrun dẹ n fun mi ṣe.

O kere tan, mo ti ri ida marundinlọgọrin (75 %) iyẹn ṣe.  Ẹlomi-in n ri OPC gẹgẹ bi iṣẹ, ẹlomi-in o fẹẹ ṣiṣẹ, wọn aa ṣaa lọọ jokoo si Zone OPC lataarọ dalẹ, ki wọn maa gbe ẹjọ wa, ọkọ atiyawo maa ja laduugbo, wọn maa mu wọn wa, wọn maa ba wọn pari ija, ti wọn ba n lọ, wọn aa ni ki wọn fi owo ẹjọ silẹ. Gbogbo iru iyẹn ni mo ti n gbiyanju ati ṣiṣe le lori.

Ko o too le jẹ alakooso (Coordinator), iyẹn lakọkọ, ti alakooso ko ba niṣẹ lọwọ, ko le kuro ni zone,nitori o maa fẹẹ jẹun, o dẹ niyawo atọmọ nile. Ṣe ẹ wa ri i, ẹ ma jẹ ka da wọn lẹbi funyẹn o, nitori pupọ ninu wọn, OPC lo gbaṣẹ lọwọ wọn.

Nitori gẹgẹ bii alakooso OPC, pe ẹ ko lọ si ipade rara, ẹ maa lọ bii ẹẹmẹrin laarin ọsẹ kan. Ẹ waa sọ fun mi, nigba ti mo ba ni mo da iṣẹ silẹ, tẹ ẹ debi lonii, tẹ ẹ o ba mi, tẹ ẹ debi lọtunla, tẹ ẹ o ba mi. Tẹ ẹ wa sọdọ mi bii ẹẹmẹta laarin ọsẹ kan tẹ ẹ o ba mi, ẹ maa gbeṣẹ yin lọ sibomi-in nao.

Kinni yẹn fa ọwọ aago sẹyin fun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn awọn eleyii nisinyi, mo maa n jẹ ko ye wọn pe, oo le jẹ alakooso zone ko o ma niṣẹ lọwọ, ti o ba niṣẹ lọwọ, o ti fi apẹẹrẹ to daa silẹ fawọn ọmọlẹyin ẹ.

To o ba wa n ṣiṣẹ, tasiko ipade ba to, wa a gbiyanju ibi to o le kọ foonu nọmba ẹ si to o ba lọmọ lọdọ. To ba jẹ pe o lọmọ lọdọ, wa a maa fi foonu ṣọ bi nnkan ṣe n lọ lọdọ wọn, ‘Mo wa nibi iṣẹ o, ta a lo beere mi o?’

 To o ba dẹ n lọ, to ba jẹ pe oo lọmọ lọdọ, kọ foonu nọmba ẹ sibi taaye ba wa, ki wọn pe e sori ẹ, nnkan-ki-nnkan ti wọn ba fẹ, wa a ṣe fun wọn nibi to o wa.

 Gbogbo awọn kinni yẹn lemi fi n kọ wọn, pe OPC ki i ṣe iṣẹ, ẹgbẹ ni OPC. Ẹ jẹ ki onikaluku niṣẹ lọwọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, emi funra mi, lati oogun oju mi,mo ro awọn ọmọ ẹgbẹ mi lagbara nao, OPC ko ṣeru ẹ ri, OPC kankan ko ṣeru ẹ. Mo n sọ ọ gbangba bayii ni, ẹni to ba loun  ṣeru ẹ ri,ko jade wa.

Oogun oju mi ni mo fi ro wọn lagbara bi agbara mi ṣe mọ, ki n le jẹ ko maa ye wọn pe iṣẹ ṣe koko ni, ki wọn le fi eyi ti mo ṣe yẹn gbe iṣẹ wọn soke si i ni, iṣẹ wọn ṣe pataki.

Gbogbo iru yẹn nisinyi naa, a ti n ri i ṣe. Tẹlẹtẹlẹ, ẹnikẹni lo le ṣe alakooso, ko di dandan ko niṣẹ lọwọ, ki n dẹ too gbaayan kan sinu OPC nisinyi, mo fẹẹ mọ iru iṣẹ to n ṣe, ẹlomi-in o niṣẹ, o dẹ n waṣẹ. Ṣugbọn iwọ ti o ko niṣẹ ti o o dẹ tun waṣẹ, o dẹ fẹẹ jẹ eeyan, ki lo fẹẹ fi ṣe e?

