IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 17 July 2025

Buhari lo fun Arẹgbẹṣọla nipo mìnìsita, ki i ṣe Tinubu- Amugbalẹgbẹ



Aṣiiri  ti  suyọ bayii pe Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, to tun figba kan jẹ minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹní Rauf Arẹgbẹṣọla ki i ọmọọsẹ 
Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu nidii oṣelu, bi
ko ṣe alabaṣiṣẹpọ
 
Bakan naa la gbọ pe  lati bii ọdun meloo kan sẹyin ti aarin Ọgbẹni Arẹgbẹsọla ati Aarẹ ti daru, gbogbo ọna  ni wọn ni Gomina tẹlẹ ọhun fa lati jẹ ki alaafia waye, amọ tawọn arijẹ ninu madaru tunbọ bu epo si i.


Ko si pẹ laipẹ yii ti ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun fi kede pe awọn yọ Ọgbẹni danu lẹgbẹ APC, ti wọn ni awọn ko ba a ṣe mọ.


Nitori igbagbọ tawọn aṣaaju oloṣelu ninu ẹgbẹ PDP ati APC ni ninu Arẹgbẹṣọla lo mu ki Abubakar Atiku atawọn kan lọọ ṣe ipade pọ pẹlu Minisita tẹlẹ naa lati wa ọna abayọ si bi atunṣe yoo ṣe de ba oṣelu orileede yii.


Ko si pẹ ti wọn fi pamọpọ lati darapọ mọ ẹgbẹ ADC, nibi ti David Mark ti jẹ alaga wọn, nigba ti wọn si fi Arẹgbẹṣọla jẹ akọwe, tawọn mejeeji si jọ n dele lọwọ.


Lojuẹsẹ ni Arẹgbẹṣọla ti bẹrẹ iṣẹ, to si n ṣe ifikunlukun kaakiri, amọ sibẹ, ibajẹ ẹ lawọn ọta ẹ nidii oṣelu n wa, amọ to kọ ipakọ si wọn, ti ko ri ti wọn ro.


Ni bayii, ọkan lara awọn to sunmọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti tan imọlẹ sawọn ahesọ tawọn kan maa n sọ nipa Gomina Ọṣun tẹlẹ naa.


Gẹgẹ bo ṣe wi, 'O ni lọdun 2018, nigba ti Arẹgbẹṣọla fipo gomina silẹ, o lọọ ba Aṣiwaju nile ẹ pe oun fẹẹ rin irinajo lọ si Amẹrika, wọn le fẹẹ yẹ 'CV,' oun wo pe ki wọn gba.


Onitọhun tun ṣalaye siwaju pe ohun ti Tinubu sọ  nipe "Kin    in ni mo fẹẹ fi ṣe, a nilo ẹ mọ, a ti lo ẹ, bi a ṣe fẹẹ lo ẹ'


O ni ilu oyinbo ni ọga oun wa, to fi ri orukọ ẹ ninu iwe iroyin ti Buhari fun un nipo minisita, o ni oun fi tan imọlẹ fawọn eeyan pe Oloogbe Buhari lo fun Arẹgbẹṣọla nipo naa ki i ṣe Tinubu.


Bakan naa ni ẹní  tun ṣalaye siwaju si i  pe Arẹgbẹṣọla ki i ṣe ọmọọdọ tabi ọmọleewe ti Tinubu kọ ni oṣelu, alabaṣiṣẹpọ ẹ ni.


O ni ẹni to ṣiṣẹ ọpọlọ to jẹ ki Tinubu ṣe aṣeyọri laarin ọdun 1999 si 2007, o ni Arẹgbẹsọla ni, nipa awọn iṣẹ idagbasoke atawọn imayedẹrun.



 

No comments:

Post a Comment

Adbox