IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 12 July 2019

Ijamba ina epo Ijegun: Onarebu Adedipe Dauda Ewe Nla benu atelu awon olopaa, o ni won ko se ise won bii ise



Gbajugbaja oloselu, to tun je onisowo pataki nilu Eko, Onarebu Adedipe Dauda Ewe Nla, ti bu enu atelu ileese olopaa ipinle Eko pelu won se ko lati fi panpe oba gbe awon to lowo ninu fifo opa epo bentiroolu to fopo emi ati dukia sofo lose to koja ni Ijegun. Oga ileese  Adedas Development Foundation so pe ohun ti ko bojumu ni bawon olopaa ko se fofin gbe awon to lowo ninu ijamba naa.

O ni ‘O se mi laanu pe lati bii ojo mewaa seyin tawon to n ji epo wa ti fopo emi ati dukia sofo  nilu Ijegun, awon olopaa ko ri awon to sise ibi naa mu. E je ki n bi won, awon olopaa da, awon SARS da, o da mi loju to ba je pe lasiko ibo tabi ipolongo ibo niru ijamba yii sele, awon olopaa to sise fun egbe oselu APC to n dari ipinle Eko yoo ti maa fi olopaa wa awon omo egbe alatako kiri, won yoo so pe awon ni baba isale awon a- fo- opa- epo-yii.

Iru iya ti won fi je mi lasiko tijamba ina sele ni Abule-Egba, iya nla ni won ko ba fi je awon omo egbe alatako to n gbe ni Ijegun atawon agbegbe e. Nitori pe mo gbe apoti ibo labe egbe oselu PDP lati soju awon eeyan mi lekun idibo Alimosho 1 nile-igbimo asofin Eko lo je kawon asaaju egbe oselu APC fiya ohun ti n mi o mowo,ti n ko mese e fi je mi. Odidi ojo metadinlogoji ni won fi ti mi mo ahamo, ese ti mo se won ni pe mo ko lati darapo mo egbe APC. 

Titi dasiko yii lo se mi ni kayeefi idi ti won se ran oran  nla si mi lorun, mi o ki  n se olopaa,mi o ki siifu difensi tabi soja tijoba ni ko maa so opa epo, e jowo,ojo wo lo di  ese lati je omo egbe oselu alatako lorile-ede yii?.     
Nigba ti won kuna ise won lati dabo bo awon eeyan, paapaa awon olopaa to je pe ise won akoko ni lati dabo bo emi ati dukia awon eeyan ko se ise won bii ise ni won se yi ebi won le mi lori. 

Won ti iyawo mi, awon ebi atawon ore mimo inu ahamo, iya a i modii  ni won fi je awon eni eleni. Won ri i pe  ogbontarigi omo egbe oselu PDP ati oludije nla ni mi ni Alimosho won fi da gbogbo ogbon lati fiya je mi. Egbe oselu mokanlelaadorun-un la ni lorile-ede yii, gbogbo omo orile-ede yii pata lo letoo lati darapo mo egbe oselu to ba wu u, sugbon nipinle Eko ko ri bee rara, ninu ki o darapo mo won, ki o se ti won tabi ki won fiya je eni to ba ko lati bawon se. 

Enikeni to ba ko lati se ti won, ti onitohun-un tun waa je oloselu to gbajumo tawon eeyan feran re, inu galagala ni won yoo so eni naa si, ojo ibo ku ojo merin ni won too fi eni naa sile, ti ko fi ni i raaye sepolongo ibo’.



No comments:

Post a Comment

Adbox