IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday 27 June 2023

Abosi ni Aarẹ Tinubu se lori ‘subsidy’ to yọ - Ṣẹgun Ṣowunmi



Agbẹnusọ fun oludije s’ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, iyẹn Ọtunba Ṣẹgun Ṣhowunmi ti sọ pe ko si alabosi to to ijọba APC, paapaa Aarẹ Bọla Tinubu Tinubu lori awọn igbesẹ to n gbe latigba to ti de ori aleefa.

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi lo sọrọ yii lasiko to n ba ẹgbẹ akọroyin Yoruba ti a mọ si League of Yoruba Media Practitioners, LYMP, sọrọ nibi ifọrọwerọ to waye lori ayelujara lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ṣẹgun Ṣowunmi nigba to n dahun ibeere nipa awọn igbesẹ ti Aarẹ Tinubu n gbe, paapaa lori owo iranwọ ori epo rọbii, iyẹn ‘subsidy’ ti wọn yọ ati awọn ọga ologun ti wọn yọ danu.

Agba oloṣelu naa nipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ ṣalaye pe latigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti n polongo ni wọn ti n sọ tipẹ pe awọn yoo yọ owo iranwọ ori epo rọbii naa danu, nitori ko mu ilọsiwaju kankan ba Naijiria.

O ni Aarẹ Tinubu mọ pe nnkan ti ko dara ni, ṣugbọn ti ko sọrọ lori ẹ nigba to gbe Aarẹ ana, Muhammadu Buhari wọle gẹgẹ bi aarẹ Naijiria, ati pe ko tun gba a lamọran lati ṣe awọn ohun to yẹ.

O ni ẹtanjẹ ni Tunubu n ṣe fun Buhari f’ọdun mẹjọ, nitori pe ko gba a lamọran to dara, o kan kawọ gbera lati fi ri anfaani araalu gba lasan ni.

Ninu ọrọ rẹ, Ṣhowunmi sọ pe: “Yoruba  ni gbobo wa, otitọ ọrọ naa bo ṣe ri lookan aya mi ni mo maa sọ ọ fun un yin. Mo i tii ba alabosi to to ijọba APC ti awọn Bọla Ahmẹd Tinubu n ṣe yii ṣe ri laye. Maa sọ idi pataki rẹ, ijọba to wa nibẹ fun ọdun mẹjọ, ijọba APC ni. Aarẹ to wa nibẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti APC ni.

“Aṣaaju ẹgbẹ ni wọn n pe Aṣiwaju Bọla Tinubu nigba yẹn. Buhari lo dara julọ loju wọn nigba yẹn, Buhari nikan lo mọ ọn ṣe julọ nigba yẹn loju wọn. Kii ṣe pe ijọba yẹn bọ sọwọ alatako nigba yẹn, ọdọ ẹyin APC naa lo bọ si, ti ẹ si jọ n ṣe e pọ.

“O ṣe wa a jẹ pe laarọ ọjọ keji, gbogbo nnkan ti Buhari n ṣe ni ko dara mọ loju yin. To ba jẹ pe lotitọ ni ẹ mọ pe kini yẹn ko dara, ki lo de ti ẹ ba wọn ṣe fun ọdun mẹjọ, ti ẹ ko sọrọ, ti ẹ ko le gba wọn lamọran lori ọna to tọ. Ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti n pariwo tipẹ wi pe ki a yọ owo ori iranwọ epo kuro tipẹ.

“Gbogbo igba ti Buhari wa nibẹ, niṣe ni wọn n sọ pe awọn ko mọ sii, ko si nnkan to n jẹ bẹẹ, nigba ti wọn mọ lọkan ara wọn pe nnkan ti ko dara ni owo ori iranwọ epo jẹ.

“Bi ẹni to kan n tan awọn ilu jẹ ni, ki lo de to jẹ pe ọjọ keji ti wọn debẹ ni wọn yọ owo naa kuro. O yẹ ki ẹ mọ pe ẹtanjẹ ni.

