IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday 18 June 2023

Idi ti ayeye 'Asa Day' todun yii yoo se waye niluu Abuja ree- Oloye Joel Oyatoye Olaniyi Baba Asa

Laipe yii ni okan gboogi ninu awon kaaro-oojire, Oloye Joel Oyatoye Olaniyi gba awon akoroyin lede Yoruba, iyen ' League of Yoruba media practitioners lalejo, eyi to waye nile egbe awon oniroyin eka ti ipinle Eko to wa ni Ikeja.

Lasiko iforowero pelu omooba  naa to tun je aare ati oludasile ayeye Asa Day Incorporation lorileede Canada ti gba awon omo egbe naa niyanju lati ri i pe won gbe e de ibi to lapeere ko le je itewogba fun tolori-telemu


Baba Asa ko sa i menuba awon ohun to je ki Ina asa jo ajoreyin

“Tijọba ba ya minisiri aṣa sọtọ, ti wọn fi awọn eeyan ti wọn mọ nipa ẹ ti wọn ko si tori owo ṣe e sibẹ, wọn yoo ri i pe idagbasoke ọrọ aje yoo waye kia ju bi wọn ṣe n pin ‘Culture mọ Information’ lọ. Dandan kọ ni ki minista wa lọtọ fun Culture, wọn le yan alaboojuto aṣa nikan fun un bi wọn ba yan minista iroyin tan, ki wọn waa wo o boya eeyan aa maa jẹ ọba kiya jẹ ẹ, boya awọn on-nilẹ ko ni i maa gbọ bukaata ju tiṣaaju lọ’’

Bẹẹ ni Oloye Joel Ọlaniyi Ọyatoye (Baba Aṣa) wi.

Lasiko yii to si waa jẹ pe aarẹ Yoruba lo wa lori aleefa ni Naijiria, Baba Aṣa ṣalaye pe igbagbọ wa pe iyatọ yoo wa ninu bawọn eeyan wa ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu aṣa, eyi naa lo si fa a to fi jẹ pe ayẹyẹ Aṣa Day tọdun yii yoo waye niluu Abuja ti i ṣe olu-olu Naijiria, ko le baa ṣoju Aarẹ Bọla Tinubu gan-an.

Ki iyatọ si le wa si tawọn ijọba atijọ ti wọn ki i ṣe elede wa. Ipari oṣu kẹsan-an ni ti United Kingdom, yoo waye ni Canada pẹlu ki wọn too pada wale s’Abuja lati ṣe tiwa bi Baba Aṣa ṣe sọ.

No comments:

Post a Comment

Adbox