Ninu iwe yii ni Primate Ayodele ti salaye awon ohun ti yoo sele lorile-ede yii ati lagbaaye lagbo oselu, eto ilera, eko, eto ibara-eni-soro, ere idaraya, eto oro aje atawon eka mi-in. Iwe asotele yii ti won pe oruko re ni Warning to the nations lo ti n jade lati odun 1994.
Lara awon asotele to wa ninu iwe naa ni emi mimo ti fi han Primate Ayodele pe oludije fun ipo aare lorile-ede yii labe egbe oselu PDP ma se fakoko ati owo re sofo,nitori pe egbe APC ni yoo pada jawe olubori ni kootu.Ojise Olorun yii fi kun oro re pe Atiku yooja fitafita titi de ile-ejo to ga ju lo lorile-ede yii, sugbon ko ni i rowo mu, nitori pe ile-ejo tirabuna yoo gbe awon ilana eto idajo kan kale.
Ninu iwe yii ni Olorun ti fihan pe Primate Ayodele pe egbe PDP si nilo adari ile igbimo asofin agba tele, Senato Bukola Saraki ti won ba fee se aseyori ninu eto idibo odun 2023.
Bakan naa ni wolii nla yii tun so pe ile-ejo to n gbo esun magomago to jeyo lasiko ibo yoo yo awon omo egbe oselu PDP ati APC kan danu. Eni-owo Ayodele tun saleye ninu iwe yii pe awon omoleyin Asiwaju Bola Ahmed Tinubu yoo da a, won yoo se ohun ti ko lero. 'Emi Olorun so fun mi pe egbe PDP ni yoo jawe olubori nipinle Bayelsa, ipo gomina nipinle Kogi ni fi bee rogbo, sugbon ti PDP ba fee wole, Dino Melaye ni ki won lo gege bii oludije ipo gomina ninu egbe won'.
Primate Ayodele fi kun oro e pe a ni lati gbadura daadaa ki iyan ma tun sele lorile-ede yii. 'Gomina ipinle Eko, Ogbeni Babajide Sanwo-Olu yoo pade idojuko latowo awon asaaju egbe APC nipinle Eko, gbogbo ohun to ba se ko ni i te won lorun
Primate Ayodele tun so pe kawon ololufe ere boolu alafesegba gbadura ki ijamba ina ma sele lori papa, ki a ma si padanu agbaboolu kankan lorile-ede yii lasiko to n gba boolu lowo. 'E je ka gbadura ma padanu igbakeji igbakeji oga olopaa patapata nileese olopaa zone1 . Ka gbadura pe ka ma ri ikolu lawon ogba ileewe giga wa, ka tun gbadura pe ka ma ri ajalu ile wiwo lawon ileese girama ati alakobere wa lorile-ede yii. Ki oba Olowo tuntun to sese je gbadura daadaa ki Olorun fun un lemi gigun, nitori pe yoo salaba pade awon ipenija kan. Kawon omo ijo kerubu ati serafu gbadura ki won ma padanu awon asaaju won, awon eeyan kan yoo dide lati pin ijo sele si wewe. A gbodo sadura fawon oba kan nile hausa ki won le gun lemi-in, ki won ma yo won nipo. Ka tun gbadura pe ka ma ri iku olori esin islam kan. Kawon osere wa gbadura ki won ma padanu awon kan ninu won, bee ni ki won gbadura pe ki won ma ri ijamba moto.
Oro po ninu e jare, iwe ti gbogbo eeyan gbodo ni lowo ni Warning to the nation yi.
No comments:
Post a Comment