IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday 2 July 2023

Atiku ati Obi ko setan lati di aare, Olorun nikan lo gbajoba lowo Tinubu - Primate Ayodele

 

Primate Elijah Ayọdele, to jẹ oludasilẹ ijọ ‘INRI Evangelical Spiritual Church’, ti sọ pe ki awọn ọmọ orileede yii fọkanbalẹ nitori Aarẹ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni erongba rere fun wọn, eyi ti yoo jẹ ki akoko ẹ da ju ti aarẹ tẹlẹ, iyẹn Mohammadu Buhari lọ, ṣugbọn ki o sọra gidigidi ki wọn le ba jẹ ko ri ijọba ọhun lo bo ṣe n fẹ.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lasiko to n ṣafihan iwe asọtẹlẹ rẹ to pe ni ‘Warning to the nation’, o sọ pe bi Tinubu ṣe n ṣe lọ yii, irọrun pada bọ wa si orileede yii, amọ awọn kan yoo fẹẹ dide lati maa tako, iyẹn to ba fẹẹ maa wọdii awọn oniwa ibajẹ lakooko Buhari.

Bakan naa lo tun kilọ fun Alaaji Atiku Abubakar, oludije aarẹ fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party  ati Peter Obi, toun jade labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour lati ma ṣe ro abajade rere kan ninu ẹjọ ti wọn pe lori ibo aarẹ to kọja.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni gbogbo awọn lọya ati adajọ ti wọn n gbẹjọ ọhun ni yoo ko sinu igba, ti yoo si sọnu. O sọ pe Emi lo kan ti Tinubu n pe lakooko ipolongo ki i ṣoju lasan, o ni aṣẹ nla kan ninu, eyi to jẹ ki o ja si rere fun un.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa tun fi kun ọrọ ẹ pe bigba ti eeyan fi akoko sofo loun ri awọn mejeeji ti wọn lawọn fẹẹ le Tinubu kuro lori oye. O ni aṣeyọri Tinubu kọja oye ẹda, nitori aṣẹ emi lo kan yẹn ki i sọrọ ẹnu lasan

O ni, “Atiku ati Obi ko ti i ṣetan rara lati di , ṣe wọn ro pe Tinubu yoo kan jokoo lasan ti yoo si kawọ gbera?, Gbogbo awọn agbẹjọro ati adajọ ni yoo ko sinu igba kan, ti yoo si ju da Atiku ati Obi danu bii   omi isanwọ.

“Tinubu ki i sẹni ti wọn le foju bintin wo, Ọlọrun nikan lo le mu  u kuro. Atiku ati Obi nnkan fi akoko wọn ṣofo, wọn ko ti i ṣetan lati di aarẹ orileede yii.

 

Ojiṣẹ  Ọlọrun naa sọ pe ariwo ori ẹrọ ayelujara lasan lawọn yẹn pa, ṣe wọn ro pe ibẹ ni wọn yoo ti ṣaṣeyọri ni. Bakan naa lo sọ pe lati ọdun1994, lawọn ti bẹrẹ eto ti Ọlọrun si ran awọn lọwọ, bẹẹ lo ni ọpọ awọn eeyan niṣẹ iranṣẹ naa ti ran lọwọ nipa ironilagbara.

Lori ibeere pe ki lo de tawọn eeyan ki i fi ri iyawo atawọn ọmọ pẹlu ẹ gẹgẹ bi oludasilẹ ijọ, Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ pe oun ni Ọlọrun pe ki i ṣe awọn ẹbi oun, oun ko si ri ara oun bii olori ijọ bi ko ṣe iransẹ Ọlọrun. Iṣẹ onikaluku si yatọ si ara wọn, ti ọkan ko si di ikeji lọwọ.

 

 

No comments:

Post a Comment

Adbox