 Awọn nnkan ti mo ti ri ṣe ti mo dẹ ti ni ni afojusun ẹ tẹlẹ ni, a dupẹ lọwọ Ọlọrun.

 

Akọsile awọn ọmọ ẹgbẹ lọna imọ ẹrọ n lọ lọwọ

Ti mo ba ni mo mọ iye awọn ti wọn jẹ ọmọ  ẹgbẹ lọwọlọwọ bayii, mo n parọ ni, mi o le sọ pe iye bayii ni wọn. Idi ati itumọ dẹ ni pe a n ṣe akọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ lọna igbalode lọwọ ( Database).

Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, ẹlomi-in le ṣẹṣẹ dara pọ mọ ẹgbẹ, boya l’Ekoo ni o, Ọyọ ni o tabi Ogun, to jẹ pe ko tiẹ ti i ni iwe idanimọ, ṣugbọn o ti fifẹ han lati dara pọ mẹgbẹ, fun idi yii, orukọ ẹ ko ti i ni i wọnu ẹgbẹ.

Lọwọlọwọ bayii, mi o ti i le sọ pe iye bayii ni wa,ṣugbọn nnkan ti mo mọ ni pe a pọ, nnkan ta a ba dẹ fẹẹ ṣe, aa to o ṣe. Ko dẹ sibi kankan nilẹẹ Yoruba, ti wọn maa ni o ya, ọmọ ẹgbẹ OPC Reformed jade ti wọn o ni i jade.

 

Akitiyan n lọ lati mu atunto ba eto aabo si i

 Se ẹ mọ pe ara afojusun wa naa ni eto aabo, emi maa n sọ ọ pe ala mi ti mo n la fun ilẹ Yoruba ni pe ba a ṣe n kọle ta a maa mọ fẹnsi gogoro, ta a maa fi waya ina sori ẹ nitori ole, mi o tiẹ fẹ keeyan maa fẹnsi ile ẹ rara,  tọkan ẹ dẹ maa ba le, ta a dẹ sun, ti ko dẹ ni i tilẹkun ile ẹ to ba fẹẹ lọọ sun, ta a fi mọto ẹ silẹ nita ti ko dẹ ni i tilẹkun ẹ to maa fi lọọ sun, nnkan to wu mi lọkan niyẹn. Iru orilẹ-ede Yoruba to wu mi lọkan pe ka a ni niyẹn, ti ko dẹ n ṣe pe ko ṣee ṣe.

Ṣugbọn owo ni toun o ba si nile, keeyan ma daba kankan. Ka ni ijọba ṣetan lati ṣatilẹyin, ti wọn ba ni o ya, ẹyin eeyan yii, ẹ maa n sọ pe ẹ ṣe igba, ẹ le ṣe awo, ẹ waa gbiyanju ẹ wo, o ya, ẹ ba wa ṣe kinni yii.

 Ki wọn kan tiẹ fi adugbo kan dan an wo, pe ipinlẹ yii o, a fẹẹ gbe e le yin lọwọ fun aabo, ẹ ba wa lọọ ṣe e ka wo bo ṣe maa ri, a fun yin loṣu mẹta.

Iru iyẹ,n bo ṣe wu mi kilẹ Yoruba ri niyẹn. Ara ẹkọ temi maa n fi kọ awọn ọmọ mi niyẹn, mo n jẹ ko ye wọn pe ọlọpaa o ki n ṣe ọta yin o, ọrẹ yin ni ọlọpaa o.

Iṣẹ yoowu tẹ ẹ ba n ṣe, ẹ fi n ran ọlọpaa lọwọ ni. Ọlọpaa gangan lo niṣẹ, wọn dẹ gbọdọ maa mọ riri iṣẹ ta a ba n ṣe, awọn n gba owo fun iṣẹ aabo ni, awa o gba owo, awa n ṣe e lọfẹẹ ni, nitori ifẹ ta a ni siluu wa lawa fi n ṣe eyi ta a n ṣe.

