IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday 4 October 2023

Agba-oje Olorin Fuji, Ishola Sandoka, di Baale nipinle Ogun



Iroyin ayo to te wa lowo bayii nipe agba-oje Olorin Fuji nni, Alhaji Ishola Fatai Olawale Sandoka topo awon eeyan mo si Yoboroyoboson ti di baale niluu Adelegun Isamuro, niluu Ago-Iwoye, nipinle Ogun.


Gege bi a se gbo, Ebumawe ilu Ago-Iwoye,  Alayeluwa Oba Abdulraheem Adesina Adenugba pelu awon afobaje ni won fowosi yiyan Sandoka gege bi Baale tuntun.

Ojo ketalelogun osu kokanla odun yii layeye iwuye yoo waye laafin Ebumawe. Nigbati iweje-wemu yoo waye lojule ketalelogun opona Obaruwa, Isamuro, Ago-Iwoye nipinle Ogun

Awon eeyan Pataki lawujo ni won reti nibi ayeye iwuye naa.

No comments:

Post a Comment

Adbox