IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 8 July 2019

OLOMU TILU OMU-ARAN, OBA OLADELE ADEOTI FEE SABEWO SILUU EKO

Nnkan nla yoo sele niluu Eko ninu osu ti a wa yii, Oba ilu Omu-Aran, nipinle Kwara,  Oba Abdulraman Oladele Adeoti Ologbomona Olomu tilu Omu-Aran ti i se Olomu Efon Keji lo fee sabewo sawon omo ilu e.

Gege bi atejise ti egbe Omu-Aran People’s Movements,  fi sowo si wa, ojo kokandinlogun  osu yii ni Oba Alaye naa yoo de siluu Eko, gbara ti Kabiyeesi ba de ni won yoo sabewo si oludasile ile-ijosin 'Winners Chappel', Eni-owo Bishop Oyedepo.   

Ogunjo osu yii ni Oba Alaye naa yoo de odo gomina akoko nipinle Eko,  Alhaji Lateef Kayode Jakande, nigba ti Alayeluwa yoo se ipade nla pelu awon omo ilu Omu-Aran ti won n gbe nipinle Eko lojo kokanlelogun osu yii. Gbongan nla to wa nile-igbafe Airport Hotel to wa ni Ikeja nipade naa yoo ti waye.

No comments:

Post a Comment

Adbox