Oun lo fi jẹ pe tawọn ọmọ mi ba mu ole tabi ajininigbe, ti wọn ba ti mu wọn, abi wahala kan ṣẹlẹ laduugbo, ti wọn ba ti ko wọn, wọn maa pe ọlọpaa ko wa ko wọn ni, bi wọn o ba le wa, wọn aa ko wọn lọ si teṣan funra wọn.

Ni gbogbo awọn agbegbe tawọn ọmọ mi dẹ wa, awọn ọlọpaa le jẹrii si i, pe awọn ọmọ OPC Reformed atawọn o, ajọṣepọ to dan mọọnran wa laarin wa.

 

(3) Idanimọ ọmọ ẹgbẹ OPC Reformed han kedere yatọ si tawọn ẹgbẹ yooku

Ọna pọ loriṣiiriṣii ti wọn fi maa da ọmọ ẹgbẹ OPC Reformed mọ. Akọkọ ni pe a ni kaadi idanimọ,ojulowo ọmọ ẹgbẹ gbọdọ ni kaadi idanimọ. A tun wa ni Logo to yatọ si tawọn ẹgbẹ to ku, to jẹ tẹ ẹ ba ti ri Logo yẹn, ẹ maa mọ pe awọn OPC Reformed lo wa nibi yii. Logo wa, o dẹ maa n wa lara gbogbo aṣọ ta a ba wọ.

Yatọ siyẹn,eyi ti mo fẹẹ sọ yii, ko yẹ ki n sọ ọ, ṣugbọn ti mi o ba sọ ọ, ko ni i kun to. Ohun naa ni pe bawọn ọlọpaa ṣe ni yunifọọmu,awa naa ti n ṣeto yunifọọmu kan lọwọlọwọ, to jẹ pe gbogbo ọjọ to ba ti jẹ ọjọ ipade OPC Reformed, aṣọ yẹn ni gbogbo wa maa wọ, ti ko dẹ jọ ti ẹnikẹni, o ti wa nilẹ.  A ni aṣọ yunifọọmu oriṣiiriṣii ninu ẹgbẹ, a ni ti monitoring,ṣugbọn eleyii maa yatọ, debi pe emi funra mi maa ni temi, gbogbo wa pata la maa ni yunifọọmu ti wọn aa maa fi da wa mọ.

4) Ohun to jẹ ki ẹgbẹ okunkun maa gbilẹ si ni pe ṣaṣa ni olu ileeṣẹ ijọba kan ti wọn o ti ni baba nigbẹẹjọ

Ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, o jẹ nnkan to n baayan lọkan jẹ gan-an, iwa ibajẹ yẹn dẹ waa n gbilẹ si i, ṣugbọn ẹẹ wa mọ nnkan to jẹ ki ẹgbẹ yẹn pọ to bẹẹ, oun ni pe ṣaṣa ni olu ileeṣẹ ijọba kan ti wọn o ti ni baba nigbẹjọ .

Ṣe ẹ mọ pe inu ileewe ni wọn ti maa n ṣe ẹgbẹ okunkun, iwọ to o ba lọ sileewe giga bii Yunifasiti, Poli lo le darapọ mọ ẹgbẹ okunkun. Ṣugbọn nigba to de aaye kan, OPC lo jẹ ki ẹgbẹ yẹn pin yẹlẹyẹlẹ bẹẹ yẹn o, tẹ ẹ fi n ri wọn kiri.

Ṣe ẹ mọ, wọn sọ pe tawọn ba ti ṣe nnkan kan, OPC lo maa n koju awọn, ti wọn ki i jẹ kawọn ri nnkan tawọn ba fẹẹ ṣe ṣe.

 Awọn naa wa a wo o pe bawo lawọn ṣe le ṣe e tawọn naa maa fi pọ si i, lo fi wa di pe wọn wa bọ sigboro, wọn waa n ko oriṣiiriṣii awọn ọmọ, ọmọ kafinta, wọn aa gba a sinu ẹgbẹ okunkun, mẹkaniiki, wọn aa gba a sinu ẹgbẹ okunkun, ọmọ to n rin kiri adugbo ti ko niṣẹ, wọn aa gba a sinu ẹgbẹ okunkun, kawọn naa le pọ, o wa di iru wa, ogiri wa, iwa ibajẹ yẹn waa gbilẹ si i.

