
Rodiyat to n gbe ni Dublin salaye fun wa pe 'Mo wa si Naijiria lati Dublin ti mo n gbe lodun naa lohun-un fun ipolowo rekoodu mi ti mo se jade nigba naa ti mo pe akole re ni 'Hello Olohun'. Obinrin sorososoro kan ti oruko re n je Labisi Ayaba ni mo waa ba lojo naa pe ko maa ba mi lo rekoodu mi naa lori radio.Nibi ti emi ati e ti n soro lo ti nawo si Ididowo pe manija Pasuma niyen, o ni o le ran mi lowo lati se rekoodu papo pelu Pasuma ati awon irawo olorin mi-in. Mo ba won soro lojo naa,won si je ki n mo pe awon n bo wa si Dublin pelu Pasuma ni osu mefa si asiko ti a wa naa.
Lojo naa ni mo ro o lokan ara mi pe mo ma san oore ti won se fun lati se awo po pelu Alaaji Pasuma la n san kobo. Mo se itoju won daadaa nigba ti won de Dublin, itoju won ti mo se yii lo dun mo Ididowo ninu ni won ba so pe awon yoo fe mi, sugbon mo je ko ye won pe mi o le fe kristeni,won lawon yoo di musulumi, mo si so fun won pe ki won koko loo di musulumi naa ki won ma tori mi fi esin won sile. Lojuese ni won pe aafaa,ti won se gbogbo ohun ti won gbodo se fun eni to ba fee di musulumi fun won,ti won fun won ni suna Abdulateeef. Latigba naa ni won ti di musulumi.

No comments:
Post a Comment