IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 3 May 2020

Gbajumọ Olorin ẹmi, Ay Inspiration, gbe orin Iya mi ati Inspiration Jufuji jade

Ọkan pataki ninu awọn olorin ẹmi lorilẹ-ede yii ni  AY Inspiration, ọkunrin naa ti gbe orin tuntun meji to pe ni  'Inspiration Jufuji ati Iya mi jade'

Ọmọ bibi ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun ni Ayo Orimogunje, lati kekere lọkunrin naa ti n kọrin ninu ẹgbẹ akọrin ijọ ti awọn obi ẹ n lọ, ṣugbọn ọdun 1999 lo mu iṣẹ orin ni okukundun ti oun naa di gbajumọ laarin awọn ẹlẹgbẹ ẹ yooku. .

Rẹkọọdu meji lọkunrin naa ti gbe jade, awọn awo ọhun ni: 'Inspiration ati Appreciation', bẹẹ lo wa nile agodo to n sisẹ lọwọ lori awọn orin ẹ mi-in to pe ni 'Cry No More'.

Bakan naa lọkunrin naa ti ju orin meji sori afẹfẹ ẹrọ 'Boomplay', awọn orin naa ni 'Inspiration Jufuji ati Single Title Iya Mi'. Awọn orin yii lawọn ololufẹ ọkunrin naa fi n jaye orin wọn bayii.

Ninu ọrọ ẹ, Ay Inspiration  rọ awọn ọdọ to ṣẹṣẹ n dide bọ nidi orin lati mu Ọlọrun ni koko, ki wọn tẹpa mọ iṣẹ wọn daadaa.

No comments:

Post a Comment

Adbox