“Ni ti awọn ọga ologun ti wọn tun yọ danu, ṣe ka sọ awọn ologun naa ti di oloṣelu ni bayii, to fi jẹ pe latigba ti a ti bẹrẹ eto iṣẹjọba awaarawa lọdun 1999 ni wọn ko tii ṣe ohun to dara loju ijọba.

“Ṣe dandan ni ko jẹ pe ọjọ ti wọn ba ti yan aarẹ tuntun naa ni wọn maa le ologun to wa lori ipo tẹlẹ lọ ni tipatipa? Ti ẹ maa sọ pe ki ẹni to ni ọjọ ati akoko ifẹyinti maa lọ ni tipatipa. Ṣe ologun yẹn ko le gba aṣẹ lẹnu aarẹ tuntun ni, ṣe gbogbo wọn pata ni wọn gbọdọ lọ lẹẹkan-naa ni? A n tan ara wa jẹ ni

“Ẹ fẹẹ yọ owo lori epo rọbii kuro, ohun mẹta to jẹ koko lo yẹ ki wọn kọkọ ṣe. Akọkọ ni pe, mo lero wi pe owo ti mo fẹẹ gbe kuro lori awọn mẹkunnu yii, ibo ni wọn fẹẹ gba fun wọn pada. Ẹẹkeji ni pe, mo lero wi pe gbogbo awọn to ṣokunfa irin ajo owo iranwọ ori epo yii, ki wọn fọwọ ṣinkun ofin mu wọn.

“Wọn ko ri ẹnikẹni mu lati fi jofin gbogbo gbese ti wọn ko araalu si. Mi o ro pe wọn mọ iye idile ti wọn ko nii lagbara lati bọ ọmọ wọn mọ. Talo maa fun mẹkunnu ni owo iranwọ lati rọpo owo oṣu t’awọn oṣiṣẹ n gba.

“Awa kọ la sọ pe ki wọn maa jale owo ori iranwọ epo, awa kọ la sọ pe ki wọn maa ṣe fayawo, awa kọ la ko Naijiria s’oko gbese, iṣẹ ijọba ni lati mu gbogbo awọn ti wọn da wahala silẹ faraalu, ṣugbọn ṣe ni wọn tun gbe bukata naa le araalu lori.

“O tun ya, wọn sọ pe wọn maa fowo kun owo ina, ki lo le to bẹẹ. A ko sọ pe ki Bọla Tinubu ma ṣe daadaa lori aleefa, a ko sọ pe kii ṣe ọmọ kaarọ-o-jiire-bi. Ohun ti a n beere ni pe, ṣe Yoruba maa wa di pe igba ti ọmọ wa ti de ori aleefa bayii, ko si otitọ mọ ninu ati lẹnu wa.

“To ba jẹ nnkan ti ẹ fẹ ka fi jẹ Yoruba niyẹn, mo jẹ Yoruba ju wọn lọ. Ki ẹnikan ma sọ pe oun fẹran Yoruba ju iru awa lọ, ṣugbọn a ko nii fẹran Yoruba debi wi pe a ma maa fọwọ pa ọmọ wa lori.

“Ẹni to ba fẹ ki ọmọ rẹ ṣe daadaa nileewe, ko nii fi ọwọ to rọ mu, gbogbo igba lo ma maa ba a wi. Beeyan ba ba ọmọ rẹ jẹ, yoo ba nilẹ bẹẹ. Mi o tii binu sii debi wi pe o ti ni agbekalẹ kan pato ti a ko ri iru ẹ ri. Ohun ti mo n beere ni pe ṣe APC asiko yii naa ni APC alatako ijọba ọdun mẹjọ to kọja ni, nitori pe ki ni wọn n wo lati ọjọ yii?

“Lẹyin ọgọrun ọjọ lori ipo, a maa ri awọn nnkan ti wọn ti ṣe. Ti iyan ba mu, ti ebi ba si pa gbogbo ilu tan, boya wọn a maa ṣe ijọba lori oun ati mọlẹbi rẹ.”

No comments:

Post a Comment

Adbox