IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 4 August 2022

Emi nifa mu gege bi Aboro ti Ibeshe, won fee fowo ola gba mi loju ni---Omooba Alexander Adegbemiro Idowu


 
Leyin ti ijoba ipinle Ogun ti gbe opa ase fun omooba Mulero gege bi Aboro ilu. ibeshe, nitosi ilu Ilaro, Omooba Alexander Adegbemiro Idowu ti so pe ona eburu gba a ni won gba lati so pe Mulero ni ipo naa to si.

Lasiko ti Omooba Alexander Adegbemiro Idowu n ba wa soro, o ni oun ga- an ni ifa mu, sugbon tawon afobaje gbe ipo naa fun Ogbeni Mulero to je omo obinrin nidile Idowu.

Omooba Idowu ni saaju kawon afobaje too so pe Mulero nipo naa to si ni okan ninu awon ti pe oun, to so pe  awon afobaje ti loo wadii lowo ifa lati mo eni ti ipo to si, ti ifa si so pe oun Alexander ni ifa mu un, sugbon eni yii so foun pe ko ma je ki enikeni mo. Omooba yii fi kun oro e pe leyin e ni enikan tun pe oun lati ijoba ibile pe koun yoju si won. 

Baba yii so pe kayeefi nla lo je foun bi won se yi oro naa biri, ti won si kede eni ti ki I se ojulowo omooba gege bi oba tuntun

Bakan naa la gbo pe nitori owo wa lowo Ogbeni Mulero ni won se yan an,ti awon oba alade to wa ni agbegbe naa ko si ri ohunkohun se si i

Ni bayii, Omooba Alexander Adegbemiro Idowu ti ke si ijoba Ipinle Ogun labe isakoso Ogbeni Dapo Abiodun lati da si Iro naa ki awon borokini to fi owo ola gba oun loju,bee lo dupe lowo Alake ti Ile Egba fun aduroti re.

Sa o ,Oro naa si wa ni kootu ,ti ko si leto lati dade fun enikeni gege bii Aboro ilu Ibeshe sugbon ti Mulero ti gba Ade nigbati oro si wa nile ejo.

No comments:

Post a Comment

Adbox