Okan pataki ninu awon olorin emi ti won n fi ebun ti Olorun fun won gbe oruko orile-ede yii ga loke-okun ni Ajiyinrere Oludamilola Olori Jesu. Orile-ede Amerika lobinrin naa ti n gbe ogo ile yii ka.
Lasiko to n ba wa soro ni obinrin yii ti so pe latigba ti oun ti wa lomo odun merin loun ti n korin ninu ijo baba oun, koun too dipe oun gba orile-ede Amerika ti oun wa yii lo toun si mu ise orin ni koko.
Rekoodu akoko ti oun ati egbon jo se ni won pe oruko re no 'Arena of rival'. Awo naa so won di llu mo on ka laarin awon egbe won.
Bakan naa ni obinrin yii salaye fun wa pe agba-oje olorin emi nni, Mama Bola Aare lawokose oun nidi ise orin ti oun yan laayo. O ni lati aadota odun seyin ni Mama Bola Aare ti n fi orin jeere okan, bee ni won ko kuro nidii ise Olorun ti won gbe dani yii.
Bee lo fi kun oro e pe rekoodu oun kan n bo lona ti yoo jade ninu osu kejila odun ti a wa yii.
O wa a ro awon ololufe lati tewo gba rekoodu naa to ba ti jade.
No comments:
Post a Comment