 To ba wa di pe OPC naa wa ṣiṣẹ takun-takun, ti wọn ba mu ninu wọn, ti wọn ko wọn fawọn ọlọpaa, ẹẹ kan ri i pe ẹni tẹ ẹ ko fọlọpaa fun aṣemaṣe,nigba to ba maa fi di bii ọjọ keji, ọjọ kẹta, o tun ti bọ sigboro pada, o tun ti n rin kiri. La maa wa a wo o pe o tan, a ro pe o maa ku sibẹ ni, ṣe bi oun naa lo tun ti de yii.

Ẹni to huwa ibajẹ, to jẹ iwoyi ọdun kan si isinyi,ko tiẹ yẹ ko ti i bọ sita rara, ẹẹ dẹ ti ri i to tun n yan kaakiri.  Iṣẹ yẹn diidi pọ lọwọ ijọba ni, ọwọ ijọba lo pọ si ju, awa n ṣe iwọn ta a le ṣe, nitori ẹ lo fi jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ki i gbe saara wọn kọjaa mọṣalaaṣi ọdọ tiwa.

Gbogbo nnkan ta a le ṣe lori ẹ la n ṣe, kijọba naa maa ṣe nnkan to yẹ ki wọn ṣe lori ẹ, nitori ti apa kan ba n ṣe, ti apa keji o ṣe, awọn esi to yẹ ki wọn ri lori ẹ, aa o ni i ri i to.

Fun idi eyi, lori aarin yẹn, mo n gba ijọba naa niyanju, agaga awọn ọlọpaa wa naa, ki wọn maa ṣe ootọ to daju lori awọn ọrọ yẹn lati ri i pe iya n jẹ ẹni to ba ṣe aṣemaṣe pẹlu awọn iwa ti wọn n hu.

 

 Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC Reformed ki i ṣe ajagungbalẹ

 Iṣẹ ajagungbalẹ, iṣẹ awọn ẹlomi-in ni, awọn ‘Land Agents’,ilẹ ni wọn maa n ta, ti wọn maa n lọọ ba awọn ọmọ pe ẹbi kan nilẹ to pọ, wọn o dẹ mọ bi wọn ṣe le ta a, wọn o mọ bi wọn ṣe le ṣe e.

 To maa lọ ba awọn abanikọle, abanitalẹ, awọn wọnlẹ-wọnlẹ ( surveyor) sọrọ pe ki wọn ran oun lọwọ, ki wọn ba oun ṣe iru iṣẹ yẹn.

 To ba jẹ iwe tootọ wa, ti awọn ejẹẹnti to gbaṣẹ yẹn dẹ ni sikiọriti, wọn maa n wa sọdọ wa, awa maa n ṣe e, ṣugbọn pe ẹ maa ri ọmọ OPC Reformed kankan nibi ilẹ kan ti ko tọ, ti wọn aa ni wọn lọọ fi ọwọ agbara ṣe kinni kan, abi wọn bọ sori ilẹ kan, wọn lọọ n yinbọn nibẹ, wọn lọọ n paayan kan, rara.

Iru iṣẹ bẹẹ yẹn, ti awa ba fẹẹ ṣe e, ọlọpaa gbọdọ mọ si i, yatọ si pe awọn iwe ẹ pe, ọlọpaa maa mọ si i pe ibi bayii o, awọn OPC n lọ sibẹ, awọn iwe ti wọn dẹ ko wa ree. Gbogbo awọn to dẹ kan lo maa jokoo, wọn aa ṣe ipade, ọlọpaa maa mọ nipa ẹ, wọn aa dẹ gba sikiọriti, wọn aa ko awọn ọmọ lọ sibẹ, wọn aa ṣe e.

Ṣugbọn yatọ siyẹn, rara o, awa ki i faramọ ọn, pe keeyan kan lọọ maa ja lori ilẹ onilẹ lọna aitọ, to o mọ bo ṣe jẹ, wọn ni ko o ko ibọn wa, o lọọ n ko ibọn lọ, a o ki i ṣeru ẹ.

OPC Reformed gan-an, ao ki n gba gbogbo iru nnkan bẹẹ yẹn laye, nitori orukọ ta a n jẹ yẹn, a maa n fẹ ko ro wa ni gbogbo igba, ohunkohun ta a ba dẹ n ṣe, a maa wo orukọ yẹn.

