IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 27 August 2025

Yoruba lo yẹ ko jẹ aṣaaju nipa fila ati gele lagbaaye- Alake tilẹ Ẹgba


Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, ti ṣapejuwe Yoruba gẹgẹ bii aṣiwaju laarin awọn ẹya gbogbo kaakiri agbaye, paapaa, ti a ba n sọ nipa aṣa fila dide ati gele wiwe.

O ni bi ajọ to n moju to eto ẹkọ , iwadii ijinlẹ, ati ọrọ aṣa lagbaaye, ìyẹn United Nations Educational, Scientific and Cultural Organization (UNESCO), ba maa da ọjọ kan ya sọtọ fun ayajọ fila ati gele pẹlu gbogbo nnkan ti iran ọmọniyan lorilẹ aye fi n ṣe ọṣọ sọrọ lagbaaye, Yoruba lo tọ si lati jẹ olupilẹṣẹ iru igbesẹ bẹẹ nitori ọkẹ aimọye ara lẹya Yoruba n fi fila, gele ati ade ori awọn ọba da.

Alake Ilẹ Ẹgba sọrọ yii lỌjọ Wẹsidee, ọsẹ yii lasiko to gbalejo awọn aṣoju igbimọ alaṣẹ ajọ to n gbe aṣa Yoruba ga kaakiri agbaye, iyẹn Ọmọ Yoruba Atata Socio-cultural Initiative, ỌYÀSI.

Ọba Gbadebọ, ẹni ti ko si ni Naijiria lọwọlọwọ bayii, ṣugbọn ti ọkan pataki ninu awọn ijoye rẹ, Oloye, (Onimọ-ẹrọ) Olusọji Ṣodamọla, ṣoju fun, sọ pe ayajọ Fila ati Gele Agbaye, ti ajọ ỌYÀSI gbe dani yii wu awọn  (igbimọ Alake Ilẹ Ẹgba) lori nitori eto to gbe aṣa Yoruba ga lawujọ agbaye ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ti iru yin bayii ko ba dide ni, aṣa wa iba kan maa parẹ lọ ni. Ti a ko ba si kọ awọn ọmọ wa lati kekere, aṣa mi-in ni wọn maa gba. Awa ti a si jẹ obi naa, a ko kọ ibi ara sI i. A gbọdọ maa sọ ede wa, ka maa fi i yangan, iyẹn lo maa jẹ ki wọn mọ ibi ti a ti wa níbikíbi ti a ba wa laye."

O tẹsiwaju pe "a gbọ nipa eto ayajọ Fila ati Gele Agbaye ti ẹ ṣe n'Ibadan lọdun to kọja. A si nigbagbọ pe ti ọdun yii tun maa dun ju bẹẹ lọ. 

"Ti ajọ agbaye ti wọn n pe ni UNESCO ba maa ya ọjọ kan sọtọ gẹgẹ bii Ayajọ Ọṣọ Ori Lagbaaye, lati ọdọ awa Yoruba naa lo yẹ ko ti wa nitori awa la ni fila ti a fi n da oriṣiiriṣii ara, awa la tun ni gele alaranbara pẹlu awọn to n fi gele wiwe ṣe iṣẹ aje lode ariya.

Gbogbo alaye ti ẹ ṣe yii lo dara pupọ, nigba ti Kabiesi ba de, a maa jiṣe fun wọn, a si nigbagbọ pe inu wọn maa dun lati ṣatilẹyin fun yin nitori pe ẹni to mu aṣa ati iṣe Yoruba ni pataki ni Kabiyesi jẹ.

Nigba ti wọn n sọ nipa idi ti wọn ṣe ṣabẹwo naa, alaga ajọ ỌYÀSI, Ọgbẹni Ọlawale Ajao, pẹlu Ọgbẹni Adeyẹmi Olorire, ti i ṣe akapo ajọ naa, ti sọ pe awọn wa si aafin Alake lati gba iwure ori ade ati lati beere fun atilẹyin olori awọn ọba ipinlẹ  Ogun naa ni igbaradi fun ayajọ Ọsọ Ori ẹlẹẹkeji Irun ẹ, eyi ti yoo waye n'Ibadan lọjọ  kejidinlọgbọn (28), oṣu Kejila, ọdun 2025 yii.

Igbimọ Alake Ilẹ Ẹgba lo gba wọn lalejo.
Lara awọn to pẹlu Oloye Ṣodamọla lati gbalejo awọn eeyan naa lorukọ Ọba Gbadebọ ni Oloye (Dokita) Fatai Badru, ti i ṣe Jaguna Ijẹun; Oloye Taofeeq Aarẹ (Ọtun Iporo); ati Oloye Yẹkini Ṣomade (Oluwo Ẹkun), ti gbogbo wọn jẹ agba ijoye ilẹ Ẹgba.

Wọn ṣeleri pe awọn yoo jabọ abẹwo naa fun Ọba Gbadebọ nigba to ba de, awọn si nigbagbọ pe alaga igbimọ awọn ọba ọhun yoo nifẹẹ si lati ṣatilẹyin fun aṣeyọri eto naa nitori ọba ti ki i fi ọrọ aṣa Yoruba ṣere ni.

No comments:

Post a Comment

Adbox