IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 13 April 2023

Aralola Oga Awon obinrin to n lulu seto nla fawon omoota lEkoo




Obinrin akoko to koko sopa si ilu gangan nile adulawo Afirika, Serifat Olamuyiwa ti awon eeyan ilu ati awon ololufe re mo si Ara to ti di gbajumo lagbaye nidii ilu lilu, to tun gbe eto “Eko Inspire me” kale, eto to wa fun titun aye awon oba igboro ti awon eeyan n pe ni “Omo ita” l’Ekoo se ni o se abewo si awon oba igboro naa to wa l’Osodi.

Ojo Ojoru Weside ose yii ni gbajugbaja Obinrin Ayangalu lagbaye nni, iyen Serifat Olamuyiwa tawon eeyan mo si Ara se abewo si awon oba igboro ti awon eeyan olugbe ilu Eko maa n pe ni omo ita, to si bawon soro omoluwabi leyin opo ere lorisirisi nipa idije, jije-mimu pelu orin ati ijo ti won fi da ara won lara nibi eto naa.

Gege bi erongba rere ti arabinrin Onilu naa ni fun awon omo oba igboro yen, Ara je ki a mo pe opo ninu awon omo ti awon eeyan awujo n wo gege bi omo buruku tabi omo ita ni ko wu ko ma gbe iru igbe aye ti won n gbe naa, o ni awon omo ita naa ba ara won ni ipo ti won wa yii nitori airi oluranlowo tabi alatileyin to le fawon lowo soke, ere idi toun fi gbe eto to pe akole re ni “Eko Inspire me” kale ree fun awon omo ita ilu Eko yii, ki erongba rere nnkan ti won fee da laye le wa si imuse funwon.

Lasiko abewo Ara si awon oba igboro Osodi naa, orisirisi idije lo waye bii ayo boolu eleyin ori tabili ti awon eleyibo n pe ni (Table Tennis), idije eni to mo ijo jo julo (Best Dancer), Orin kiko (Best performing artist) Olorin-aforokan-ma-pe-meji (Best Rapper) ati bee bee lo, ti awon to jawe olubori si gba ebun bamta-bamba lo sile onikaluku won. 

Lara awon olukopa ni, tabu teniisi ti awon odo langba ni Habeeb Amutairu, Amoo Waheed, Abdulramon Lasisi, Kazeem Ibrahim, Kehinde Wahab, Seun Diamond, Yesuf Tunase Ayoola, Akinola Azeez, Tijani Fawaz, Waheed Wariz, Kazeem Qudus, Wahab Taiwo, Opeyemi Muiz, ati Habeeb Adegbenro. 

Awon agbalagba to kopa ni idije tabu teniisi ni Adedigba Hakeem, Lekan Oni, Sodiq Kasali, Ishola Lukman ati Seun Fabunmi.

Awon oludije ni ipele orin kiko, ijo jijo at orin-aforokan-ma-pe-meji ni Emmmenuel Bamigboye, Nurudeen Tajudeen, Adegboyega Damilare, Odeyemi Gbolahan ati bee bee lo. 

Ara si tun beere lowo awon oba igboro naa ohun ti won n fe, ti opo ninu won si so ero okan won fun un bii wi pe, awon fee pada sile iwe, ti opo si lawon n fe irinse owo ti won ko. Ara seleri wi pe, oun yoo lo eto “Eko Inspire me” fi ran awon to fee pada sile iwe pada, ti awon yoo si tun ra irinse fun awon to fe irinse owo won. 

Awon eeyan pataki lawujo naa lo wa ni ijokoo lati ye Ara si lojo naa. Inu gbongan nla ibudoko Taminal 3 to wa niluu Osodi l’Ekoo ni eto abewo si awon oba igboro naa ti waye. 

Ara si fi dawa loju wi pe, bi eto naa yoo se maa waye niyen kiri origun mereerin ipinle Eko lati le mo ohun ti awon le se ati ona ti awon le gba lati ran awon oba igboro naa lowo, ti aye won yoo fi pada ni itumo bi awon gan-an funra won se n fe.

No comments:

Post a Comment

Adbox