Reformed la pe kinni yii, nnkan to maa tun waa da wa pada soko aarọ, ẹ ma jẹ ka ṣe e o. Lori aarin yẹn, gbogbo iyẹn la maa n mojuto lati ri i pe awọn ọmọ wa ko ṣe bẹẹ.

Ta a ba dẹ ri ọmọkọmọ abi ẹnikẹni to ba ṣeru kinni yẹn, tẹ ẹ ba mu un wa sọdọ wa, a maa da si i, a dẹ maa ṣe nnkan to yẹ ka a ṣe lati ri i pe wọn o gbe ẹbi fun alare, wọn o gbe are fun ẹlẹbi, awọn to ni nnkan wọn loootọ ati lododo,wọn aa gba nnkan wọn pada. Ba a ṣe maa n ṣe e niyẹn.

 

Aisowo lo n fa wa sẹyin, awa OPC Reformed  maa n lọ kaakiri ile akọku lati mu awọn oniṣẹ ibi

Ṣe ẹ mọ pe mo sọ ọ nibẹrẹ pe ororo ara wa la fi n yan ara wa, gbogbo nnkan ta a n ṣe niluu wa yii, ko si eyi ti ko ni i ṣe pẹlu owo. Ẹni to ba fẹe rin awọn irin ta a n rin yẹn, a maa ni lati lo ọkada, a maa gbe mọto lati rin awọn irin yẹn, a dẹ maa ra epo, a ṣi n ṣe e, ṣugbọn ko da bii ti tẹlẹ mọ, inawo yẹn pọ, ko dẹ si oluranlọwọ kankan.

Erongba wa ni pe adugbo wa, ko wa lalaafia, a dẹ mọ pe awọn ile akọku lawọn ọmo janduku, awọn ọmọọta maa n sa pamọ si, to ba doru ni wọn maa jade ti wọn maa lọ ṣiṣẹ ibi, iyẹn la ṣe maa n wọbẹ.

Igba ti wọn o lero la maa n wọbẹ, a n wọbẹ loru nigba mi-in. Igba mi-in, ọsan ni wọn maa lọ sun sibẹ, aa ka wọn mọbẹ.

Igba mi-in, idaji la maa ka wọn mọ, aa wọbẹ nidaji, boya bi wọn ṣe n de, a maa fun wọn lakamọ mọbẹ, aa dẹ ko wọn, o di agọ ọlọpaa. Ṣugbọn gbogbo awọn irin yẹn, o nawa lowo, o na wa lara, a fi ara wa silẹ latiṣe e, ṣugbọn owo yẹn nkọ, ko si iranlọwọ, ko si atilẹyin.

Iyẹn lo fi da bii pe boya o lọ silẹ diẹ, ṣugbọn ki i ṣe pe o lọ silẹ patapata, ta a ba tun ri iranlọwọ, ẹẹ tun maa gburoo ẹ bẹ ẹ ṣe n gbọ ọ yẹn naa ni, ṣugbọn a ko duro ṣaa lori ọrọ aabo yii.

Iyẹn la ṣe maa n sọ fawọn ara adugbo naa, pe awa ta a jẹ OPC, eeyan ni wa, a o ki n ṣe alujọnnu, awọn nnkan ta a ba gbọ nigba mi-in naa la maaa ṣiṣẹ le lori.

Tẹ ẹ ba ri nnkan kan, ẹ sọ ọ sita, nitori ẹ la ṣe maa n ni OPC zone kaakiri, a maa n jẹ ko wa nitosi. To o ba ti gbọ nnkan kan, tete lọ si eyi to sunmọ ọdọ ẹ, to o ba de Zone wa, wa a ri banner nibẹ (Eyi n kede ẹgbẹ ni) wa a ri nọmba mi nibẹ.

To o ba pe nọmba yẹn, ibikibi ti nnkan ba ti n ṣẹlẹ, bi mo wa l’Amẹrika, London tabi ibikibi laye yii, to o ba pe mi, mo le ko awọn to maa lọ sibẹ jọ lati lọọ ṣiṣẹ yẹn.

 Nọmba yẹn o dẹ ki n ku, ibikibi ti nọmba yẹn wa, temi ni.

No comments:

Post a Comment

Adbox